Orí Kẹfà

1 Ẹ kíyè sára kí ẹ má se ìse òdodo yín niwaju ènìyàn kí wọ́n lè rí yín, bíkòsebẹ́ ẹ kì yóó ní èrè láti ọ̀dọ̀ baba yín tó wà lọ́run 2 Nítorí nàà nígbàtí ẹ bá nfí fún ni, ẹ má fun ìpè níwájú yín bí àwọn alágàbàgebè se íse nínú sínágọ́gù àti ní ìloro, kí wọ́n le gba ìyìn àwọn ènìyàn. Lóótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba ère wọn náá. 3 Sùgbọ́n nígbà tí ẹ bá fi fún ni, ẹ má se jẹ́kí ọwọ́ òsì yín mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tun yín se, 4 kí ẹ le fi ọrẹ yín fún ni ní kọ̀kọ̀. Nígbà náá ni baba yín tó nrí ní kọ̀kọ̀ yíó fi èrè fún yín. 5 Nígbà tí ẹ bá ngbàdúrà, ẹ má se dàbí àwọn alágàbàgebè, nítorí wọ́n fẹ́ràn láti mọ́ dúró gbàdúrà nínú sínágọ́gù ní igu àwọn ìloro kí àwọn ènìyàn ba le rí wọn. Lóótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn náá. 6 Sùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ bá ngbàdúrà, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín. Ẹ ti ilẹ̀kùn, kí ẹ sì gbàdúrà sí baba yín tó wà ní kọ̀kọ̀. Nígbà náá ní baba yín tó nrí ní kọ̀kọ̀ yíó sán fún yín. 7 Nígbà tí ẹ bá ngbàdúrà, ẹ má se àtúwí asán bí àwọn kèfèrí tí íse, nítorí wọ́n ro wípé a ó gbọ́ wọn nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ wọn. 8 Nítorí nàà, ẹ má se dà bí wọn, nítorí baba yín mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bí léèrè. 9 Nítorí nàà, ẹ gbàdúrà bá yíí: 'baba wa ní ọ̀run, mímọ́ ni orúkọ rẹ 10 Jẹ́ kí ìjọba rẹ́ dé, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé bí tọ̀run. 11 Fún wa ní óúnjẹ òjọ wá lóni. 12 Dárí gbèsè wa jìn wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú tí ndáríjì àwọn oní gbèsè wa 13 Mọ́ mú wa wá sínú ìdanwò, sùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni ibi. 14 tí ẹ bá dárí èrékọjá àwọn ènìyàn jìn wọn, baba yín lọ́run pẹ̀lú yíó dáríjìn yín 15 Sùgbọ́n tí ẹ bá dárí èrékọjá wọn jìn baba yín kì yíó dárí èrékọjá yín jìn yín. 16 Síwájúsí, nígbàtí ẹ nbá gbàwẹ̀, ẹ má se ojú bí ẹní nsọ̀fọ̀ bí àwọn alágàbàgebè tí nse, nítorí wọ́n korò ojú kí wọ́n le farahàn sí àwọn ènìyàn pé wọ́n ngbàwẹ̀. lóótó ni mo wí fún yín, wọ́n tí gba ère wọn náá. 17 Sùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ bá ngbàwè, ẹ ku orí yín kí ẹ sì fọ ojú yín, 18 kí o mọ́ ba hàn sí àwọn ẹlòmíràn pé ẹ́ ngbàwẹ̀, sùgbọ́n sí baba yín nì kan soso tó wà ní kọ̀kọ̀; baba yín tó nrí ní kọ̀kọ̀, yíó sán fún yín. 19 Ẹ má se to ìsura jọ fún ara yín ní ayé, níbití kòkòrò àti ìpáàrà báájé, àti níbití olè tí nfọ́ wolé tí wọ́n sí njalè. 20 Dípò bẹ́ẹ́, ẹ to ìsura jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbití kòkòrò tàbí ìpáàrà kí tíí báájẹ́ àti níbití olè kí tíí fọ́ wọlé latí jalè. 21 Nítorí níbití ìsura yín bá gbé wà, ní bẹ̀ ni ọkàn yín yíó wá pẹ̀lú. 22 Ojú ní àtùpà ara. Nítorí náá tí ojú yín bá dára, gbogbo ara ti kun fún ìmọ́lè. 23 Sùgbọ́n tí ojú yín kò bá dára, gbogbo ara ti kún fún òkùnkùn. Nítorí náá, bí ìmọ́lè tó wà nínú yín bá tilẹ̀jẹ́ òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn ná ìbà tóbi tó! 24 Ẹnikẹ́ni kò le sín ọ̀gá méjì, bíkòse pé yíó kórira ọ̀kan yíó si fẹ́ràn tọ̀ún, bíkòsebẹ́ yíó gbáralé ọ̀kan yíó sí yan tọ̀ún nípọ̀sì. Ẹ o lè sin Ọlọ́run ati ọrọ̀. 25 Nítorí nàà, mo wí fún yín, ẹ mọ́ se ìnira nípa ayé yín, ohun tí ẹ o jẹ tàbí ohun tí ẹ o mu - tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ o wọ̀. Nítorí ayé kò ha sàn ju óúnjẹ lọ bí, àti ara ju asọ lọ? 26 Kíyèsi àwọn ẹyẹ inú afẹ́fẹ́. Wọn kíí gbìn tàbí kórè tàbí ká sínú àká, sùgbọ́n baba yín lọ́run bọ́ wọn. Njẹ́ ẹ̀yin kò ha sàn jù wọn lọ bí? 29 27 Tani nínú yín nípa àníyàn síse le fi ìgbọ̀nwọ́ kan kú ọjọ́ ayé rẹ̀? 28 Kí lódé tí ẹ fí nse àníyàn nípa asọ? Wòye àwọn lílí pápá, bí wọ́n tí ndàgbà. Wọn kíí sisẹ́, wọn kíí ràn wú. 29 Síbẹ̀ mo wí fún yín, Sólómọ́nì páápá nínú ògo rẹ̀ a ò da lásọ bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀n yíí. 31 30 Bi Ọlọ́run bá wo àwọn koríko inú ìgbẹ́, tí o wà lóni ti a sì sọ síná lọ́la, bá wo ni kó bá se wọ̀ yín lásọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré. 31 Nítorí náá ẹ má se àníyàn kí ẹ si wípé 'Kí ni a ó jẹ?' tàbí 'Kí ni a ó mu?' tàbí, 'Asọ wo la ó wọ̀?' 32 Nítorí àwọn Élénì nwá àwọn nkan wọ̀n yíí kiri, baba yín tó wà lọ́run mọ́ pe ẹ̀yin nílò àwọn nkán wọ̀n yíí. 33 Sùgbọ́n ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba rẹ àti òdodo rẹ̀ a ó si fi gbogbo nkan wọ̀n yíí fún yín 34 Nítorí náá, ẹ má se àníyàn fún ọ̀la, nítorí ọ̀la yíó se àníyàn fún ara rẹ̀. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni ibi tótó fún ara rẹ̀.