Orí kẹ́sàń

1 Jésù sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó rékọjá, ó sì wá sí inú ìlú òun tìkara rẹ̀. 2 Sì wóó, nwọ́n gbé ọkùnrin arọ kan tọ̀ọ́ wá lórí ẹní. Nígbàtí ó kíyèsí ìgbàgbọ́ wọn, Jésù sọ fún ọkùnrin arọ nà pé, "Ọmọ, tújúká. A ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jìn ọ́." 3 Sì wó, àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé sọ láarín ara wọn pé, "Ọkùnrin yi ńsọ ọ̀rọ̀ òdì." 4 Jésù mọ àwọn èrò ọkàn wọn ó sì wípé, "Kílódé tí ẹ fi ńro èrò ibi nínú ọkàn yín? 5 Ǹjẹ́ èwó ni ó rọrùn láti sọ, 'A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jìn ọ́' tàbí kí á wí pé, 'dìde kí o sì rìn'? 6 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó le mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní àṣẹ láyé láti dárí ẹ̀ṣẹ́ jin ni,... "ó sọ fún arọ náà pè, "dìde, gbé ẹní rẹ, kí o sì má a lọ sí ilé rẹ̀ ẹ." 7 Nígbà nàá ni ọkùnrin náà dìde ó sì lọ sí ilé rẹ̀. 8 Nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò rí èyí, ẹnu yà wọ́n, nwọ́n si yin Ọlọ́run lógo, tí ó ti fi àṣẹ irú èyí fún ènìyàn. 9 Bí Jésù sì ti kọjá lọ kúrò ní ibẹ̀, ó rí arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Máttíù, tí ó jòkó ní ibùdó (ibùjókòó) àwọn agbowó orí. Ó (Jesu) sì sọ fún "Tẹ̀ lé mi". Ó sì dìde ó tẹ̀ le e. 10 Bí Jésù ti jòkó láti jẹun nínú ilé, sì wòó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbowó orí àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ènìyàn sí wàá, nwọ́n sì bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ Jẹun. 11 Àwọn amòfin rí i, nwọ́n sọ fún àwọn ọmọ ẹyìn, "Kílódé tí Olùkọ́ yiń ńjẹun pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ènìyàn?" 12 Nígbàtí Jésù gbọ́ èyí, Ó wípé, "Ènìyàn tí ara rẹ̀ yá kò nílò olùwòsàn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dàá 13 Ó yẹ kí ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ èyí, 'Èmi ńfẹ́ àánú, kì í sì ǹṣe ẹbọ'. Nítorí tí èmi kò wá fún àwon olódòdo láti yípadà ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. 14 Ní ìgbánà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù sì tọ̀ ọ́ wá, nwọ́n sì wípé, kílódé tí àwa àti àwon amòfin ma ńsábà gba àwẹ̀ ṣùgbọ́n ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kò gba à àwẹ̀? 15 Jésù sì wí fún wọn pé, ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe fún àwọn alágbàṣe níbi ìgbéyàwó kí wọn ní ìbánújẹ́ nígbàtí ọkọ ìyàwó si wa pẹ̀lu wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ńbọ̀ tí aa gba ọkọ ìyàwó kùrò lọ́dọ̀ọ wọn, nígbàńàà nwọ́n ó gba ààwẹ̀. 16 Kò sí ẹnìkan tí ó le rán awẹ́ aṣọ tuntun mọ́n àkísà, nítorí tí yíò yà kúrò lára odindi aṣọ ná à, yíya ńà yóó sì ní agbára. 17 Bẹ́ẹ̀sìni àwon ènìyàn kò le da wáìǹì tuntun sí inú àlòkù ìgò wáìǹì. Tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ ẹ̀, awọ na yóò ya, wáìǹì ná á sì dànù, ìgò wáìǹì na yíò bàjẹ́. Bíkòṣe, nwọ́n ó ò da wáìǹì tuntun sí inú ìgò wáìǹì tuntun, nígbàńàà ni àwọn méjèèjì yíò jọ wà. 18 Nígbàtí Jésù ńsọ àwọn ǹkan wọ̀nyí fún wọn, sì wò ó, oníṣẹ́ ìjọba kan sì wá, ó sì fi orí balẹ̀ fún n. Ó sì wí fún n "ọmọbìnrin mi sì ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni, ṣùgbọ́n wá, kí o sì wá gbé ọwọ́ rẹ lée, yíò sì yè. 19 Nígbàńà ni Jésù díde ó sì tẹ̀ lé e, àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn bákanáà. 