Orí kẹjọ

1 NÍtorínáà, kò sí ìdálẹ́bi fún àwọn tí ó wà nínú un Krístì. 2 Nítorí ìlànà ti Ẹ̀mí ìyè nínú Krístì ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìlànà ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. 3 Nítorí ohun tí òfin kò le è se, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìlera nípa ti ara, Ọlọ́run se é. Ó ran ọmọ Rẹ̀ ní àwòrán eran ara ẹ̀ṣẹ̀ láti jẹ́ ẹbọ fún ẹ̀sẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nípa ti ara. 4 Ó se èyí kí á le mú gbogbo ìlànà òfin sẹ nínú n wa, àwa tí a kò rín nípa ti ara, bíkòse nípa ti Ẹ̀mi. 5 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó ń gbé nípa ti ara, a máa fi ọkàn sí ohun ti ara, ṣùgbọ́n apwọn tí ó ń gbé nípa ti Ẹ̀mi a máa fi ọkàn sí ohun ti Ẹ̀mí. 6 Nítorí èrò ti ọkàn jẹ́ ikú, ṣùgbọ́n èrò ti Ẹ̀mi jẹ́ ìyè àti àlááfíà. 7 Èrò ti ọkàn jẹ́ òkúrorò sí Ọlọ́run, nítorí kò tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òhun kò tilẹ̀ le sé. 8 Àwọn tí ó wà nípa ti ara kò le è wu Ọlọ́run 9 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò sí nínú ara bíkòse nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá jẹ́ pé Èmi Ọlọ́run ń gbé inú yín ní tòótọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí i Krístì, òun kìí se tirẹ̀. 10 Bí Krístì bá wà nínú yín, ará ti di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí wà láàyè sí òdodo. 11 Bí Ẹ̀mí ẹni tí ó jí Jésù dìde kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, Ẹni tí ó jí Krístì dìde kúrò nínú àwọn òkú yóò fi ìyè fún ara kíkú yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí i Rẹ̀, tí ó ń gbé inú un yín. 12 Nítorínáà, ará, ajigbèsè ni àwa, ṣùgbọ́n kìí se sí ara láti gbé nípa ti ara. 13 Nítorí bí ẹ̀yi bá gbé nípa ti ara, e se tán àti kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yi bá pa isẹ̀ ti ara run nípa Ẹ̀mí, ẹ̀yin yóò yè. 14 Nítorí iye àwọn tí Ẹ̀mi Ọlọ́rún bá ń dari, àwon ni ọmọ Ọlọ́rún. 15 Nítorí ẹ̀yin kò ga ẹ̀mí ẹrú mọ́ láti máa bẹ̀rù. Bíkòse èmí ìsọdọmọ, nípasẹ̀ ẹni tí àwá ń ké, "Ábbà, Bàbá!" 16 Ẹ̀mí gangan n se Ẹlẹ́rǐ pẹ̀lú ẹ̀mí wa, wípé ọmọ Ọlọ́rún ni àwa ń se. 17 Bí a bá wá jẹ́ ọmọ, a jẹ́ ajogún bákannáà, ajogún Ọlọ́rún. A sì jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú u Krístì, bí ó bá jẹ́ pé lóǒtọ́ ni a jìyà pẹ̀lú u Rẹ̀ kí á baà le se wá lógo pẹ̀lú u Rẹ̀. 