Orí Kẹẹ̀jọ

1 Ní ọjọ́ wọǹnì, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, wọn kò sí ní oúnjẹ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, 2 “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí, nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà pẹ̀lú ù mi kò sì sí ohun tí wọn yóò jẹ. 3 Bí mo bá rán wọn lọ sí ilé wọn láì jẹun, wọn le dákú lójú ọ̀nà. Àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.” 4 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?” 5 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?” Wọ́n wípé, “Méje.” 6 Ó pàṣẹ fún ọ̀pọ ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó mú àkàrà méje náà, ó dúpẹ́, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́. Ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé sí iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. 7 Wọ́n tún ní àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó dúpẹ́, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. 8 Wọ́n jẹun wọ́n sì yó, wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. 9 Àwọn tí ó wà níbẹ̀ tó ìwọ̀n ẹgbàajì ènìyàn. Ó sì rán wọn lọ. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì lọ sí agbègbè Dálímánútà. 11 NÍgbànáà ni àwọn Farisí jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ń se àríyànjiyàn pẹ̀lú u rẹ̀. Wọ́n ń wá ààmì láti ọ̀run wá lọ́wọ̀ ọ rẹ̀, láti dán an wò. 12 Ó mí kanlẹ̀ ní ọkàn an rẹ̀ ó wípé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá ààmì? Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò si ààmì tí a ó fi fún ìran yín.” 13 Nígbà náà ni fi wọ́n sílẹ̀, ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà. 14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. 15 Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.” 16 Àwọn ọmọ ẹyìn sí bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni” 17 Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Sé ẹ̀yin kò kíyèsi ni? Sé kò tilẹ̀ yẹ yín ni? Tàbí ọkàn ti rẹ̀wẹ̀sì? 18 Ẹ̀yin ní ojú, sé ẹ kò ríran ni? Ẹ̀ ni etí, sé ẹ kò sí gbọ́ran? Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò rántí? 19 Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?” Wọ́n wí fún n pé, “Méjìlá.” 20 “ Nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ni ẹ kó jọ?” Wọ́n dáhùn pé, “Méje.” 21 Ó sì wí fún wọn pé, “Sé kò tilẹ̀ tíì yé yin ni?” 22 Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisaídà. Àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀ mú afọ́jú kan wá, wọ́n sì bẹ Jésù kí ó fi ọwọ́ kàn án. 23 Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Nígbà tí ó tu itọ́ sí i lójú, Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ rí ohunkóhun?” 24 Ó wo okè, ó wípé, “Mo rí àwọn ènìyàn ti wọ́n n rìn kiri bí igi.” 25 Nígbànáà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú rẹ̀, ọkùnrin náà sì la ojú u rẹ̀, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere. 26 Jesu sì rán an sí ilé e rẹ̀, Ó wí fún n pé, “Má ṣe lọ sí ìlú. " 27 Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Kesaréà Fílípì. Lójú ọnà, ó bi àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?” 28 Wọ́n dáhùn pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi. Àwọn mìíràn wí pé, "Èlíjàh", àwọn míràn si wípé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì."' 29 Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?” Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.” 30 Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni nípa òun. 31 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde. 32 Ó sọ èyí láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn. Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí. 33 Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì dá Pétérù lẹ́kun, “Kúrò lẹ́yìn mi, Sàtánì! Ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.” 34 Nígbànáà ni Jesu pe àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jọ, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó gbọ́dọ̀ sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. 35 Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù, ẹni tí ó bá sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. 36 Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? 37 Kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? 38 Ẹnikẹ́ni tó bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”