Orí Keèje

1 Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé tí wọ́n wá láti Jèrúsálẹ́mù pagbo yí Jésù ká. 2 Wọ́n ríi wípé àwọn kan nínú àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ̀ ń jẹhun pẹ̀lú ọwọ́ àìmọ́, eyí ni, láì fọwọ́ . 3 (Nítorípé àwọn Farisí àti gbogbo àwọn Júù kìí jẹhun láì jẹ́ pé wọ́n bá fọwọ́, nítorípé wọ́n fi ọwọ́ gidi mú àsá àwọn àgbààgbà. 4 Tí àwọn Farisí bá ti ọjà dé, wọn kìí jẹhun bíkòsepé wọ́n bá kọ́kọ́ wẹ ara wọn, bẹ́ẹ̀ni wọ́n sì di àwọn àsà míràn náà mú sinsin, bíi fífọ ife ìmumi, ìkòkò, ohun èlò idẹ, àti àwọn tábìlì tí wọ́n bá fi jẹhun.) 5 Àwọn Farisí àti àwọn Akọ̀wé bèèrè lọ́wọ́ ọ Jésù, wípé, "Kílódé tí àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ kìí rìn ní ìbámu pẹ̀lú àsà àwọn àgbààgbà, nítorí wọ́n jẹ oúnjẹ wọn láì fọwọ́." 6 Ṣùgbọ́n Ó wí fún wọn pé, "Ìsáyà sọtẹ́lẹ̀ dáradára nípa ẹ̀yin àgàbàgebè. Ó kọọ́ pé, àwọn ènìyàn yíì ń fi ètè wọn bu ọlá fún mi, sùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí ọ̀dọ̀ mi. 7 Ìjọ́sìn tí kò wúlò ni wọ́n ń fún mi, wọ́n ń kọ̀ni ní ìlànà ènìyàn bíi àgbékalẹ̀ ara wọn.' 8 Ẹ pa òfin Ọlọ́run tì, ẹ sì di àsà ènìyàn mún sinsin." 9 Ó sì tún wí fún wọn pé, "Ẹ rò pé ẹ ti se ohun tí ó dára tó lójú ara yín, tí ẹ kọ òfin Ọlọ́run kí ẹ le se àmúlò àsà àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín!" 10 Sebí Mósè wípé, 'Bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ,' àti wípé, 'ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ bàbá tàbí ìyá rẹ̀ làì dára kíkú ni yíó kùú.' 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé, 'Bí ènìyàn kan bá sọ fún bàbá tàbí ìya rẹ̀ pé, "Ìrànlọ́wọ́ yòówù tí ó yẹ tí o kò bá rí gbà lọ́wọ́ọ̀ mi Kóbánì ni,"' (èyí ni, "Mo ti fi fún Ọlọ́run")- 12 Ẹ kò wá jẹ́ kí ọmọ le se ǹkankan fún bàbá tàbí ìya rẹ̀ mọ́. 13 Ẹ ń pa òfin Ọlọ́run rẹ́ nípa àsà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ẹ gbé kalẹ̀. àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan bíi irú ìwọ̀nyí ni ẹ se. 14 Ó tún pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Ó sì wí fún wọn pé, "Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ tẹ́tí gbọ́ mi, kí òye kí ó sì yé yín. 15 Kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmó nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn. Bíkòse ohun tí ó jáde wá láti inú ènìyàn sí ìta ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìse, ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́." 16 "Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, jẹ́ kí ó gbó." 17 Ní àkókò yìí, nígbàtí Jésù kúrò lọ́dọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà tí Ó sì wọ inú ilé, àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ̀ bií léèrè ìbéèrè lórí òwe náà. 18 Jésù dá wọn lóhùn wípé, "Ẹ̀yin kò tún tíì lóye èyí náà ni bíí? Sé ẹ kò tíì ri pé kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmọ́ nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn, 19 nítorípé kò le wọ inú ọkàn lọ, ṣùgbọ́n ó ń lọ sí inú ikùn ènìyàn tí yíó sì gba ibẹ̀ di ohun tí a ya ìgbẹ́ rẹ̀ sí ilé ìyàgbẹ́?" Jésù sọ gbogbo ohúnjẹ di mímọ́ pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí. 20 Ó wípé, ọ̀rọ̀ àti ìse tí ó jáde wá láti inú ènìyàn sí òde ni ó ń sọ ènìyàn di aláaìmọ́. 