Orí kọkànlá

1 Ó sìṣe nígbà tí Jésù ti parí fífi ìtóni fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá rẹ̀ tán, ó kúrò níbẹ̀ láti kọ́ni àti láti wàásù nínu àwọn ìlú wọn. 2 Nígbà tí Jòhánù gbúròo nípa ohun tí Jésù ńse láti inú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ síi 3 láti béère lọ́wọ́ rẹ̀ pé, "Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀, àbi ká máa retí elòmíràn?" 4 Jésù dá wọn lóhùn wípé, "Ẹ lọ sọ fún Jòhánù ohun tí ẹ ti rí àti tí ẹ ti gbọ́ 5 Afójú ńríran, àwọn arọ ńrìn, àwọn adẹ́tẹ̀ ńgba ìmúláradá, àwọn odi ńgbọ́ràn, àwọn òkú ń di alàyè, a sì ǹ sọ ìròyìn ayò fún àwọn aláìní 6 Ìbùkún ni fún ẹni tí kò bínú nítorí mìí." 7 Bí àwọn ènìyàn yìí ti ń lọ lọ́nà wọn, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ní bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù, "Kínni ẹ̀yin lọ sínu asálè láti wò- Ṣé enití ó máa ń yí ọkàn rẹ̀ padà ni? 8 Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin lọ wò- ènìyàn tó wọ́ṣọ́ tó níye lórí? Lóòtọ́, àfin ni irú àwọn wọ̀nyí máa ń gbé. 9 Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin lọ wò- Wòólì? Bẹ́ẹ̀ni, mo wí fún yín, àti ju wòólì lọ pàápàá. 10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ wípé, 'Wòó, èmi ńrán oníṣé mi lọ síwájú yín, ẹni tí yóò pèsè ọ̀nà yín sílẹ̀ níwájú mi.' 11 Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, láàrin àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹnití ó gajù Jòhánù onítẹ̀bọmi lọ. Síbẹ̀ ènìyàn pàtàkì tó kéré jù ní ìjọba ọ̀run jùú lọ. 12 Láti ìgbà tí Jòhánù tí ń wàásù títí di ìsinsìnyí ni ìjọba Ọlọ́run tí di àfi agbára wọ̀, àwọn ọkùnrin akíkanjú ní ń fí agbára gbàá. 13 Nítorí gbogbo áwọn Wòólì àti òfin ló ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ títí àkókò Jòhánù, 14 tí ẹ̀yin bá sì lé gbàá, òun ní Èlíjà tí a ti sọ wípé yíò wá. 15 Ẹni tó bá létí láti gbọ́ràn, ẹ jẹ́ kí ó tẹ́tí. 16 Kínni èmi yóò fi ìran yìí wé? Ó dàbi àwọn omodé tí wọ́n ń seré ní gbàgede ìtajà, tí wọ́n jókòó, tí wọ́n sì ń ké sí ara wọ́n 17 Wípé, 'àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò sì jó, àwa ń sọ̀fọ̀, ẹ̀yin kò sì sunkún.' 18 Nítorí Jòhánù kò wá láti wá jẹ búrẹ́dì àti ọtí wáínì, wọ́n sì ní, 'ó ní ẹ̀mí òkùnkùn.' 19 Ọmọ ènìyàn wá, ó sì ń jẹ jíjẹ àti mímu, wọ́n sì sọ wípé, 'Wòó, alájẹjù àti ọ̀mùtí ènìyàn ni, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀!' Ṣùgbọ́n ọgbọ́n máa ń gba ìdáláre nípa ìṣe rẹ̀." 20 Nígbànáà ni Jésù bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní bá àwọn ìlú tí ó tise iṣẹ́ ìyanu wí, nítorí tí wọ́n ko yípadà. 21 "Ègbé ni fún yín ní Kórásìn! Ègbé ní fún yín Bẹtisáídà! Tí ó ba ṣe pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ní Tírè àti Sídónì ni a ṣe nínu yín ni, wọn ìbá ti yípadà tipẹ́tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22 Sùgbọ́n yóò sàn ju Tírè àti Sídónì ju yìn-ín lọ lọ́jọ́ ìdájọ́. 23 Ìwọ, Kápánámù, sé o rò wípé a óò gbé ọ ga sí ọ̀run? Rárá o, inú ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óò jù ọ́ sí. Nítorí kání Sódómù ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ̀, yóò sì wà títí di òní. 24 Mo ṣọ fún yín wípé yóò sàn fún ilẹ̀ Sódómù jù yín lọ lọ́jọ́ ìdájọ́." 25 Ní àkókò náà, Jésù wípé, mo yìn Ọ́, Bàbá mi, Ọlọ́run ọ̀run òhun ayé nítorí tí O ti fi àwọn ǹkan wọ̀nyí pamọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti olóye, Ó sì ti fihan àwọn tí a kò kọ́ bi àwọn ọmọ kékeré. 26 Bàbá, torí èyí ni ìfẹ́ inú rẹ. 27 Ohun gbogbo ni bàbá mi tí fi lé mi lọ́wọ́, kò sì ẹnití ó mọ ọmọ àyàfi bàbá, bẹ́ẹ̀ni kò sì sí ẹni tó mọ bàbá àyàfi ọmọ, àti ẹni tí ó wu ọmọ láti fi bàbá rẹ̀ hàn. 28 Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wúwo rù, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. 29 Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. 30 Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sí fúyé."