Orí Kejì

1 Nítorí ìwọ kò ní àwáwí kankan, ìwọ ènìyaǹ, ìwọ tí o ńdájọ́, nítorí ohun tí ìwọ ńdájọ́ ní ti ẹlòmiràn ìwọ ńdá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ tó ńdájọ́ ńṣe àwọn ǹkankan náà. 2 Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run wà sí òtítọ́ nígbàtí ó bá dé sórí áwọn ẹnití wọn ńṣe ǹkan bẹ́ẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ro èyi, ìwọ ènìyaǹ, ìwọ tí o ńdájọ́ ẹnití ńse àwọn ǹkan bẹ́ẹ̀ biótilẹ̀jẹ́ wípé ìwọ ńṣe ǹkankan náà. Ǹjẹ́ ìwọ yóò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run bi? 4 Tàbí ìwọ rò wípé kékeré ni ọrọ̀ àánú Rẹ̀, ìlọ́ra ìjìyà Rẹ̀, àti sùúrù Rẹ̀? Ìwọ kò mọ̀ pe àánú Rẹ̀ yẹ kí ó darí rẹ sí ìrònúpíwàdà? 5 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí ìyigbì àti àinírònú pìwàdà ọkàn èyí tí ó ńmú ọ kó ìbínú pamọ́ di ọjọ ìbínú, èyí tí íṣe, ọjọ́ ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 6 Òun yóò san fún ẹnìkọ̀kan gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀: 7 sí àwọn gẹ́gẹ́bí ìdúrósinsin, àwọn iwà tó dáráa ti ó ni ìyìn, ọlá àti àìdibàjẹ́, Òun yóò gba iyè àìnípẹ̀kun. 8 Ṣùgbọ́n sí àwọn olùwá-ti-arawọn-nìkan, àwọn tíó ńṣe áìgbọràn ṣí òtítọ́ ṣùgbọ́n ṣe ìgbọràn sí àìsòdodo, ìbínú àti ìbínú gbígbóná yóò wáá. 9 Ọlọ́run yóò mú ìpọ́njú àti ìdàmú sórí gbogbo ọkàn ẹni tí ó ńṣe ibi, àkọ́kọ́ sí àwọn Júù, àti sí àwọn Gíríkì. 10 Ṣùgbọ́n ìyìn, ọlá, àti àlàáfíà ni yóò si ẹnikẹ́ni t'ó ńse rere, àkọ́kọ́ sí àwọn Júù, àti sí àwọn Gíríkì. 11 Nítorí kò sí ojúsàájú pẹ̀lú Ọlọ́run. 12 Fún gbogbo iye ènìyàn tí ó bá ti ṣẹ̀ làíse nípa òfin yóò parun làíse nípasẹ̀ òfin, àti gbogbo àwọn tó bá ṣẹ̀ nípasẹ̀ òfin ni a ò dá lẹ́jọ́ nípasẹ̀ òfin. 13 Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ràn sí òfin ni ó olódodo níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ò dáláre. 14 Nítorí àwọn Kèfèrí, àwọn tí wọn kò ní òfin, ńṣe nípa ara àwọn ǹkan ti òfin, àwọn wọ̀nyí jẹ́ òfin sí ara wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin. 15 Nípasẹ èyi wọn fihàn pe àwọn ìṣe èyítí òfin ńbèère fún a kọọ́ sínu ọkàn wọn. Bẹ́ gẹ́gẹ̀ ni ẹ̀ri ọkàn wọn ńjẹ́rìí sí wọn, àti àwọn èrò wọn yálà ó ńfi wọn sùn tabi ó ńdábòbò wọ̀n ọ́n sí ara wọn 16 àti pẹ̀lú sí Ọlọ́run. Èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ tí Ọlọ́run yóò ṣè ìdájọ́ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ìhìnrere mi, nípasẹ̀ Jésù Krístì. 17 Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá pe ara rẹ ní Júù àti wípé o dúró nínú òfin àti wípé ò ńsògo nínu Ọlọ́run, 18 àti wípé o mọ ìfẹ́ Rẹ̀ àti pé o mọ ohun tí ó dára ju nítorí a ti ńkọ́ ọ nínú òfin; 19 àti tí ìwọ bá ní ìdánilójú pe ìwọ tìkálára jẹ́ a fi ọ̀nà han àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà l'ókùnkùn, 20 olùtọ́ni àwọn aṣiwèrè, olùkọ́ àwọn ọmọ kékeré, àti wípé ìwọ ní ìmọ̀ nípa òfin àti nípa òtítọ́, ǹjẹ́ báwo ni àwọn ǹkan wọ̀nyí ṣe ń dí ọ lọ́wọ́ bí o se ńgbe ayé rẹ? 21 Ìwọ tí ò ńkọ́ àwọn ẹlòmíràn, ṣé ìwọ kò kọ́ ara rẹ bìí? Ìwọ tó ńwàásù má ṣe jalè, ǹjẹ́ ìwọ kò ńjalè bìí? 22 Ìwọ tí o ńsọ pé ki ẹǹkan má se àgbèrè, ǹjẹ́ ìwọ ńṣe kò àgbèrè bìí? Ìwọ tí o kórira àwọn òrìsà, ǹjẹ́ ìwọ kò má a jalè àwọn tẹ́mpílì bìí? 23 Ìwọ tí ò ńyayọ́ ìgbéraga nínú òfin, ṣé o ko má a tàbùkù Ọlọ́run nípa ìtàpà sí òfin? 24 Nítorí tí "orúkọ Ọlọ́run di ẹ̀gàn láàrin àwọn kèfèrí nítorí yín," gẹ́gẹ́bí a ti ṣe kọ́ sílẹ̀. 25 Nítorí ìkọlà nítòótọ́ ní èrè tí ìwọ bá pa òfin mọ́, ṣùgbón tí ìwọ bá rú òfin, ìkọlà rẹ di aláìkọlà. 26 Bí, nígbà náà, ènìyàn aláìkọlà bá pa àwọn ìlànà òfin mọ́, ǹjẹ́ àìkọlà rẹ̀ a kì yóò gbà á bí i ìkọlà bíí? 27 Ǹjẹ̀ ẹni tí kò kọlà kì yóò dá ọ lẹ́bi tí òun bá ńpa òfin mọ́ bíí? Nítorí pé ìwọ ní òfin tí a kọ sílẹ̀ àti ìkọlà, ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ ńrú òfin! 28 Nítorí ti kìí se Júù nípa ti ìwò òde nìkan, tàbí ìkọlà èyí tí ì se òde ti ara. 29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ṣe Júù ni ẹni ti inú, àti ìkọlà ni ti ọkaǹ, nínú Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ti òfin. Ìyìn irú ènìyàn bẹ́ ẹ́ kò wá láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.