Orí Kẹta

1 Ǹjẹ́ kíni àǹfàní tí àwọn Júù ní? Kí sì ni pàtàki ìkọlà? 2 Ó tóbi ní gbogbo ọ̀nà. Ní àkọ́kọ́, àwọn Júù ni a yọ̀ǹda ìran fún ní àtọ̀dọ Ọlọ́run. 3 Nítorí bí àwọn Júù kan kò bá ní ìgbàgbọ́ ńkọ́? Ṣé àìnígbàgbọ́ wọn sọ pé Ọlọ́run kìí se olódodo? 4 Kò jẹ́ ríbẹ̀. kàkà bẹ́ẹ̀, kí Ọlọ́run nìkan jẹ́ olòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn jẹ́ onírọ́. Bí a ti kọ́ pé, "Kí á lè dayín mọ̀ nínú òótọ̀ ọ̀rọ yín, kí ẹ leè borí ní ìdájọ́" 5 Ṣùgbọ́n tóbá jẹ́ pé inú àìsòdodo wa nìkan ni òdodo Ọlọ́run ti ń farahàn síwa, kí ni a ó sọ? Ṣé áwà á sopé kò bójúmu b'Ọ́lọ́run se bínú síwa ni? (Ká ti ẹ̀ wò léro t'èyan.) 6 Kò le jẹ́ béè láyé! Tóba jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo l'Ọlọ́run yó ṣe wa sèdájọ́ ayé? 7 Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ nínú irọ́ mi ni ìyìn òtítọ́ Ọlọ́run ti jẹ́ Tirẹ̀, kílódé tí wọ́n dámi lẹ́jọ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀? 8 Ẹ ò ṣe jẹ́ ká sọpé, bí wọ́n se ń parọ́ mọ́ wa, tí àwọn kan ńjẹ́ ri sí pé a sọpé, "Ẹjẹ́ ká ṣebi ká lè ríre"? Ìdálẹ́bi tọ́ sí wọn. 9 Kílókù? Ǹjẹ́ àwá ń yọ ara wa kúrò bìí? Rárá o. Àti Júù àti Gíríkì, gbogbo wọn lati dálẹ́jọ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ńbáwọn fínra. 10 Gẹ́gẹ́ bí ati kọọ́ pé: "Kò s'ẹ́nìkan kan tí ó jẹ́ olódodo, kò s'ẹ́nìkan. 11 Kò sí ẹnìkankan tí ó lóye. Kò sẹ́ni tó ńwá Olúwa. 12 Oníkálukú ti yà sọ́nà míràn. Wọn kò wúlò. Kò sẹ́nìkan kan tó ńṣe rere, kódà kò sí ọ̀kan. 13 Ihò iṣà òkú ni ọ̀nà-òfun wọn. Ahọ́n wọn tàn èyàn. Ète wọn ń soró bí ejò. 14 Èpè àti ọ̀rọ̀ tí ń panilẹ́kún pọ̀ lẹ́nu wọn. 15 Ẹsẹ̀ wọn má ń súwọn lọ ibi àtitẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. 16 Ìparun àti ìyà wà lọ́na wọn. 17 Àwọn èǹyàn wọ̀n yí kò mọ ọ̀nà ti álàfíà. 18 Ìbẹ̀ru Ọlọ́run ò jámọ́ ǹkankan lóju wọn." 19 Nísinsìnyí àwá mọ̀ pé gbogbo ohun tí òfin ńsọ, àwọn tó wà lábẹ́ òfin ni o ńbá wí. Ìlànà yí wà kí kẹ́kẹ́ pa mó gbogbo ẹnu, kí gbogbo àgbáyé le è jíyìn fún Ọlórun. 20 Ìdí ni pé kò sí ẹlẹ́ran ara kankan tí a ó dáláre nípa iṣẹ́ òfin níwájú Rẹ̀. Nítorí nípasẹ̀ òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ṣe wá. 21 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí yàtọ̀ sí ófin òdodo Ọlọ́run ti jẹ́ mímọ̀. Àti òfin ati àwọn wòlíì jẹ́ri síi, 22 pé, òdodo Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù f'áwọn tó gbàgbó. Nítorí kò sí ìyàtọ̀. 23 Nítorí gbogbo ènìyàn lótiṣẹ̀, tí wọ́n kò sì yẹ fún ògo Ọlọ́run, 24 wọ́n sì ti gba ìdáláre nípasẹ̀ ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà tí ó wà nínú Jésù Kristì. 25 Nítorí Ọlọ́run pèse Krístì Jésù fún wa gẹ́gẹ́ bíi ohun ètùtù nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínù ẹ̀jẹ Rẹ̀. Ó fi Jésù ẹ̀rí ìdájọ́ Rẹ̀, nítorí pé kò ka ẹ̀ṣẹ̀ tí ati ṣè sẹ́yìn mọ́ 26 nínú sùúrù Rẹ̀. Gbogbo eléyǐ ṣẹlẹ̀ láti fi òdodo Rẹ̀ hàn ní àkòkòyí. Èyí ríbẹ̀ kí Ó leè jệrí ara Rẹ̀ bíi olódodo, àti kí Ó fihàn pé Ò ń dá ẹnikẹ́ni láre nítorí ìgbàgbọ́ nínú Jésù. 27 Kíni ànfàni ìjàre-ẹnu? Kò wú lò. Lórí kìnni? Ṣé lórí iṣẹ́? Rárá, ṣùgbọ́n lórí ìgbàgbọ́. 28 A wá gbà wípé éníyán gba ìdáláré torí ìgbàgbọ́ láì sí iṣẹ́ òfin. 29 Tàbí ǹjẹ́ Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run Júù nìkan ni? Ǹjẹ́ kìí se wípé Òun náà ni Ọlọ́run Kèfèrí? Bẹ́ẹ̀ni, ti àwọn Kèfèrí náà. 30 Nígbà t'Ọ́lọ́run jẹ́ ẹyọkan, àtẹni t'ókọlà, àtẹni tí ò kọlà, Òun ni ó dáwọn láre nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. 31 Sé awá sọ òfin di asán nípa ìgbàgbọ́ ni? Kí ómá ríbẹ̀ láíláí! Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbè òfin ró.