Orí Kẹrin

1 Kí la ó sọ pé Ábráhámù, baba ńlá wa nípasẹ̀ ara, rí? 2 Nítorí bí Ábráhámù bá ti gba ìdáláre nípasẹ̀ iṣẹ́, kò bá ti ní ìdí láti janu, ṣùgbọ́n kìí ṣe níwájú Ọlọ́run. 3 Nítorí kínni ìwé mímọ́ wí? "Ábráhámù gbà Ọlọ́run gbọ́, a sì kàá kún ódodo fún-un." 4 Nísinsìnyí, fún ẹni tí ó sisẹ́, ohun tí a fún-un ni a kò le kà kún ẹ̀bùn, ṣùgbọ́n ohun tí a jẹ ẹ́. 5 Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò siṣẹ́ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ nínú eni tí dá aláìwà-bíi-Ọlọ́run láre, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni a ó kàkún òdodo. 6 Dáfídì náà súre fún ẹni t'Ọ́lọ́un kàkún olodódodo láì sí iṣẹ́. 7 Ó wípé, "Ìbùkún ni fún ẹni tí órí ìdàríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, àt'ẹni tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. 8 Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run kòní ka ẹ̀ṣẹ rẹ̀." 9 Nígbànáà ǹjẹ́ ìbùkún a wà lórí àwọn òǹkọlá nìkan bí, tàbí àti àwọn aláìkọlà? Nítorí àwa wípé, "A ka ìgbàgbọ́ kún òdodo fún Ábráhámù." 10 Báwo ni asì ti kàá? Nígbàtí Ábráhámù jẹ́ òǹkọlá, tàbí aláìkọlà? Kìí ṣe nínú ìkọlà, ṣùgbọ́n nínú àìkọlà. 11 Ábráhámù gba àmìn ìkọlà. Ìkọlà yí jẹ́ èdìdí òdodo ìgbàgbọ́ tí Ábráhámù ti ní nígbà àìkọlà. Èyí tún sọ Ábráhámù di baba ńlá gbogbo ẹni tí ógbàgbọ́, kódà kí wọ́n mọ́ kọlà. A ó kàá kún òdodo fún wọn. 12 Èyí tún jẹ́pé Ábráhámù di baba ńla àwọn tó kọlà kìí se fún àwọn òǹkọlà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn tó ń rìn nílàna ìgbàgbbọ́ Ábráhámù kí ó tó se ìkọla. 13 Nítorí ìlérí fún Ábráhámù àti ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ajogún kò wá nípa òfin ṣùgbọ́n nípa òdodo ìgbàgbọ́. 14 Nítorí tó ba jẹ́ pé àwọn tó ń pa òfin mọ́ ni yóò jẹ́ ajogún, ìgbàgbọ́ kò wúlò, ìlérí náà síì jásásan. 15 Nitorí òfin a mọ́ọ mú ìbínú wá, ṣùgbọ́n níbití kò sí ófin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀. 16 Nítorí ìdí èyí nípa ìgbàgbọ́ ni, kí ìlérí leè dúró lórí ore-ọ̀fẹ́ àti kí ósì dájú fún àwọn ìran Ábráhámù--kìí ṣe àwọn t'ófin ńdarí nìkan, ṣùgbọ́n fún áwọn tó pín nínú ìgbàgbọ Ábráhámù. Òun ni baba ńlá gbogbo orílèdè, 17 bí a ṣe kọ́ pé, "Èmi ti fi ọ́ ṣe bàbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílèdè." Ábráhámù wà níwájú Ẹni tí òhun gbàgbọ́, èyí tíí ṣe Ọlọ́run, tó ń jí òkú dìde tó sì ń pe ohun tí kò sí tí ósì wà. 18 Pẹ̀lú gbogbo ìsòro àfojúrí, Ábráhámù gba Ọlọ́run gbó fún ọjọ́ ọ̀la. Ó di bàbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílèdè, gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ati sọ, "Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ re." 19 Kò rẹ̀ ẹ́ nínú ìgbàgbọ́. Ábráhámù mọ̀ pé ara òun kò le bímọ mọ́ (torí ó ti tó bíi ọgọ́run ọdún), ó tún mọ̀ pé Sárà ti kọjá ẹni tò lè bímọ. 20 Ábráhámù kò siyèméjì nítorí ìlérí Ọlọ́run. Dípo rẹ̀, ó di alágbára nínú gbàgbọ́, ó sì tún yin Ọlọ́un. 21 Ó dá lójú gan wípé Ọlọ́run yóò ṣe ohun tó bá ti sèlérí. 22 Nitorí náà Ọlọ́run tún ka eléyìí kún ódodo fún Ábráhámù. 23 Nísinsìnyí a kò kọ́ sílẹ̀ fún àǹfàní rẹ̀ nìkan, wípé a kàá fún-un. 24 A kọ̀ fún àwa náà, tí a ó káà fún-un, àwa tí ó gbàgbọ́ nínú Ẹni tó jí Jésù Olúwa dìde kúrò nínú àwọn òkú. 25 Èyí ni ẹni ti a fi fún wa nítorí ẹ̀ṣẹ wa, tí a sì jí dìde kí álè dá wa láre.