Orí Kọkànlá

1 Mo sọ nígbànáà pé, sé Ọlọ́run kọ àwọn ènìyàn Rẹ̀ sílẹ̀? Ká má ri. Nítoripé èmi páàpáà ọmọ Ísráélì ni mí, àrólé Ábúráhámú, ti ìran Béńjámínì. 2 Ọlọ́run kò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀sílẹ̀, tí ó tí mọ̀sáájú. Sé o mọ̀ohun ti ọ̀rọ̀Ọlọ́run sọ nípa Èlíjà, gẹ́gẹ́bí o ti bẹ̀bẹ̀pẹ̀lú Ọlọ́run lòdì sí Ísráélì? 3 "Olúwa wọ́n ti pa àwọn wòlíí Rẹ, èmi nìkan ni ó kù, Ṣùgbọ́n wọ́n sí ńlépa ọkàn mi." 4 Ṣùgbọ́n kíni ìdáhùn Ọlọ́run sí èyí? Mo fi pamọ́ fún ara mi ẹgbẹ̀rún méje ọkùnrin tí wọn ko tii tẹríba fún báálì. 5 Pẹ̀lúpẹ̀lú, ní àkókò yii, pẹ̀lú ìyókù tí ó wà níbẹ̀, nítorí yíyan ore ọ̀fẹ́. 6 Ṣùgbọ́n tí ó bájẹ́nípa ore ọ̀fẹ́, kì íse nípa iṣẹ́mọ́. Nídàkejì ore ọ̀fẹ́kò ní jẹ́ore ọ̀fẹ́mọ́. 7 Kíni nígbàná? Ohun ti àwọn ọmọ Ìsràélì ńwá, tí wọn kò rí gbà, àwọn tí ó kù ni a mú ní ọkàn le. 8 Ó rí gẹ́gẹ́bí a ti kọ́: "Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mi agọ̀ojú, kí wọ́n má ba lè ríran, àti ki wọn maa ba gbọ́, títí di ọjọ́òní." 9 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ṣọ pé,"Jẹ́kí tábìlì wọn dàbí àwọn àti pákútè, òkúta ìdìgbòlù àti èrè fún wọn." 10 Jẹ́kí ojú wọn di bàìbàì, kí wọn má bà ríran, àti títẹ̀ẹ̀hìn wọn láíláí." 11 Mo ṣọ nígbànáà pé, "Ǹjẹ́wọn kò kọsẹ̀, kí wọ́n ba ṣubú?" kí ó má rí bẹ̀. Dípò ìjákulẹ̀wọn, ìgbàlà ti dé ọ̀dọ àwọn kèfèrí láti ru wọ́n sí owú. 12 Bí àsìṣe wọn bá jẹ́ ọrọ̀fún ayé, àti bí ìpàdánù wọn bá jẹ́ ọrọ̀ fún kèfèrí, báwo ni ìparí wọn yoo se tóbi to? 13 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo ńbá àwọn kèfèrí sọ̀rọ̀, tí mo bá sì jẹ́ àpósítélì fún àwọn kèfèrí, mo lè yangàn nínú isẹ́ ìránṣẹ́mi. 14 Bóyá tí mo ba rú wọn sí owú àwọn tí wọ́n jẹ́ẹran ara mi. Bóyá a o gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn là. 15 Bí ìkọ̀sílẹ̀wọn bá túmọ̀sí ìlàjà gbogbo àgbáyé, kíni gbígbàá wọn yóò jẹ́, sùgbọ́n ìyè láti ọ̀dọ̀ àwọn òkú. 16 Bí àkọ́so bá wà ní ìpamọ́, bí odidi ìyẹ̀fun. Bí gbòǹgbo bá wà ní ìpamọ́, bẹ́ẹ̀ni àwọn ẹ̀ka. 17 Ṣùgbọ́n bí díẹ̀nínú àwọ́n ẹ̀ka bá bàjẹ́, tí ìwọ, àìtùlójú ẹ̀ka ólífí, bá wọnú ara wọ́n, bí ó bá sìí pin pẹ̀lú wọn nínú gbóǹgbò ọrọ̀igi ólífì. 18 máse yangàn lóri ẹ̀ka wọn. Ṣùgbọ́n bí ó bá yangàn, kìí se ìwọ ni ó se àtìlẹ́yìn fún gbòǹgbò, ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó se àtìlẹ́yín fún ara rẹ̀. 