18 Nítorí mo mọ̀ pé èmi kò le fi ìjìyà ti ìsinsìnyí we ògo tí a ó fi hàn wa. 19 Nítori ẹ̀dá ń dúró ní àfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́rún. 20 Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba sí asán, lòdì sí ìfẹ́ ẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n fún ẹni tí ó tẹrí i rẹ̀ ba. Ò wà nínú ìgboyà ìdánilójú 21 pé a ó gba ẹ̀dá fúnrara rẹ̀ kúrò ní oko ẹ̀rú sí ìdibàjẹ́, a ó sì mu wá sí ìtúsílẹ̀ ògo àwọn ọmọ Ọlọ́rún. 22 Nítorítí a mọ̀ pé gbogbo ìsẹ̀dá ń gbin wọ́n sì ń rọbí nínú ìrora papọ̀ títí di ìsinsìnyí. 23 Kì í se èyí nìkan, ṣùgbọ́n àwa fúnrara wa, tí ó ní àkọ́so ti Ẹ̀mí-àwa tíkalára wa ń gbin nínú ara wa, á ń dúro de ìsọdọmọ wa, ìràpadà ara wa. 24 Nítorí nípa ìgboyà ni a gbà wá là. Ṣùgbọ́n a kò tí ì rí ohun tí a ní ìdánilójú pé yóò sẹlẹ̀, nítorí tani ó ń dúró ní ìdánilójú fún ohun tí ó ti rí? 25 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ní ìdánilójú nípa ohun tí àwa kò tíì rí, àwa ń dúró pẹ̀lú ìfarabalẹ̀ fún n. 26 Bákannáà, Ẹ̀mí ń ràn wá lọ́wọ́ nínú àìlera wa. Nítorí àwa kò mọ bí ó ti yẹ kí á gbàdúrà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí tíkalára rẹ̀ ń sipẹ̀ fún wa pẹ̀lú ìrora tí a kò le è sàlàyé. 27 Ẹni tí ó ń wá ọkàn mọ ohun ti Ẹ̀mí, nítorí ó ń sipẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́rún. 28 Àwá mọ̀ pé fún àwọn tí ó fẹ́ràn Ọlọ́rún, Ó ń se oun gbogbo papọ̀ fún rere, fún àwọn tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinu Rẹ̀. 29 Nìtorí àwọn tí ó kó ó mọ̀, ni ó kọ́ yàn láti rí bí àwòrán Ọmọ Rẹ̀, kí ó le è jẹ́ àkọ́bí láàrín arákúnrin púpọ̀. 30 Àwọn tí Ó kọ́ yàn, àwọn ni Ó pè. Àwọn tí Ó pe, àwọn wọ̀nyí ni Ó dáláre. Àwọn tí Ó dálare, àwọn wọ́nyí ni Ó selógo. 31 Kíwáni àwa yóò sọ nípa àwọn nǹkan wọnyí? Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, tani ó lòdì sí wa? 32 Òun kò wo ti Ọmọ Rẹ̀ ṣùgbọ́n Ó fi sílẹ̀ nítorí wa, báwo ni ko ní tilẹ̀ fún wa ní ohun gbogbo lọ́fẹ̌ pẹ̀lú u Rẹ̀? 33 Tani yóò fi ẹ̀sùn kan àwọn tí Ọlọ́run yàn? Ọlọ́run ni Ó ń dániláre. 34 Tani yóò dánilẹ́bi? Krístì ni ó kú fún wa, ju èyí lọ, a tún jíi dìde. Ó ń jọba pẹ̀lú Ọlọ́run ní ibi ẹ̀yẹ, Òun sì ni ó ń sìpẹ̀ fún wa. 35 Tani yóò yà wá nínú ìfẹ́ Krístì? Ìpọ́njú, tàbí wàhálà, tàbí inúnibíni, tàbí ebi, tàbí ìhòhò, tàbí idà? 36 Bí a sì ti se kọ́, " Nítorí rẹ ni a se ń pa wá ní gbogbo ọjọ́. A kà wá kún àgbùntàn fún pípa." 37 Nínú gbogbo èyí, àwá ju asẹ́gun lọ nípa ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí ó ti dámilójú pé ìbáà se ikú, tàbí ìyè, tàbí áńgẹ́lì, tàbí ìjọba, tàbí ohun ìsinsìnyí, tàbí ohun tó ń bọ̀, tàbí agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun tí a dá, ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó wà nínú Krístì Jésù Olúwa wa.