21 Nítorípé nínú ènìyàn, láti inú ọkàn wá ni àwọn èrò burúkú ti ń jáde wá, ìsekúse, olè jíjà, ìpànìyàn, 22 panságà, ojúkòkúrò, ìkà, ẹlẹ̀tàn, ọlọgbọ́n lójú ara rẹ̀, ìlàra, abaníjẹ́, agbéraga, aláìnírònú. 23 Láti inú ọkàn ni gbogbo ibi wọ̀nyí ti máa ń jáde wá, àwọn ló sì ń so ènìyàn di aláìmọ́." 24 Ó sì dìde kúrò níbẹ̀, Ó sì lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì. Ó wọ inú ilé kan, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ pé Òun wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò le sápamọ́n fún wọn. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọ rè ní ẹ̀mí àìmọ́, gbọ́ nípa rẹ̀, ó wá, ó sì kúnlẹ̀ sílẹ̀ ní ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. 26 Ara Gíríkì ni obìnrin náà ń se, ọmọ bíbí Sirofẹ́níkà níí se. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí èsù inú ọmọbìnrin òun jáde. 27 Jésù wí fún un pé, "Jẹ́ kí àwọn ọmọ ilé Ísrẹ́lì kọ́kọ́ jẹhun ná, nítorípé kò dára kí á wá lọ gbé ohunjẹ àwọn ọmọ kí á lọ gbée fún àwọn kéfèrí." 28 Ṣùgbọ́n Obìnrin yìí dáhùn, ó wí fún Jésù pé, "Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, àwọn kèfèrí pàápàá le jẹ ẹ̀rúnrún ohúnjẹ àwọn ọmọ Ísrẹ́lì tí ó bá bọ́ sí ilẹ̀ láti oríi tábìlì." 29 Ó wí fún un pé, "Nítorítí ìwọ́ sọ èyí, máa lọ lómìnira. Ẹ̀mí èsù náà ti jáde kúrò làra ọmọbìnrin rẹ." 30 Obìnrin náà sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ó sì bá ọmọbìnrin rẹ̀ tí ó ń sùn lóríi bẹ́ẹ̀dì, àti wípé ẹ̀mí èsù náà ti fíi sílẹ̀ lọ. 31 Jésù tún kúrò ní agbègbè Tírè, Ó sì gba inú Sídónì lọ sí òkun Gálílì, ní ìgòkè lọ sí agbègbè Dẹ́kápólísì. 32 Àwọn ènìyàn gbé ẹnìkan tí kò gbọ́ ọ̀rọ̀, tí ó sì nira fún láti sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ wípé kí Jésù wòó sàn. 35 34 Jésù mú ọkùnrin náà jáde sí ẹ̀gbẹ́ kan kúrò láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyan, Ó sì ń fi ìka rẹ̀ bọ ọkùnrin nàà létí, lẹ́yìn ìgbàtí Ó tutọ́ sí ọwọ́ Rẹ̀, Ó fi ọwọ́ kan ọkùnrin náà ní ahọ́n. 33 Jésù gbé ojú wo òkè ọ̀run, Ó mí kanlẹ̀, Ó wí fún ọkùnrin náà pé, "Éfátà" èyí tíí se "Ṣí!" Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ etí ìgbọ́ràn rè sì ṣí, Jésù sì tú ahọ́n rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlé sọ̀rọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ yékéyéké. 36 Jésù kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n máse sọ fún ẹni kankan. Sùgbọ́n bí Ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń polongo Rẹ̀ síi. 37 Ẹnu ya àwọn ènìyàn kọjá gidigidi, wọ́n sì ń wípé, "Ó ti se gbogbo ǹkan dáradára. Ó mú kí adití gbọ́ràn, Ó sì mú kí ẹnití kò le sọ̀rọ̀ di ẹnití ó ńsọ̀rọ̀."