Orí Kẹfà

1 Kínni ká ti wí? Ṣé kí àwa kí ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí oore-ọ̀fẹ́ lé pọ̀ si? 2 Kí o maṣe rí bẹ̀. Àwa tí a ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, báwo ni a ó tún ṣe máa gbé inú rẹ̀? 3 Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ wípé iye àwọn tí a rì bọ inú Krístì Jésù ni a ti rì bọ inú ikú rẹ̀? 4 A sin wá, bákan náà, pẹ̀lú Rẹ̀ nípasẹ̀ ìtẹ̀bọmi sínú ikú. Èyí ṣẹlẹ̀ wípé gẹ́gẹ́ bí a ti jí Jésù dìde kúrò nínú òkú lẹ́ẹ̀kan nípa ógo Baba, bẹ́ẹ̀ni kí àwa pẹ̀lú léè ma rìn ní ìgbé ayé ọ̀tun. 5 Nítorí bí a bá ti sọ wá dọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀ nípa àfarawé ikú Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a o sọ wá dọ̀kan pẹ̀lú àjínde Rẹ̀. 6 Àwá mọ̀ èyí pé, a ti kan ọkùnrin ogbologbo wa mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú Rẹ̀, kí a lè pa ara ẹ̀ṣẹ̀ run. Èyí ṣẹlẹ̀ kí a má bàá wà lábẹ́ ìsìnrú ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 7 Ẹnikẹni tí o ti kú ni a sì kà sí olólodo nípa ohun tí ó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀. 8 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ti kú pèlú Krístì, àwá gbàgbọ́ wípé a ó wà láàyè pèlú Rẹ̀ 9 Àwá mọ̀ wípé a ti jí Krístì dìde kúrò láàrin àwọn òku, àti pé kò kú mọ́. Ikú kò láṣẹ lórí Rẹ̀ mọ́. 10 Nítorí nìti ikú tí Ó kú sí ẹ̀ṣẹ̀, Ó kú fún wa lẹ́ẹ̀kan náà. Síbẹsíbẹ̀, wíwà tí Ó wà láàyè, Ó wà láàyè fún Ọlọ́run. 11 Bákan náà, o gbọ́dọ̀ ka ara rẹ kún ẹni tí ó kú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó wà láàyè sí Ọlórun nínú Krístì Jésù. 12 Nítorí nàà, ẹ máse jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jọba lórí ara ìdibàjẹ́ yín kí ẹ̀yin má bàá ma gbọ́ran sí ìfẹ́kùfẹ́ rẹ. 13 Ẹ máṣe yọ̀nda àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bi ohun èlò fún àìṣododo. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀nda ara yín fú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn òku tí ó wà lááyè nisisinyi. Àti wípé kí ẹ yọ̀nda ara yín fún Olọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun èlò sí òdodo. 14 Ẹ máṣe jẹ́kí ẹ̀ṣẹ̀ jọba lórí yín. Nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n bíkòṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́. 15 Njẹ́ kíni? Ṣé àwa yóò ṣẹ̀ nítorípé àwa kò sí lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́ bí? Kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀. 16 Njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ẹni náà tí ẹ̀yin bá yọ̀nda ara yín fuń gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ oun ni ẹni náà tí ẹ̀yin ṣe ìgbọràn sí, ẹnití ẹ̀yin gbọdọ̀ gbọ́ran sí? Òtítọ́ ni èyí bóyá ẹ̀yin jẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó lọ sípa ikú, tabi ìránṣẹ́ sí ìgbọràn tí ó lọ sí ipa òdodo. 17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run! Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yín ti fi tọkàntọkàn gbọ́ràn si ìlàna ẹ̀kọ́ ti a fi fún yín. 18 A ti sọ yín di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, a sì ti sọ yín di ẹrú òdodo. 19 Èmi sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nítorí kùdìẹ̀kudiẹ ara yin. Gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yin ti ṣe yọ̀nda àwọn ẹ̀yà ara yín sí àìmọ́ àti sí ibi, lọ́ná kan náà báyi, ni kí ẹ̀yin yọ̀nda àwọn ẹ̀yà ara yín gẹ́gẹ́ bi ẹrú òdodo fun ìyàsímímọ́. 20 Nítorí ìgbàtì ẹ̀yín jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin di òmìnira kúrò nínú òdodo. 21 Nígbà náà, èso kíni ẹ̀yín ní bayi nínú ohun tí ó n tí yìn lójú nisisiyi? Nítorí ikú ni àbájáde nkàn wọ̀nyi jẹ́. 22 Ṣùgbọ́n nisisyi tí a ti sọ́ yín di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀yin sí ti di ẹrú Ọlọ́run, ẹ̀yín ní èso yín sí ìyàsímímọ́. Àbájáde rẹ̀ sì jẹ́ ìyè àínípẹ̀kun 23 Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àínípẹ̀kun nínú Krístì Jésù Olúwa wa.