Orí Kejìlá

1 Nígbà náà, Jésù gba ọ̀nà oko ọkà kọjá lọ́jọ́ sábátì, ebí sì ń pa àwọn ọmọ èyìn rẹ̀. Wọ́n sì ń ré orí okà láti jẹ. 2 Ṣùgbón nigbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún Jésù, "wò ó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń se ohun tí kò bá òfin mu lọ́jọ́ Sábátì". 3 Jésù sọ fún wọn, "ṣé ẹ̀yin kò tíì ka ohun tí Dáfídì se, nígbà tí ebi ń paá àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ 4 Ó lọ si ile Ọlọ́run, ósì jẹ àkàrà tíó wà ní ibi pẹpẹ, èyí tí kò bá òfin mu fún àwọn ọkùnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n fún àwọn àlùfa nìkan. 5 Ṣé ẹ̀yin kò tíì ka nínú òfin ni, pé àwọn àlùfáà nínú tẹ́mpìlì ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò ní ẹ̀bi? 6 Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín, ẹni tíó ju tẹ́ḿpìlì lọ ti wà níbí. 7 Tí ẹ̀yin bá mọ ìtunmọ̀ èyí 'àánú ni mo fẹ́, kìí se ebọ', ẹ kò ní dá aláìṣẹ̀ lẹ́bii 8 nítorí ọmọ ènìyàn ni Olúwa Sábàtì." 9 Nígbà náà ni Jésù sì kúrò níbẹ̀, ó sì lọ sí inú sínágọ́gù wọn 10 Sì wòó, ọkùnrin kan wà tí ó ní ọwọ́ ríro, àwọn Farisí sì bi Jésù, wípé,"ṣé ó bá òfin mu láti wòsàn ní ọjó Sábátì" kí wọ́n le baà ka ẹ̀ṣẹ̀ sí I lọ́rùn. 11 Jésù sì sọ fún wọn wípé, "irú ọkùnrin wo nínú yín ni tí ó bá ní àgùtàn kan, tí àgùntàn yìí sì kósí kòtò tó jìn lọ́jọ́ Sábàtì, ni kò ní gbá a mú, kó sì fàá jááde? 12 Mélo-mélo ni ènìyàn jẹ́ iyebíye ju àgùtàn lọ. Nítorínà, ó bá òfin mu látii se nkan rere lọ́jọ́ ọ Sábàtì". 13 Jésù sì sọ fún ọkùnrin náà, "na ọwọ́ rẹ", ó nà á, ósì padà sí ipò, bí ọwọ́ ìkejì 14 Àwọn Farisí sì jáde láti lọ dí ọ̀tẹ̀ mọ́ ọ. Wọ́n gbèrò bí wọn yóò se paá. 15 Bí Jésù ṣe mọ èyí, ó yẹ ara kúrò níbẹ̀. Ènìyàn púpọ̀ tẹ̀le, ó sì wo gbogbo wọn sàn 16 Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máṣe fi òun hàn fún àwọn míràn, 17 kí ohun tí a ti ẹnu wòlíì Àìsáyà sọ lè ṣẹ, wípé, 18 "wo, ìráńṣẹ́ mi tí mo ti yàn; àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ́ sí. Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú rẹ̀, yóó sì se ìdájọ́ àwọn kèfèrí. 19 Kò ní ṣaápọn tàbí fi igbe ta a, ẹnikẹ́ni kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní òde 20 yóò ní àánú fún àwọn aláìlera, yóò sì ṣe pẹ̀lé sí àwọn tí ó ní ọgbẹ́ 21 ní orúkọ rẹ̀ ni àwọn kèfèrí yóò ní ìrètí kan. 22 Nígbà náà ni wọ́n gbé ẹnìkan tí ó fọ́jú, tí kò sì le sọ̀rọ̀, tí ẹ̀mí èṣù sí ń yọ lẹ́nu wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, ó wò ó sàn, okùnrin odi náà sì sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 ẹnú sì ya gbogbo áwọn èrò. Wọ́n sì wípé, "ṣé ọkùnrin yíí lè jẹ́ ọmọ Dáfídì bí?" 24 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí, wọ́n wípé, "ọkùnrin yìí kò lé ẹ̀mí èṣù jáde, bí kò ṣe nípasẹ̀ Beelzebul, ọmọba àwọn ẹ̀mí èṣù" 25 Sùgbọ́n Jésù mọ èro wọn, ó sì wí fún wọn pé, "Gbogbo ìjọba tí ó bá ní ìpinyà nínú rẹ̀ ni yóò di ahoro, àti ìlú tàbí ilé tí ó bá ní ìpinyà nìnù rẹ̀ ni kì yóò dúró. 26 Tí Sàtánì bá lé Sàtánì jade, ìpinyà wà ní inú rẹ̀. Báwo ni ìjọba rẹ̀ yóò se dúró? 27 àti pé tí èmi bá lé ẹ̀mi èṣù jade pèlu Beelzebul, ní ipasẹ̀ tani àwọn ọmọ yín nse lé wọn jáde? Fún ìdí èyí, àwọn ni yóò jẹ́ adájọ́ yín. 28 Sùgbọ́n tí mo bá lé ẹ̀mí èsù jáde nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run, ìjọba Ọlọ́run ti dé sí orí yín. 29 Báwo ni ènìyàn se le wọ ilé ọkùnrin alágbára láti jí nkan ìní rẹ̀, láì kọ́kọ́ so ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni yóò lè jí nǹkan ìni rẹ̀ 30 Ẹni tí kò wà pẹ̀lú mi lòdì sí mi, ẹni tí kò bá kójọ, ń fọ́nká. 31 Nítorí náà, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a ó dáríjì ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí ni a kò ní dáríjì. 