Orí Kẹẹ̀wá

1 Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ méjìlá papọ̀, ó sì fún wọn ní àsẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́, láti lé wọn jáde, àti láti wo orísìrísìí àrùn ati onírúurú àìsàn sàn. 2 Orúkọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá náà nì wọ̀n yí. Àkọ́kọ́, Símónì (ẹnití Ó tún pè ní Pétérù), àti Áńdérù tí ó jẹ́ arákùnrin rẹ̀; Jémísì ọmọ Sébédè, àti Jòhánù tí ó jẹ́ arákùnrin rẹ̀; 3 Fílípì, àti Batilómẹ́ù; Tómásì, àti Máttíù agbowó orí; Jémísì ọmọ Álfáúsì, àti Tádẹ́úsì; 4 Símónì ajíjágbára, àti Júdásì Ìsìkáríotù, ẹni tí ó sẹ́ Jésù. 5 Àwọn méjìlá yǐ ni Jésù rán jáde. Ó sì wí fún wọn pé, "Ẹ má se lọ sí ibi tí àwọn kèfèrí ba ń gbé, ẹ má sì se lọ sí ìlú tí ó jẹ́ ti àwọn ará a Samáríà. 6 Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israeli tí ó sọnù; 7 bí ẹ sì ti ń lọ, ẹ wàásù kí ẹ sì wípe, 'Ìjọba ọ̀run sún mọ́.' 8 Wo aláìsàn sàn, ẹ jí òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì lé àwọn ẹ̀mí òkùnkùn jáde. Ọ́fẹ́ ni a fi fún n yín, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fún ni. 9 Ẹ má se mú wúrà, fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìpamọ́ yín. 10 Ẹ má se gbé báàgì dání fún ìrìn àjò yín, tàbí asọ, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá, nítorí òsìsẹ́ yẹ fún oúnjẹ rẹ̀. 11 Ìlú kílǔ tàbí abúlé tí ẹ bá wọ̀, ẹ se ìwádǐ ẹnití ó yẹ níbẹ̀, kí ẹ sì dé sí ọ̀dọ rẹ̀ títí ẹ ó fi kúrò níbẹ̀. 12 Bí e bá wọlé, ẹ kí wọn 13 Bí ilé náà bá yẹ, kí àlááfìà yín kí ó wá sórí rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ilé náà kò bá yẹ, kí àlááfìà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín. 14 Fún àwọn tí kò gbà yín tàbí tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ yín, nígbàtí ẹ bá kúrò ní ilé tàbí ìlú náà, ẹ gbọ́n iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ yín kúrò. 15 Lóǒtọ́ ni mo wí fún n yín, ó sàn fún ilẹ̀ Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún ìlú náà. 16 Wò ó, mo rán an yín jáde gẹ́gẹ́ bí àgùntàn láarín àwọn ìkokò, nítorínà ẹ gbọ́n bí àwọn ejò, kí ẹ sì jẹ́ aláìlúwu bí àwọn àdàbà. 17 Ẹ ṣọ́ra fún enìyàn! Nítorí wọn yóò jọ̀wọ́ yín fún àwọn ìgbìmọ̀, wọn á sì nà yín nínú Sínágọ́gù wọn. 18 Wọn á sì mú u yín wá sí ọ̀dọ àwọn Gómínà àti àwọn ọba nitorí tèmi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn kèfèrí 19 Nígbàtí wọ́n bá sì jọ̀wọ́ yín, ẹ máse se àníyàn nípa báwo tàbí ohun tí ẹ̀yin ó sọ, nítorí a ó fun yín ní ohun tí ẹ̀yin ó wí ní àkókò náà. 20 Nítorí ẹ̀yin kọ́ lẹ ó ò sọ̀rọ̀; ṣùgbọ́n Ẹ̀mi Bàbá yín ni ó sọ̀rọ̀ jáde nínú yín. 21 Arákùnrin yóò jọ̀wọ́ arákùnrin rẹ̀ fún ikú, àti bàbá ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò dìde lòdì sí àwọn òbí wọn láti jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n. 22 A ó kórira yín nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n, ẹnití ó bá forítǐ dé òpin, ni a ó gbàlà. 23 Nígbàtí wọ́n bá pọ́nyínlójú ní ìlú yǐ, ẹ sá lọ sí òmíràn, nítorí looto ni mo wí fún yín, ẹ kò tí ì le la gbogbo ìlú Israeli kọjá tán kí Ọmọ Ènìyan yóò fi dé. 24 Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹrú kò ju olúwa rẹ̀ lọ. 25 Ó tó fún ọmọ ẹ̀yìn kí ó dàbí olùkọ́ rẹ̀, àti fún ẹrú bí olúwa rẹ̀. Bí wọ́n bá pe baálé ilé ní Bélísẹ́búlù, orúkọ búburú wo ni wọn yóo pe àwọn ẹni tí ó ń gbé inú ilé rẹ̀! 26 Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tí ó wà ní ìpamọ́ tí kò ní fara hàn, kò sì sí ohun àṣírí tí a kò ní mọ̀. 27 Ohun tí mo sọ fun yín níkọ̀kọ̀, ẹ sọ ọ́ ní gbangba, ohun tí ẹ gbọ́ ní ìdájẹ́jẹ́, ẹ kéde rẹ̀ lórí òrùlé. 28 Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n pa ara, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ṣebí meji kọbọ ni wọ́n ń ta ológoṣẹ́?Sibẹ ọ̀kan ninu wọn kò lè jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn Baba yín. 30 Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni ó níye. 31 Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ níye lórí pupọ ju ológoṣẹ́ lọ. 32 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú eniyan, Èmi náà yóo jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Bàbá à mi tí ń bẹ lọ́run. 33 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá sẹ́ mi níwájú eniyan, Èmi náà yóo sẹ́ ẹ níwájú Bàbá à mi tí ń bẹ lọ́run. 34 “Ẹ má rò pé mo wá láti mú alaafia wá sáyé. N kò wá láti mú alaafia wá, bíkòse idà. 35 Nítorí mo wá láti dá ìyapa sílẹ̀, láàrin ọmọkunrin ati baba rẹ̀, láàrin ọmọbinrin ati ìyá rẹ̀, ati láàrin iyawo ati ìyá ọkọ rẹ̀. 36 Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni. 37 Ẹnití ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. 38 Ẹni tí kò bá gbé agbelebu rẹ̀, kí ó máa tẹ̀lé mi, kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Sùgbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóò rí i. 40 Ẹni tí ó bá gbà yín, èmi ni ó gbà, ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó fi iṣẹ́ rán mi. 41 Ẹni tí ó bá gba wolii ní orúkọ wolii yíò gba èrè wolii, ẹni tí ó bá gba olódodo nítorí ó jẹ́ olódodo yóo gba èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fún ọ̀kan nínú àwọn kékeré yǐ, àní ife omi tútù mu, nítorí tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin, lóotó ni mo wí fún n yín, kò ní sọ èrè rẹ̀ nù.