Orí Keje

1 Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò a mọ̀, ará (nítorí èmi ń bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀), wípé bí èyàn bá sì wà láyé, ówà lábẹ́ òfin. 2 Nítorí obìrin tó ti l'ọ́kọ wà lábẹ́ ófin nígbà t'ọ́kọ náà sì wà láyé, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà bákú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin ìgbéyàwó. 3 Torí náà, tí ó bá lọ s'ọ́dọ̀ okùnrin míràn nígbàti ọkọ rẹ̀ wáà láyé, ó sàgbèrè. Ṣùgbọ́n b'ọ́kọ rẹ̀ bákú tó sì gbé pẹ̀lúu ọkùnrin mìíràn, kìí sàgbèrè. 4 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, a sọ yìn di òkú sí òfin nípasẹ̀ ara Krístì. Kí á le è so yín pọ̀ mọ́ ara yín, èyí i nì, sí Ẹni tí a jí kúrò láarín àwọn òkú, kí á le è so èso fún Olúwa. 5 NÍtorí nígbà tí a wà nínú ara, ìfẹ́kúfẹ̌ ẹ̀sẹ̀, tí ó wá nípasẹ̀ òfin, ó ń sisẹ́ nínú wa láti so èso tí ó yẹ fún ikú. 6 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí a ti tú wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin. A ti kú sí ohun tí ó dì wá mú. Kí á baà le sín ní ilànà titun ti Ẹ̀mi, kì í se nípa ti ìlànà àtilọ́ ti òfin. 7 Kíni àwa ó ha ti wí? Ǹjẹ́ òfin jẹ́ ẹ̀sẹ̀? Kí a má rí i. Ṣùgbọ́n, èmi kì bá tí mọ ẹ̀sẹ̀, bíkòṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò bíkòṣe pé òfin wípé, "Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ se ojúkòkòrò." 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀sẹ̀ ti ipa òfin ó sì mú onírúurú ìfẹ́kúfẹ̌ sínú mi. Nítorí láìsí ẹ̀sẹ̀, ikú ni ẹ̀sẹ̀. 9 Nígbà kan mo wà láyé láìsí òfin, ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀sẹ̀ gba ìyè, mo sì kú. 10 Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, wá já sí ikú fún mi. 11 Nítorí ẹ̀sè ti ipa òfin láti rí àyè ó sì tàn mí jẹ. Ó sì pa mí nípa òfin. 12 Nítorínáà òfin jẹ́ mímọ́, àsẹ sí ì jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú, àti òdodo, àti dáradára. 13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára di ikú bi? Kí á má rí i. Ṣùgbọ́n èsè, kí á báa lè fihàn pé ẹ̀sẹ̀ ni nípasẹ̀ ohun tí ó dára, mú ikú wá nínú mi. Ẹ̀yí jẹ́ pé nípasẹ̀ òfin, ẹ̀ṣẹ yóò di èṣẹ̀ tí ó kọjá òsùwọ̀n. 14 NÍtorí a mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun ti ẹ̀mí, ṣùgbọ́n èmí jẹ́ ti ara. A ti tà mí lábẹ́ ẹrú sí òfin. 15 NÍtorí ohun tí mò ń se, kò tilẹ̀ yé mi gidigidi. NÍtorí ohun tí mo fẹ́ se, èmi kò se é, ohun tí èmi sì kórira, èmi ń se é. 16 NÍtorí tí èmi bá se ohun tí èmi kò fẹ́ se, mo gbà pẹ̀lú òfin pé òfin dára. 17 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí kì í se èmi ni ó ń se wọ́n, ṣùgbọ́n èọẹ̀ tí ó ń gbé inú ùn mi. 18 NÍtorí mo mọ̀ pé nínú ǹ mi, àní nínú ara à mi, ayé kìí se ohun dáradára. NÍtorí ìfẹ́ ohun dídára wà pẹ̀lu mi, ṣùgbọ́n èmi kò le é se é. 19 NÍtorí ohun tí ó dára tí mo fẹ́, èmi kò se é, ṣùgbọ́n ohun búburú tí èmi kò fẹ́, èyí ǐ ni mò ń se. 20 Nísinsìnyí, tí èmi bá ń se ohun tí èmi kò fẹ́ se, kì í se èmi ni ó ń se é bíkòse ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń gbé inú ùn mi. 21 Nígbànáà ni mo rí, ìlànà náà nínú mi pé mo fẹ́ se ohun tó dára, ṣùgbọ́n ohun búburu u nì wà nínú ún mi. 22 Pẹ̀lú ẹni tí ó wà nínú, inú mi dùn nínú òfin Ọlọ́run 23 Nítorí mo rí ìlànà míràn nínú ẹ̀yà ara mi. Èyí tí ó ń jà lòdì sí ìlànà titun ti ọkàn mi. Ó mú mi ní ìgbèkùn nípa ìlànà ẹ̀sẹ̀ tí ó wà nínú ẹ̀yà ara mi. 24 Mo jẹ́ otòsì ènìyàn! Tani yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ ara ikú yǐ ? 25 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nipasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi! Ǹjẹ́ nitorínáà, Èmi gangan ń si òfin Ọlórun pẹ̀lú ọkàn mi. Ṣùgbọ́n nípa ti ara, mò ń sin ìlànà ti ẹ̀ṣẹ̀.