Orí kẹẹ̀wá.

1 Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ ó lọ sí agbègbè Jùdéà àti sí ìkọjá odò Jọ́rdánì, ọ̀pọ̀ àwọn èrò sì tún tọ̀ọ́ wá. ó tún nkọ́ wọn lẹ́ẹ̀kan si gẹ́gẹ́bí ó ti má n se. 2 Nígbànáà ni àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ọ rẹ̀ láti dán-an wò wọ́n bèrè wípé, " ǹjẹ́ ó bá òfin mu kí ọkọ kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?" 3 ó dá wọn lóhùn, " kínni Mósè palásẹ fún yín?" 4 Wọ́n wípé, "Mósè fi àyè gba ọkùnrin láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ kí ó sì lée jáde." 5 "Nítorí ọkàn líle yín ni ó se kọ òfin wọ̀nyí fún yín," Jésù wí fún wọn bẹ́ẹ̀. 6 Ṣùgbọ́n láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìṣẹ̀dá, 'Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo'. 7 'Fún ìdí èyí ni ọkùnrin yó se fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yò si faramọ́ aya rẹ̀, 8 àwọn méjèejì yó sì di ara kàn.' wọ́n kìí sì se méjì mọ́, bí kò se ara kàn. 9 Nítorínàa, ohun tí Ọlọ́run bá ti so pọ̀ di ọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má se pín wọn lọ́tọ̀ọtọ̀." 10 Nígbàtí wọ́n wà nínú ilé, àwọn ọmọ ẹyìn bèrè lẹ́ẹ̀kan si nípa èyí. 11 Ó wí fún wọn pé, "ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí ó si gbé obìnrin míràn ní ìyàwó ó se panságà síi. 12 Bí obìnrin bá kọ ọkọ rẹ sílẹ̀ tí ó si fẹ́ ọkùnrin míràn, ó se panságà." 13 Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn ọmọ wọn wẹẹrẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó le fi ọwọ́ kàn wọ́n, sùgbọ́n àwọn ọmọ ẹyìn bá wọn wí. 14 Ṣùgbọ́n nígbàtí Jésù se àkíyèsi rẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn rárá ó sì wí fún wọn pé "ẹ jẹ́kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ máse dí wọn lọ́wọ́, nítorí ìjọba Ọlọ́run wà fún àwọn tó dàbí wọn. 15 Lóòtọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá fẹ gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kan dájúdájú kò ní leè wọlé sí ibẹ̀." 16 Lẹ́yìn náà ó gbé àwọn ọmọ kékeré sí apáa rẹ̀ ó sì bùkún fún wọn bí ó se ńgbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn. 17 Nígbàtí ó bẹ̀rè ìrìnàjò rẹ̀, ọkùnrin kàn sáré tọ̀ọ́ wá ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹẹ̀, ó bèrè " Olùkọ́ni rere, kínni èmi yóò se kín lè jogún iyè ayérayé?" 18 Jésù wípé, kínni ìdí tí o fi pè mí ní rere? Kò sí ẹni rere kan, à fi Ọlọ́run. 19 Ìwọ mọ àwọn òfin: 'máse pànìyàn, máse se panságà, máse jalè, máse jẹ́ẹ̀rí èké, máse rẹ́nijẹ, bu ọlá fún bàbá àti ìyá rẹ'." 20 Okùnrin náà wípé, "Olùkọni, gbogbo ǹkan wọ̀nyí ni mo ti gbọ́ràn sí láti ìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́" 21 Jésù wòó ó sì fẹ́ẹ. Ó wí fún pé, " ohùn kan ni o kò ní. O gbọ́dọ̀ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì fi fún àwọn aláìní, ìwọ yó sì ní ìsura ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà wá, máa tẹ̀lé mi" 22 Sùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ yí ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ kúrò pèlú ìbànújẹ́ ọkàn, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 23 Jésù sí wo àyíká ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, "báwo ni yó ti nira tó fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ íjọba Ọlọ́run! 24 "Ẹnú ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí àwọn ọ̀rọ̀ọ rẹ̀. Sùgbọ́n Jésù tún sọ fún won lẹ́ẹ̀kan si, " Ẹ̀ yin ọmọdé, báwo ni yó se nira tó láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Ó rọrùn fun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba Ọlọ́run" 26 Ẹnú sì yà wọ́n gidigidi wọ́n sì ńbá ara wọn sọ̀rọ̀, "taani yóò wá le là bá yì?" 27 Jésù wò wọ́n ó wípé, "pẹ̀lú ènìyàn ó sòro se sùgbọ́n kò rí bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí ohun gbogbo ni síse fún Ọlọ́run." 28 Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí báa sọ̀rọ̀, "wòó a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ a sì ti tẹ̀lé ọ." 29 Jésù wípé, lóòtọ́ ni mo wí fún yin, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí ìyá tàbí bàbá tàbí àwọn ọmọ tàbí ilẹ̀ nítorí tèmi àti nítorí ìyìn-rere 30 tí kì yóò gbàá ní ìlọ́po ọgọ́rùnún ní ayé yìí: ilé àti, arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá àti àwọn ọmọ àti ilẹ̀ pẹ̀lú inúnibíni àti ní ayé tí ńbọ̀ iyè aìnípẹ̀kun. 31 , Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ẹni iwájú ní yóò di ẹni ẹ̀yìn àti ẹni ẹ̀yìn yóò sì di ẹni iwájú." 32 Wọ́n wà lójú ọ̀nà wọ́n ńlọ sí Jèrúsálẹ̀mù, Jésù sí ńlọ níwájú wọn. Ẹnú ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àti àwọn tí ò ǹtẹ̀le wọn lẹ́yìn ni ẹ̀rù síì ńbà. Lẹ́yìn náà Jésù mú àwọn méjìlá sí ẹ̀gbẹ́ kan ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí òun ní kòpẹ́kòpẹ́. 33 "wòó, àwa ńgòkè lọ sí Jèrúsálẹ̀mù, a ó sì fi ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé lọ́wọ́. Wọn ó dáa lẹ́bi ikú wọn ó sì fi lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́. 34 Wọn ó fi se ẹlẹ́yà, wọn ó tu itọ́ sí lára, wọn ó nàá pẹ̀lú ẹgba, wọn ó sì paá. Sùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ kẹ̀ta yó dìde. 35 Jákọ́bù àti Jòhánnù, àwọn ọmọ Ṣébédè gòkè wá sọ́dọ́ rẹ̀ wọ́n wípé, "Olùkọni, àwa fẹ́ kí ẹ se ohunkóhun tí a bá bèrè fún wa" 36 Ó bi wọ́n pé, kínni ẹ fẹ́ kí èmi ó se fún yín?" 37 "Wọ́n wípé, gbà wá láàyè láti jókòó pẹ̀lú rẹ nínú ògo, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ." 38 Jésù dá wọn lóhùn, ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀yin ńbèrè. Ẹ̀ yín a le mu ife tí èmi yóò mu tàbí farada ìtẹ̀bọmi tí a ó fi rì mí bọmi?" 39 Wọ́n wí fún pé, "àwa leè sé" Jésù wí fún wọn pé , ife tí èmi yóò mu ni ẹ̀yin náà yóò mu àti ìtẹ̀bọmi tí èmi ó se ni aó se fún ẹ̀yin náà. 40 Ṣùgbọ́n, ẹni tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi, kìí se tèmi láti fúnni bíkòse àwọn tí a ti pèsèe rẹ̀ sílẹ̀ fún." 41 Nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́ẹ̀wá yó kù gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí Jákọ́bù àti Jòhánnù. 42 Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ó wípé, "ẹ̀yín mọ̀ pé àwọn tí a kà sí olórí láàrín àwọn kèfèrí má ńlo ipá lórí wọn àti àwọn alásẹ àgbà ńlo ipò àsẹ lórí wọn. 43 Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàrín yín. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di gíga nínú yín yóò se ọmọ ọ̀dọ̀, 44 àti ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ se asájú nínú yín yóò se ìránsẹ́ gbogbo won. 45 Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá pé kí á se ìránsẹ́ fún òun bíkòse láti se ìránsẹ́ fún ẹlòmíràn àti láti yònda ara rẹ̀ fún ìràpàdà ọ̀pọ̀lọpọ̀." 46 Wọ́n wá sí Jẹ́ríkò. Bí ó se fi Jẹ́ríkò sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò, ọmọ Tíméaù, Bátólóméù afọ́jú tí ó ntọrọ, jókòó ní ẹ̀bá ọ̀nà. 47 Nígbàtí ó gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ síi kígbe wípé, "Jésù ọmọ Dáfídì sàánú fún mi". 48 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló bá afọ́jú náà wí, pé kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ó kígbe lóhùn rara síi "ọmọ Dáfídì sàánú fún mi!" 49 Jésù dúró ó sì pàsẹ pé kí wọ́n pèé wá. Wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, Ó ńpè ọ́ se bi akin! dìde! Ó ńpè ọ́." 50 Ó ju asọ rẹ̀ sí apákan ó dìde wá sọ́dọ̀ Jésù. 51 Jésù dáhùn ó wípé, "Kínni ìwọ́ ńfẹ́ kí èmi kí ó se fún ọ?" Ọkùnrin afọ́jú náà wípé, Rábbì , mo fẹ́ kín rí ran." 52 Nígbànáà ni Jésù wí fun pé, máa lọ ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá" Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rí ran lẹ́ẹ̀kan si, ó sì ńtẹ̀lé wọn lẹ́yìn lójú ọ̀nà.