Orí Keje

1 Ẹ ma se dájọ́, a ki o si dá yín lẹ́jọ́ 2 Nítorí pẹ̀lú ìdájọ́ tí ẹ bá dá ní lẹ́jọ́ la ó fi dá yín lẹ́jọ́, àti òsùwọ̀n tí ẹ bá fi wọ̀n, la ó wọ̀n jáde fún yín. 3 Kí ló dé tí ẹ fí wo ẹ̀ru igi tí ó wà nì ojú arákùrin rẹ, sùgbọ́n o kò kíyèsí ìti igi tí o wà ní ojú ìwọ tì kara rẹ? 4 Báwo ni ó se wi fún arákùnrin rẹ, 'Jẹ́ kí mú ẹ̀rún igi tí ó wà ní ojú rẹ kúrò,' nígbàtí ìti igi wà ní ojú ìwọ tì ká ra rẹ? 5 Ẹ̀yin alágàbàgebè! Ẹ kọ́kọ́ yọ ìti igi kúrò nì ojú ara yín, nìgbà náá ni ẹ ó rí ran kedere láti yọ ẹ̀rún kúrò lójú arákùrin yín. 6 Ẹ ma se fi ohun mímọ́ fún àwọn ajá, ẹ má si se sọ pẹ́rílì yín fún ẹlẹ́dẹ̀. Bíkòsebẹ́ wọn o tẹ́ é mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀, wọ́n o sí kọjú sí yín, wọn o sí fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. 7 Bèrè, a ó si fi fún ọ. Wá kiri, ó sì rí. Kàn kùn, a ó si sí sílẹ̀ fún ó., 8 Nítorí olúkúlùkù tí ó bá bẹ̀rẹ̀, nrí gbà; olúkúlùkù ti ó wá kiri, nrí; àti fún ẹni tó kàn kùn la ó si fún. 9 Tàbí ta ni nínú yín, ti ọmọkùnrin rẹ bá bèrè fún àkàsù búrẹ́dì, ni yíó fún ní òkúta? 10 Tàbí tí ó bá bère ẹja, ni yíó fún ní ejò? 11 Nítorí náá, tí ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ búburú bá mọ bí ẹ tí fí ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélomélo ni baba yín tó wà lọ́run yíó fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bíí lérè? 12 Nítorí nàà, ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn se fún yín, ẹ se bẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ fún wọn, nítorí èyí ni òfin àti àwọn Wòlí. 13 Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tóró wọlé. Nítorí fífẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, gbòrò sì ni ọ̀nà náá tí ó lọ sí ìparun, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó sí nlọ nípa rẹ̀. 14 Sùgbọ́n tóró ni ẹnu ọ̀nà, ọ̀nà náá sí sòro tí ó lọ sí ìyè, díẹ́ ni ó si wá rí. 15 Ẹ kíyèsára fún àwọn Wòlí èké, tí wọ́n ntọ́ yín wá nínú asọ àgùntàn sùgbọ́n apanirun ìkokò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn lẹ ó fi mọ̀ wọ́n. Njẹ́ àwọn ènìyàn a mọ́ kó èso gírèpù jọ láti inú ẹ̀gún ọ̀gàn tàbí fírì láti inú òsùsu? 17 Bẹ́ gẹ́gẹ́, gbogbo igi rere a mọ́ mú èso rere jáde, sùgbọ́n igi búburú a mọ́ mú èso búburú jáde. 18 Igi rere ò le mú èso búburú jáde bẹ́ni igi búrurú kò le mú èso rere jáde. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a ké kúrò asì sọ́ sínú iná. 20 Bẹ́ gẹ́gẹ́, nípa èso wọn ni ẹ ó fi mọ̀ wọ́n. 21 Kí íse gbogbo ẹnití ó pé mí ní 'Olúwa, Olúwa,' ni yóó wọ ìjọba ọ̀run, àfi àwọn tí ó bá se ìfẹ bàbá mí tó wà lọ́run. 22 Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yíó wí fún mi ní ọjọ́ náá, 'Olúwa, Olúwa, njẹ́ àwa kò sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, ní orúkọ rẹ ni a lé ẹ̀mí èsù jáde, àti ní orúkọ rẹ ni a se ọ̀pọ̀ isẹ́ ìyanu? 23 Nígbà náá ni má kéde rẹ̀ ní gbangba fún wọn 'èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníwà búburú! 24 Nítorí nàà, gbogbo ẹnití ó bá gbọ́ ọ̀rò mi tí o si gbà wọ́n gbọ́ yíó dàbí okùnrin amòye tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta 25 Òjò rọ̀, ìku omi dé, afẹ́fẹ́ fé ósì bìlù ilé nàà, sùgbọ́n kò subú lulẹ̀, nítorí a kọ́ sórí àpáta. 26 Sùgbọ́n olúkúlùkù ẹnití ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi ti ko si gbà wọ́n gbọ́ yíó dàbí okùnrin asiwèrè tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí yanrì 27 Òjó rọ̀, ìku omi dé, afẹ́fẹ́ sí fẹ́ o sì bìlu ilé náá, ó sì wó lulẹ̀, ìparu rẹ̀ sí tán. 28 Ó sì se nígbà tí Jésù parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀n yíí, ẹnú ya ìjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ẹ̀kọ rẹ̀, 29 nítorí ó kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kíí sí se bí àwọn akọ̀wé.