Orí Kẹẹ̀wá

1 Ẹ̀yin ará, èrò ọkàn mi àti ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn ni ìgbàlà wọn. 2 Nítorí pé mo jẹ́ri nípa wọn pé wọn ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì íse nípa ìmọ̀. 3 Nítorí wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọn sì n wá ọ̀nà láti fi òdodo tiwọn lélẹ̀. Nwọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run náà. 4 Nítorí Jésù ni ìmúṣẹ òfin náà fún òdodo fún gbogbo ẹni tí ó gbàgbọ́. 5 Nítorí Mósè kọ nípa òdodo tí ó wá láti inú òfin: "Ẹni náà tí ó bá ṣe òdodo nípa òfin yóò wà láàyé nípa òdodo òfin." 6 Ṣùgbọ́n òdodo náà tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́ sọ èyí pé, "Má se wí ní okàn rẹ pè 'tani yó gòkè re ọ̀run?' (túmọ̀sí, làti mú Kírísítì sọ̀kalẹ̀); 7 kí ẹ má se wípé, "Tani yóò lọ̀ sí ọ̀gbun àìnísàlẹ̀?" (túmọ̀sí, láti mú Kírísítí gòkè wá lárin àwọn òkú). 8 Sùgbọ́n kíni ó wí? "Ọ̀rọ̀ náà sún mọ́ ọ yín, nínú okàn àti ẹnu yín èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ náà, tì à n kéde. 9 Pé bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ Jésù ní Olúwa, tí o sì gbàgbọ̀ nínú ọkàn rẹ pé a jí i dìde kúrò nínú àwọn òkú, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi n gbàgbọ́ fún òdodo, àti ìjẹ́wọ́ ìgbàlà nìpa ẹnu. 11 Nítorí ìwé mímọ́ wípé, "Ẹnikẹni tó bá gbà á gbọ́ oju kò ní tìí. Nítorí kò sí ìyàtọ̀ láàrin Júù àti Gíríkì. 12 Nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, òun ni ọrọ̀ púpọ̀ fún gbogbo ẹni tí ń ké pè é 13 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orukọ Olúwa ni a ó gbàlà. 14 Báwo ni wọn ó se képe ẹni tí wọn kò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo ni wọn ó ṣe gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ẹni tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rí. 15 Nwọn ó ṣe wàásù, nígbà tí a kò rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, "Ẹsẹ̀ àwọn tí n wàásù ìhìnrere àláfíà ohun rere ti dára tó. 16 Ṣùgbọ́n kì í se gbogbo wọn ni ó tẹ́tí ṣí ìhìnrere. Nítorí Àìsáyà wípé, "Olúwa tani ó ti gba ọ̀rọ̀ wa gbọ́?" 17 Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ń wá nípa gbígbọ àní gbígbọ́ ọ̀rọ̀ kírísítí. 18 Sùgbọ́n mo wípé, "Nwọn kò a gbọ́ bí? "Bẹ́ẹ̀ni, ó dájú gbangba. Ohun wọn ti jáde lọ sí ilẹ̀ gbogbo, àti ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ayé náà. 19 Pẹ̀lú pẹẹ̀lú, mo wípé, "Ísírẹ́lì kò a mọ̀ bí?" Mósè ni ó kọ́ wípé, "Èmi ó ru yín sókè láti jowú nípa ohun tí kì í se orílèdè. Nípa orílèdè tí kò ní òyè, ni èmi ó fi ru ìbínú yín sókè." 20 Nígbà náà ni Àísáyà wí pẹ̀lú ìgboyà pé, "Àwọn tí kò wá mi rí mi. Mo farahán fún àwọn tí kò bèrè mi." 21 Ṣùgbọ́n fún Ísírẹ́lì ó wípé, "Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi sí aláìgbọràn àti alágbídí ènìyàn kan."