19 Ìwọ yóò sọ nígbànáà pé, "a ké ẹ̀ka kurò kí èmi léè wọnú rẹ̀." 20 Òtítọ́ni èyí. Nítorí àìgbàgbọ́wọn a ké wọn kúrò, Ṣùgbọ́n ìwọ dúro sinsin nítorí ìgbàgbọ́rẹ. Máse rò páapáà nítorí gíga rẹ, ṣùgbọ́n bẹ̀rù. 21 Nítorí ti Ọlọ́run kì bá tí dáá àdáyébá ẹ̀ka sí, bẹ́ẹ̀ni kì bá dá ìwọ sí. 22 Wòó, nígbànáà, irú ìgbẹ́sẹ̀àti ìdibàjẹ́ nínú Ọlọ́run. Ní ọ̀nà míràn, ìdibàjẹ́wá láti orí àwọn Júù tí ó subú. Ṣùgbọ́n ní ọ̀nà míìràn, ojú rere Ọlọ́run wa lórí rẹ, tí o ba ńtẹ̀síwájú nínú ojú rere rẹ̀. Bí bẹẹ́kọ́ìwọ náà yoo di gígé kúrò. 23 Àní àti àwọn, tí wọn kò bá tẹ̀síwájú nínú àìgbàgbọ́wọn, àwa yoo di titun nínú rẹ̀. Nítorí Ọlọ́run lee sọ wọn di titun nínu rẹ̀lẹ́ẹ̀kansi. 24 Bí a ba ké ọ kúro nínú ìsẹ̀dá ẹ̀gàn igi ólífì, àti ní ìlòdì sí ìsẹ̀dá tirun sí igi ólífì dáradára, mélóòmélóò ni pẹ̀lú àwọn Júù, ti o jẹ́ẹ̀ka ìsẹ̀dá, da tirun wọn padà sígi ólífì? 25 Nítorí èmi kò fẹ́kí ẹ̀yin wá ní àìmọ̀, arákùrin, nípa ohun ìjìnlẹ̀, tí ẹ̀yin kò fi ní jẹ́ọlọ́gbọ́n nínú èrò yín. Ohun ìjìnlẹ̀yi ni pé apa líle ti sẹlẹ̀ní Ísráélì, títí tí ìparí àwọn kèfèrí yóò dé. 26 Tí gbogbo Ìsràèlí yoo fi di ẹni ìgbàlà, gẹ́gẹ́bí ati kọ́ọ́: " Nínú Síónì Olùdándè yoo ti jáde wá. Yoo mú àìwà-bí-Ọlọ́run kúro ní Jákọ́bù, 27 àti pé èyí yoo jẹ́májẹ̀mú mi pẹ́lú wọn, nígbàtí Èmi yoo mú ẹ̀ṣẹ̀wọn kúrò. 28 Ní ọ̀nà kan náà nípa ti ìhìnrere, wọ̀n jẹ́ọ̀tá nípa rẹ. Ní ọ̀nà míràn gẹ́gẹ́bi ó se wun Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ àyàn fẹ́nítorí ìran. 29 Nítorí ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run kò se yípadà. 30 Nítorítí o ti fi ìgbà kan tàpá sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nísínsìyí o ti rí ànu un gbà nítorí àìgbọràn wọn. 31 Bákanáà, nísinsìnyí tí àwọn Júù ti se àìgbọràn. Èsì rẹ̀ni wípé pẹ̀lú àánú tí a ti fi hàn ọ́àwọn náà léè rí áànú gbà. 32 NÍtori Ọlọ́run ti sé gbogbo ènìyàn sí àìgbọràn, kí ó le fi àánú hàn si gbogbo ènìyàn. 33 Tí o bá faramọ́ ìjìnlẹ̀ọrọ̀ti ọgbọ́n àti ìmọ̀Ọlọ̀run! Àwámáridíì ni ìdájọ́Rẹ̀, àti ọ̀nà Rẹ̀kọjá àwárí. 34 "Tani ó ti mọ ọkàn Olúwa tàbí tani ó ti di onímọràn Rẹ̀? 35 Tàbí ẹníkẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́fi ohunkóhun fún Ọlọ́run, ni Ọlọ́run gbọ́dọ̀ sán fún bí?" 36 Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ áti nípa rẹ àti síi ni ohun gbogbo. Síì ni gbogbo ògo láíláí. Àmín.