Orí Kokànlá

1 ti won si de Jerusalemu, won sun mo Betifeji ati Betani, ni ori oke olifi, Jesu si ran awon omo eyin re meji jade 2 O si wi fun won pe, "e lo si abule ti o koju si wa. Ni kete ti e ba ti wo inu re, e o ri ketekete kan ti a ko gun ri. E tu ki e si mu wa fun mi. 3 Ti enikeni ba so fun yin wipe, 'kilode ti en tu?' E da lohun wipe Oluwa nilo re yio si daa pada kankan. 5 4 Won si lo, won ri kekete kan ti a so mo enu ona ni ita gbangba ni adugbo, won si tu. 5 Awon eniyan kan si duro nibe ti o wi fun won pe, "ki ni eyin n se, ti e n tu ketekete?" 6 Won si da won lohun gege bi Jesu ti so fun won, awon eniyan naa si je ki won lo ni ona ti won. 7 omo eyin meji naa mu ketekete naa wa sodo Jesu won si te aso won sori re ki Jesu le gun ketekete naa. 8 Opo eniyan si te aso won sile ni oju ona, awon miran si te imo ti won ti ge lati inu oko. 9 Awon ti o nlo niwaju re ati awon ti o n bo lehin re n kigbe, "Hosana! Ibukun ni eni ti o wa ni oruko Oluwa. 10 Ibukun ni fun ijoba baba wa Dafidi ti n bo wa! Hosana ni ibi giga julo." 11 Leyin naa ni Jesu wo Jerusalemu, O si wo inu tempili, o wo gbogbo ohun ti o wa ni ayika. Ile si ti su ni akoko naa, O si jade lo si Betani pelu awon omo eyin mejila. 12 Ni ojo keji, nigbati won pada de lati Betani, ebi si n paa. 13 O si ri igi opoto kan ti o ni ewe ni ookan, O si lo lati wo boya O leri eso ni ori re, ni gba ti o si de idi igi naa, ko ri eso kan lori re bikose ewe, nitori ki n se asiko eso opoto. 14 O si soro si, "ko si eniti yio je eso lori re mo." Awon omo eyin re si gbo. 15 Won si wa si Jerusalemu, O si wo inu tempili, O si bere si n le awon tin ra tin ta ninu tempili jade. O si da tabili awon tin se pasiparo owo ati ijoko awon tin ta eyele nu. 16 Ko gba enikeni laye lati gbe oja tita wonu tempili. 17 O si ko won wipe, Se bi ati ko wipe "a o ma pe ile mi ni ile adura fun gbogbo orile ede? Sugbon eti so di ogba awon ole. 18 Awon olori alufa ati awon akowe gbo ohun ti o so, won si n wa ona lati pa. Nitori won beru re tori opo ero ti enu ya nitori eko re. 19 Nigba ti o di irole, won fi ilu naa sile. 20 Bi won se n rin lo ni owuro, won ri igi opoto naa ti o ti gbe de gbongbo re. 21 Peteru ranti o si wipe, "Olukoni, wo o! Igi opoto ti efi re ti gbe danu." 22 Jesu si dahun wipe, "Eni igbagbo ninu Olorun 23 Looto ni mo so fun yin enikeni to ba so fun oke, 'dide gera re so sinu okun,' ti ko si siyemeji ninu okan re sugbon ti o gbagbo pe ohun ti o so yio sele, bee gege ni Olorun yio se. 24 Nitorina mo wi fun yin, gbogbo ohun ti eyin ba gbadura ti e si beere fun, e gbagbo pe e ti ri gba, yio si di ti yin. 25 Nigbati eyin ba duro lati gbadura, e dari ji eniti o se yin, ki baba yin tin be lorun le dari ese ti yin naa ji yin. 26 Sugbon ti eyin ko ba dariji, baba yin tin be ni orun ko ni dariji eyin naa. 27 Won tun wa si Jerusalemu lekan sii. Bi Jesu ti n rin lo ninu tempili, awon olu alufa, awon akowe, ati awon agbaagba wa sodo re. 28 Won si bere lowo re pe, "labe ase wo ni iwo ti n se awon nkan wonyi, ati wipe tani o fun o lase lati se won?" 29 Jesu si dawon lohun wipe, "emi a bere ibere kan lowo yin, e dami lohun emi o si so fun yin nipa ase ti mo fi n se awon nkan wonyi. 30 Iribomi ti Johanu, se lati orun wa ni tabi lati owo eniyan? e wi fun mi" 31 Won se asaro larin ara won wipe, "ti a ba so wipe, 'lati orun', oun a dahun pe 'kilo de ti e ko fi gba a gbo?' 32 Sugbon ti a ba so wipe, 'lati owo eniyan'...." Eru awon eniyan n ba won, nitori gbogbo eniyan ni o daloju pe woli ni Johanu. 33 Leyin naa won da Jesu lohun wipe, "awa ko mo." Jesu si wi fun won pe, "Emi naa ko ni so fun yin nipa ase ti mo fi se awon nkan wonyii.