Orí Karùn-ún

1 Nígbà tí Jésù rí Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Ó gun orí òkè lọ. Nígbà tí ó sì ti jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ wá sọ́dò Rẹ̀. 2 Ó ya ẹnu Rẹ̀ ó sì ń kọ́ wọn, pé, 3 Ìbùkún ni fún àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni Ìjọba Ọ̀run. 4 ni fun àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, Nítorí tí a ó tù wọ́n nínú. 5 Ìbùkún ni fún àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí tí wọn ó jogún ayé. 6 Ìbùkún ni fún àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, nítorí tí a ó kún wọn. 7 Ìbùkún ni fún àwọn aláàánú nítorí tí wọn ó rí àánú gbà. 8 Ìbùkún ni fún àwọn ọlọ́kàn mímọ́ nítorí tí n ó rí Ọlọ́run. 9 Ìbùkún ni fún àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n. 10 Ìbùkún ni fún àwọn tí à ń ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, nítorí wọn ó jogún ìjọba-ọ̀run. 11 Ìbùkún ni fún yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá tàbùkù yín tí wọn sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì parọ́ onírúurú ohun ibi mọ́ ọ yín nítorí mi. 12 Ẹ máa yọ̀ Ẹ sì máa dunnú, nítoirí èrè yín yóó pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí báyìí ni wọ́n ṣe sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín. 13 Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni a ó ṣe mú u dùn padà? Kò wúlò fún ohunkóhun mọ́ àfi kí á sọ ọ́ nu kí ó sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn ènìyàn. 14 Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè f'arasin. 15 Kò ṣe é ṣe kí àwọn ènìyàn tan fìtílà kí wọ́n sì gbé e sí abẹ́ apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n bíkòṣe pé l'órí ọ̀pá fìtílà, yóó sì tàn fún gbogbo ènìyàn nínú ilé. 16 Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín tàn kedere níwájú gbogbo ènìyàn kíwọn lè rí i kí wọ́n sì yin Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. 17 Ẹ máṣe rò pé mo wá látí pa òfin àti àwọn wòlíì run. Èmi kò wá láti pa wọ́n run, ṣùgbọ́n láti mú wọn ṣẹ. 18 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín títí ọ̀run àti ayé yóò fi kọjá lọ kékeré nínú òfin mi kì yóò lọ láìṣẹ títí gbogbo rẹ̀ yóò fi ṣẹ. 19 Nítorí náà ẹnikẹ́ni tó bá rú kékeré nínú àwọn òfin wọ̀nyí tí ó sì ń kọ́ àwọn mìíràn láti ṣe wọ́n ní a ó yẹpẹre ní ìjọba-ọ̀run. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń pa wọ́n mọ́ tí ó sì ń kọ́ wọn ni a ó pè ní púpọ̀ ní ìjọba-ọ̀run. 20 Nítorí mo wí fún yín bí kò ṣe pé òdodo yín bá kọjá ti àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí, kò sí bí Ẹ ó ṣe dé ìjọba-ọ̀run. 21 Ẹ ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará àtijọ́, 'Ìwọ máṣe pàniyàn', àti pé, 'Ẹni tí ó bá pàniyàn yóó wà ní ewu ìdájọ́'. 22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé gbogbo ẹni tí ó bá bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóó wà ní ewu ìdájọ́; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún arákùnrin rẹ̀ pé 'ìwọ aláìníláárí!' yóó wà ní ewu ìgbìmọ̀, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé 'Ìwọ aláìlọ́gbọ́n!' yóó wà ní ewu ọ̀run àpáàdì. 23 Nítorí náà bí o bá mú ẹ̀bùn rẹ wá sí ibi pẹpẹ tí o sì rántí pé arákùnrin rẹ sẹ̀ ọ́, 24 Fi ẹ̀bùn rẹ sí iwájú pẹpẹ níbẹ̀ kí o sì lọ ní ọ̀nà rẹ. Kọ́ lọ bá arákùnrin rẹ làjà ná, kí o sì wá fi ẹ̀bùn rẹ sí ibi tó yẹ. 25 Bá oníjà rẹ làjà ná nígbà tí ẹ wà l'ọ́nà ilé-ẹjọ́, kí ó má bà fà ọ́ lé onídàájọ́ l'ọ́wọ́, kí onídàájọ́ má bà fà ọ́ lé amòfin l'ọ́wọ́´, ó sì le jù ọ́ sí ẹ̀wọ̀n. 26 L'óòótọ́ ni mo wí fún ọ, o kò ní bọ́ nínú rẹ̀ títí ìwọ ó fi san kékeré tó kù nínú gbèsè náà. 27 Ẹ̀yin ti gbọ́ tí a wí pé, 'máṣe ṣe àgbèrè.' 