32 Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dáríjí. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kò ní dáríjì, yálà ní ayé yìí àti èyí tó ń bọ̀. 33 Èso igi ni yóò sọ tí igí bá dára tàbí tí ó bá burú, nítorí èso ni a fí dá igi mọ̀. 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ ó ṣe sọ ohun tó dára nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ibi? Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́ré ọkàn ni ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ 35 Láti inú ìṣúra rere ọkàn ni ọkùnrin rere mú ohun tó dára jáde, ọkùnrin ibi náà sì mú ohun búburú jáde láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀. 36 Mo wí fún yín pé, ní ọjọ́ ìdájọ́, àwọn ènìyàn yóò se ìsirò gbogbo ọ̀rọ̀ òfo tí wọ́n ti sọ. 37 Nítorí, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ yín ni a ó dá a yín láre, àti nípasẹ̀ ọ̀rọ yín ni a ó dá yín lẹ́bi." 38 Nígbà náà ni àwọn akọ̀wé àti Farisí kan dá Jésù lóhùn wípé "Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì láti ọ̀dọ̀ rẹ." 39 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn, ó wípé, "Ìran ibi àti alágbèrè má ń wá àmì kiri. Ṣùgbọ́n a kó nì fún ní àmì yàtọ̀ sí àmì wòlíì Jónà. 40 Nítorí bí Jónà se wà nínú ẹja fún ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta nínú ẹja nlá ni ọmọ ènìyàn yóò wà nínú ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta. 41 Àwọn ọkùnrin Nínéfè yóò dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran àwọn ènìyàn yìí, wọn yóò sì dá a lẹ̀jọ̀. Nítorí wọ́n yí padà lẹ́yìn ìwàásù Jónà, sì wòó, ẹni tì ò tóbi ju Jona lọ wà ní ìhín. 42 Ayaaba gúsù yóò dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ìran yìí láti dá a lẹ́jọ́. Ó wá láti òpín ayé láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, sì wòó, ẹni tí ó tóbi ju Sólómọ́nì lọ wà ní ìhín. 43 Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ ti kúrò lára ọkùnrin kan, ó gba ọ̀na ibi aṣálẹ̀ kọjà láti wá ìsinmi, ṣùgbọ́n kò sì rí i. 44 Nígbà náà ó wípé, "èmi yóò padà sí ilé mi ní ibití mo ti wá.' 45 Nígbà náà ó lo láti mú ẹ̀mí méje tó burù jù ú lọ, gbogbo wọ́n sì wá gbé ni ibẹ̀. Nígbà náà, ipò ọkùnrin náà ní ìgbẹ̀yìn yóò burú ju ti ìsááju lọ. Bẹ́ẹ̀-ni yóò rí fún ìran búburú yìí." 46 Nígbà tí Jésù ńbá àwọn èèrò sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró sí ìta láti bá a sọ̀rọ̀. 47 Ẹnìkan sọ fun, "Wò ó, ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ́ dúró sí ìta, láti bá ọ sọ̀rọ̀." 48 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn, ó sì wí fún pé tani ó wí fun, "Ta ni ìya mí, àwọn wo sì ni arákùnrin mi?" 49 Nígbà náà ni ó na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yin, Ó wípé, "ẹ wo, àwọn ìyá àti arákùnrin mi nìyìí! 50 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ohun tí bàbá mi tó wà ní ọ̀run fẹ́ ni arákùnrin, arábìnrin àti ìyá mi."