Orí Kaàrún

1 Níwọ̀n bí a ti dáwa láre nípa ìgbàgbọ́, àwá ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Krístì Olúwa wa. 2 Nípasẹ̀ Rẹ̀ àwá tún ní ọ̀nà nípa ìgbàgbọ́ sínú ore-ọ̀fẹ́ nínú èyí tí àwá gbé dúró. Àwa n yọ̀ nínú ìgboyà tí Ọlọ́run fún wa fún ọjọ́ iwájú, ìgboyà tí àwá yíò pín nínú ògo Ọlọ́run. 3 Èyí nìkan kọ́, ṣùgbọ́n àwa nyọ̀ nínú àwọn ìnira wa. Àwá mọ̀ pé ìnira a máa mú ìfaradà wá. 4 Ìfaradà a máa mú ìtẹ́wọ́gbà wá, àtí ìtẹ́wọ́gbà a máa mú ìgboyà wá fún ọjọ́ iwájú. 5 Ìgboyà yí kìí jánikulẹ̀, nítorí a ti da ìfẹ́ Ọlórun sínú ọkàn wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí mimọ, Ẹni tí a fi fún wa. 6 Nítorí nígbàtí àwa jẹ́ aláìlera, lí àkókò tí ó yẹ Krístì kú fún àwọn aláìwà-bí-Ọlórun. 7 Nítorí ó ṣòro kí ẹnìkan kú fún olódodo ènìyàn. Èyí ni pé, bóyá ni ẹníkẹni yóò lè kú fún ẹni rere. 8 Ṣùgbọ́n Ọlórun nfi ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ sí wa hàn, nítorí nígbàtí àwá jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ, Krístì kú fún wa. 9 Mélòómélòó, nígbà náà, nísisiyi tí a dá wa lare nípa ẹ̀jẹ Rẹ̀, a ó gbà wá là nípa rẹ̀ kúrò nínú ìbínú Ọlọ́run. 10 Njẹ bí, nígbàtí àwá jẹ́ ọ̀tá, a bá báwa làjà pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ ikú Ọmo rẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú, lẹ́yìn tí a bá ba wa làjà, ni a o gbà wá là nipasẹ̀ ìyè rẹ̀ . 11 Èyí nì kan kọ, ṣùgbọ́n àwa n yọ̀ nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Krístì Olúwa wa, nípasẹ̀ eni tí àwa rí ìlàjà náá gbà. 12 Torí nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sẹ̀ ti ṣe wọ ayé nipasẹ̀ ọkùnrin kan, lọna kan naa ikú wọlé nípa ẹ̀ṣẹ̀. Àti pé ikú tàn ká sórí gbogbo ènìyàn, nítorípé gbogbo ènìyàn ni ó ti ṣẹ̀. 13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà nínú ayé, ṣùgbọ́n a kò le kàá sí ẹ̀ṣẹ̀ nígbàtí kò sí òfin. 14 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, ikú jọba lati ìgbà Ádámù títí di ìgbà Mósè, síbẹ̀ lorí àwon tí kò dẹ́ṣẹ̀ bíi àìgbọ́ran Ádámù, ẹnití n ṣe àpẹrẹ ẹni tí n bọ̀. 15 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀bùn naa kìí ṣe bíi ìrékọjá. Nítorí bí ó bá ṣe nípa ìrékojá ẹnìkan ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe kú, mélòómélòó ni oore ọ̀fẹ́ Ọlórun àti ẹ̀bùn nípa oore ọ̀fẹ́ enìkan náà, Jésù Kristì, ó wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. 16 Nítorí ẹ̀bùn náà kii ṣe bi ti àbájáde ẹnikan tí ó ṣẹ̀. Nítorí ní apá kan, ìdájọ́ ti ìdálẹ́bi wá nítorí ìrékọjá ọkùnrin kan. Ṣùgbọ́n ní apá kejì, ẹ̀bùn tí ó mú ìdáláre wá ó wá lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsedédé. 17 Nítorí bí, nípa ìrékọjá ẹnìkan, ikú jọba nípasẹ̀ ẹnìkan, melomelo ni àwọn tí wọ́n gba ẹkùnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo n jọba nípasẹ̀ íyé ẹni naa, Jésù Krístì. 18 Nígbànáà, bíi nípa ìrékọjá kan ni gbogbo ènìyaǹ wá sí ìdalẹ́bi, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nípa iṣẹ́ òdodo kan ni ìdáláre sí ìyè fi wá fún gbogbo ènìyàn. 19 Nítorí nípa àígbọran ẹnìkan ni a sọ ọ̀pọ̀lọpọọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ nípasẹ̀ ìgbọ́ràn ẹnìkan ni a o sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di olódodo. 20 Ṣùgbọ́n òfin náà wá pẹ̀lú rẹ̀, pé kí ìrékọjá náà le pọ̀si. Ṣùgbọ́n níbití ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, ore-ọ̀fẹ́ pọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀. 21 Èyí ṣẹlẹ̀ pé, bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe jọba nínú ikú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ baà le ṣe àkóso nípa òdodo fún ìyè àínípẹ̀kun nípa Jésù Krístì Olúwa wa.