28 Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín pé gbogbo ẹni tó bá wo obìnrin l'ọ́nà tí kò tọ́ ti bá a ṣe àgbèreè l'ọ́kàn rẹ̀ ná. 29 Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ kí o sì sọ ọ́ nù. Nítorí ó sàn kí ọ̀kan nínú ẹ̀yà ara rẹ ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí ọ̀run àpáádì. 30 Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kí o sì sọ ọ́ nù. Nítorí ó sàn kí ọ̀kan nínú ẹ̀yà ara rẹ ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáádì. 31 A tún wí pé, 'Ẹnikẹ́ni tó bá lé aya rẹ̀ jáde jẹ́ kí ó fún-un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.' 32 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, gbogbo ẹni tó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bí kò ṣe nípa ìṣekúse nípa ìbálòpọ̀, sọ ọ́ di alágbèrè. ẹnikẹ́ni tó bá sì gbé e níyàwó lẹ́yìn náà ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀. 33 Ẹ ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará àtijọ́, 'Ìwọ máṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ èké, 34 Ṣùgbọ́n mú àròyé rẹ tọ Olúwa lọ.' ṣùgbọ́n mo wí fún yín, Ẹ máṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, ìbáà ṣe nípa ọ̀run nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni; 35 tàbí nípa ayé, nítorí àpótí ìtísẹ̀ Rẹ̀ ni; tàbí nípa Jerúsálẹ́mù, nítorí ìlú àwọn ọba aládé ni. 36 Tàbí kí o jẹ́jẹ̀ẹ́ nípa orí rẹ, nítorí o kò lè mú ọ̀kan nínú irun orí rẹ funfun tàbí dúdú. 37 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí 'bẹ́ẹ̀-ni rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀-ni' tàtí 'bẹ́ẹ̀-kọ́ bẹ́ẹ̀-kọ́.' Ohunkohun tó bá jù báyìí lọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ibi ló ti wá. 38 ti gbọ́ bí a ti wí rí pé, 'ojú fún ojú àti eyín fún eyín.' 39 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín Ẹ máṣe dí ẹni ibi lọ́wọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá gbá yín ní ẹ̀ẹ̀kẹ́ ọ̀tún ẹ kọ ti òsì sí I pẹ̀lú. 40 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mú ọ lọ sí ilé ìgbẹ́jọ́ tí ó sì gba agbádá rẹ jẹ́ kí ó gba àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. 41 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ mú ọ lọ sí máìlì kan bá a dé méjì. 42 Fifún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ má sì ṣe gbé ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó fẹ́ yá lọ́dọ̀ rẹ. 43 Ẹ ti gbọ́ bí a ti wí fún yín pé, 'Ẹ gbọdọ̀ fẹ́ràn àwẹn alábágbé yín kí ẹ sì kórira àwọn ọ̀tá yín.' 44 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín Ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, Ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín, 45 kí ẹ lè jẹ ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run nítorí Ó ń mú òòrùn Rẹ̀ ràn s'órí ẹni búburú àti ẹni rere, Ó sì ń rán òjò s'órí olóòótọ́ àti aláìsòótọ́. 46 Nítorí bí Ẹ̀yi bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín, èrè kiń ni Ẹ̀yin ó gbà? Ǹjẹ́ àwọn agbowó òde kò máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú? 47 Bí ẹ bá kí àwọn arákùnrin yín nìkan, kiń ni ẹ ṣe ju àwọn ẹlòmìíràn lọ? Àwọn aláìkọlà kò a máa ṣe bẹ́ẹ̀? 48 Nítorí náà Ẹ jẹ́ pípé bí Baba yín tí ńbẹ l'ọ́run ti jẹ́ pípé.