Orí Kẹẹ̀sán

1 Òtítọ́ ni mo sọ nínú Kristi, èmi kò pa irọ́, bẹ́ẹ̀ni ẹ̀rí ọkàn mi jẹ́mi lẹ́ẹ̀rí pẹ̀lú Èmí Mímọ́. 2 Pé, mo ní ìbánújẹ́ ńlá àti ìrora ọkàn tí kò dáwọ́ dúró. 3 Nítorí mo ró nínú mi pé, kí a fi mi ré, kí a sì yà mí sọ́tọ̀ fún Krístì fún àǹfààní àwọn arákùrin ìn mí, àwọn ìran mi nínú ara. 4 Àwọn ni ọmọ Ísráẹ́lì. Wọ́n ti ní ìsọdọmọ ogo, àti ẹ̀bùn òfin, ìsìn Ọlọ́run, àti ìlérí. 5 Àwọn ni Bàbá ńlá nípaṣẹ́ àwọn tí Krístì ti wá nípa rẹ, ẹran ara - Ẹnití ó jẹ́ Ọlọ́run lórí ohun gbogbo. Kí o di ìyìn lógo láilái. Àmín. 6 Ṣùgbọ́n, kì íse pé ìlérí Ọiọ́run tí di ìjákulẹ̀. Nítorí kìí se gbogbo ènìyàn tí ó wá ní Ísráélí ni wọ́n jẹ́ ti Ísráélì ní tòótọ́ 7 Tàbí gbogbo ìran Ábráhámù ni ọmọ rẹ̀ ní tòótọ́. " Ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ Ísáákì ni a o fi pe ìran rẹ. 8 Pé, ọmọ ẹran ara kì íse àwọn ọmọ Ọlọ́run, Ṣùgbọ́n ọmọ ìlérí ni a ńpè ní àwọn ọmọ ìran. 9 Ńitorí èyí ni ọ̀rọ̀ ìlérí :" Pé ní àsìkò yi èmi yóò wá, a o si fi ọmọ kùnrin fún Sárà." 10 Kìí ṣe èyí nìkan, lẹ́yìn ti Rèbéká náà ti lóyún nípa okùnrin kan, bàbá wa Ísáákì. 11 pé a ko tíì bí, bẹ̀ẹ̀ni wọn kò tíì se ohun dídára tàbí búburú, kí ìlérí Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí yíyàn rẹ̀ lee dúró, kìí ṣe nípaṣẹ̀ ìṣẹ, ṣùgbọn bíkòse nípasẹ́ ẹni tí ó ńpè. 12 A sì ṣọ fún un pé, " Ẹ̀gbọ́n yóò sin àbúrò". 13 Ó sì wá gẹ́gẹ́bi á ti kọọ́: "Jákọ́bù ni mo fẹ́, ṣùgbọ́n Ísáù ni mo kórìra. 14 Kíni a o ti wí? Ǹjẹ́ àìsòdodo wà pẹ̀lú Ọlọ́run? Ká má rìí. 15 Nítorí tí ó ṣọ fún Mósè, " Èmi yoo sàànú fún ẹnití èmi yoo sàànu fún," Èmi yoo si yọ́nú sí ẹni tí èmi yoo yọ́nú sí. 16 Nítorí nàá, kìí ṣe níti ẹni tí ó fẹ́, tàbí nítorí ẹnití ó ńsáré, ṣùgbọ́n nítorí Ọlọ́run tó fi àáńu hàn. 17 Ìwé mímọ́ sọ fún wa nípa ti Fáráò, "Fún ìdí èyí ni mo se gbé ọ sókè, kí nlè fi agbára mi hàn nínú u rẹ̀, kí orúkọ mi lèe di gbígbé ga ní gbogbo ayé." 18 Nítorí náà, Ọlọ́run yoo se aanu fún àwọ́n tí O fẹ, àwọn tí ó fẹ́ á sì sé wọn lọ́kàn le. 19 Nígbàna ìwo yoo sọ fún mi, " Èéṣe tí ó sì rì àṣìṣe? Tani ó le kojú ìjà sí ìfẹ́ rẹ. 20 Ní ìdàkejì, okùnrin, tani ìwọ tí ó ńdáhùn lòdì sí Ọlọ́run? Sé ohun a mọọ lee sọ fún alámọ̀ pé, " Bawo ni ó se mọ mí báyìí?." 21 Sé alámọ̀ ko ha ní àṣẹ lórí amọ̀ láti fií mọ ohun èlò fún ìlò, ìyàsọ́tọ̀ àti òmíràn fún lílò ní ojojúmọ́. 22 Tàbí bí Ọlọ́run, tí ó wùú láti fii ìbínú àti agbáraa Rẹ̀ hàn, fi sùúrù púpọ̀ pẹ̀lú faradà àwọn ohun èlò ti a pèsè síiẹ̀ fún ìparun. 23 Ǹjẹ́ bí ó bá se èyí láti se àfihàn ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ lórí ohun èlò tí ó ti pèsé ṣílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ógo? 24 Bí ó bá jẹ́ pé èyí pẹ̀lú fún wa, tí ó ti pè, kíi se láàrin àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n laarin àwọn kèfèrí pẹ̀lú? 25 Bí ó se ṣọ pẹ̀lú ní Hóséà, "Èmi yoo pe àwọn ènìyàn mi, tí kìí se ènìyàn mi, àti olólùfẹ́ rẹ̀ tí kìí se olólùfẹ́." 26 Nígbàna ni yoo jẹ́ bí a ti sọ fun wọn pé, "Ẹ̀yin kìí se ènìyàn mi, níbẹ̀ ni a ó ti pè wọn ní "ọmọ Ọlọ́run alààyè." 27 Àìsáyà kígbe síta nítorí Ísráẹ́lì, " Bí iye àwọn ọmọ Ísráẹ́lì dàbí erùpẹ̀ òkun, àwọn tí ó ba kù ni a ó gbàlà." 28 Nítorí Olúwa yoo mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sẹ lórí ilẹ̀ aye pátápátá láì fi jáfara. 29 Gẹ́gébí Àìsáyà ti ṣọ tẹ́lẹ̀, " Bí Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun kò bá tí fi ìran rẹ̀ sílẹ̀ fún wa, a o dàbí Sódómù, a ó sì dàbí Gòmórà". 30 Kí ni a sọ nígbànáà? pé àwọn kèfèrí, tí kò lépa òdodo, gba òdodo, àní òdodo nípa ìgbàgbọ́. 31 Ṣùgbọ́n Ísráẹ́lì, tí ó lépa òfin òdodo, kò leè wọ inú u rẹ̀. 32 Kò ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nítorí wọ́n kò lepa rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n nípa iṣẹ́, wọ́n ṣubú lórí i àpáta ìkọsẹ̀. 33 Gẹ́gẹ́bí a ti kọ́ ọ́, "Wòó, èmi fi lélẹ̀ ní Síónì, òkúta ìdìgbòlù àti àpáta ìkọ̀sẹ̀. Ojú ki yóò ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́.