20 Sì wòó, arábìnrin kan tí ẹ̀jẹ̀ ńya lára rẹ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ fún ọdún méjìlá, tọ Jésù wà á, ó dúró lẹ́yìn rẹ̀ ó sì fi ọwọ́ kàn etí aṣọ Rẹ̀ ẹ̀. 21 Nítorí tí ó wí fún arà rẹ̀ pèé, bí èmi bá fi ọwọ́ kan aṣọ Rẹ̀ ẹ̀, a ó sì mú mi láradá. 22 Ṣùgbọ́n Jésù yí ojú padà, ó sì wó, ó sì wí fun n pé, "Ọmọbìnrin, mú ọkàn le; ìgbàgbọ́ rẹ́ ti mú ọ láradá. Lọ́gán, obìnrin náà sì rí ìwòsàn ní wákàtí náà. 23 Nígbàtí Jésù dé ilé oníṣẹ́ ìjọba, ó rí àwọn a fun fèrè ati ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èrò tí wọ́n pariwo. Ó wípé, 24 "Ẹ lọ kúrò, nítorí tí ọmọbìnrin náà kò kú, ó kàn sùn ni." Ṣùgbọ́n gbogbo wọn sí fi rẹ́ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25 Nígbàtí nwọ́n sì ti lé àwọn èrò ná à jáde, ó wọ inú yàrá ó sì di ọmọ ná lọ́wọ́ mú, ọmọbìnrin ńà sí dìde. 26 Ìròyìn nípa èyí sì kàn káàkiri gbogbo àgbègbè náà. 27 Bí Jésù ti ńlọ kúrò ní ibẹ̀, àwọn ọkùnrin afójú méjì sí ǹ tẹ̀ le e. Nwọ́n sì ń pariwo, nwọ́n wípé, "Ṣàánú fún wa, Ọmọ Dáfídì" 28 Nígbàtí Jésù sí tì wọ inú ilé, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjèèjì tọ̀ ọ́ wá. Jésù sọ fún wọn pé, "Ǹjẹ́ ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo lè ṣe èyí?" Nwọ́n sì wípé, "Béèni i, Olúwa." 29 Nígbànáà ni Jésù fi ọwọ́ kan Ojú wọn ó sì wípé, "Jẹ́ kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí i ìgbàgbọ́ yiń." 30 Ojú wọn sí làà. Jésù si pàṣe fún wọn gidigidi wípé, "Ẹ ri dájú pe kò sí ẹnìkan tí ó mọ̀ nípa èyí." 31 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin méjèèjì lọ jáde nwọ́n sì pín ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà káàkiri gbogbo àgbègbè ná à. 32 Bí àwọn ọkùnrin méjèèjì ti ńlọ kúrò, sì wó, ọkùnrin odi kan tí ẹ̀mí èṣù ńgbé inú rẹ̀ ni wọ́n gbé wá sọ́dọ̀ Jésù. 33 Nígbàtí ó ti lé ẹ̀mí èsù náà jáde, ọkùnrin odi náà sí sọ̀rọ̀. Ẹnú ya gbogbo ọ̀pọ̀ èrò nwọ́n sì wípé, "A ò tíì rìí ìrú èyí rí tẹ́lẹ̀ ni Ísíráẹ́lì!" 34 Ṣùgbọ́n àwọn amòfin ńwípé, "Nípasẹ̀ olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó ńlé ẹ̀mí èṣù jáde." 35 Jésù lọ káàkiri àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé. Ó sì tẹ̀síwájú láti máa kọ́ni ní sínágógù wọn, ó ń wàásù ìhìnrere ìjọba, ó sì wo oríṣiríṣi àwọn ààrùn àti àilera sàn. 36 Nígbàtí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò, ó sì bojú àánú wò wọ́n, nítori tí nwọ́n dàmú àti wípé àárẹ̀ ọkàn mú wọn. Nwọ́n dàbí àgùtàn tí kò ní olùsó. 37 Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, "Ìkórè pọ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kéré. 38 Nítorínà ẹ gbàdúrà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí Olúwa Ìkórè , kí ó ba le rán àwọn alágbàṣe jáde lọ fún Ìkórè rẹ̀."