ORÍ KẸRIN

1 Lẹ́yìn naa ni Ẹ̀mí Mímọ́ darìi Jésù lọ sínú aginjù kí a lee dan an wò láti ọwọ èsù. 2 Nígbà tí ó ti gba ààwẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi bẹ̀rẹ síí paá. 3 Olùdánwò wá sọ́dọ rẹ, ó wí fún un pé, "Bí ìwọ́ bá jé Ọmọ Ọlọ́run, pàse kii àwọn òkúta wọ̀nyíì di àkàrà". 4 Ṣùgbọ́n Jésù dáa lóhùn wípé, "A ti kọọ́ pé: Ènìyàn kì yóò wà nípa àkàrà nìkan, bíkòse nípa ọ̀rọ tí o ti ẹnu Ọlọrun jáde wá." 5 Lẹ́yìn èyí ni Èsù fà Jésù lọ sínú ìlú Mímó, ó sì gbée lọ sórí sóńsó Tẹḿpìlì, 6 Ó wí fún ún wípé: "Bí ìwo bá jẹ Ọmọ Ọlọ́run nítòótọ́, kí o bẹ́ sílẹ̀. Nítorí a sáà ti kọ̀wée rẹ̀ wípé, 'Òun yóò pàsẹ fún àwọn ańgélì Rẹ láti pa ọ́ mọ́', àti pé, 'Àwọn ańgẹ́lì yóò si gbé ọ sókè ní apáa wọn', kí íwọ ma baa se fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta." 7 Jesu sọ fun un wípé, "A ti tún kọ̀wẹ rẹ̀ wípé: 'Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọ́run rẹ wo'." 8 Lẹ́ẹ́kàn an sí i, Esu gbe Jésù lọ sori pepele ti o ga, ó fi gbogbo ìjọba ayé yii àti àwọn ògo rẹ̀ hàn án. 9 O wi fun un pe: "Gbogbo n kàn wọ̀nyí ni èmi yóóò fi fún ọ bí ìwọ ba le forí balẹ̀ kí sì o sìn mi." 10 Nígbà naa ni Jesu báá wi pé: "Lọ kúrò lọdọ mi, Sátánì!, A ti kọ̀wé rẹ wípé, 'Olúwa Ọlọrun un rẹ nìkansoso ni kí ìwo kó forí balẹ̀ fún', 'Oun nìkan soso ni kí ìwo ki o maa sín'." 11 Nígbà naa ni Èsù lọ kúrò lọdọ rẹ, sì kíyèsii, àwọn ángẹ́lì si wa lati maa se irànsẹ́ fún un. 12 Ǹjé nigba ti Jesu gbọ́ pé Ọba ti pàṣe láti fi ipá mú Jòhánù, Jésù yẹra kúrò ní Gálílì. 13 O lọ kúro ni Násárẹ́tì láti máa se àtìpó gbé ni Kápánáúmù, ni agbègbè Òkun Gálilì, ní àláà Ṣébúlúnì àti Náfítálì. 14 Èyíi sẹlẹ̀ láti se àmúṣẹ àsotẹlẹ̀ ti wolii Àísàyà kọ wípé, 15 Ṣébúlúnì àti Nàfìtálì, ní ìhà òkun, rékojá Odò Jọ́dáni, Gálílì ti àwọn Kèfèri! 16 Àwọn ènìyàn tó jókòó nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá; lára àwọn tó jókòó ní àfonífojì ikú ni ìmọ́lẹ̀ tàn sí." 17 Lati igbà naa ni Jesu ti bẹrẹ si wàásu pe: "Ẹ ronúpìwàpà, nitori pé ijọba ọ̀run kù si dẹ̀dẹ̀." 18 Bi o ti n rìn ni ìhà Òkun Gálílì, ó rí àwọn ọkùnrin méjì, Símónì ẹni tí à n pè ní Pétérù, àti Anderu arakunrin rẹ̀, wọn ń jù àwọ̀n ìpeja wọn sínú odò, nitori ti wọ́n jẹ apeja. 19 Jésù sọ fún wọn pẹ́, "Ẹ wa, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hín, èmi yóò si sọ yín di apẹja ènìyàn." 20 Lójúkan náà ni wọn fi àwọ̀n ìpeja wọn sílẹ, wọn si bẹ̀rẹ̀ si tọ̀ọ̀ lẹ́hin. 21 Bi Jésù ti ń lọ kúrò níbẹ̀, o tún rí àwọn arákùnrin méjì míràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wa nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lu Sébédè ti o jẹ́ bàbá wọ́n, ti wọ́n ńyanju àwọ̀n ìpẹja wọn. 22 Ó pè wọ́n, lojukannáà ni wọ́n fi bàbá wọn silẹ láti máa tọ̀ọ lẹhin. 23 Jesu si re kọjá lọ si gbogbo agbègbè Gálílì, O ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn, o n wàásù nípa ìjọba ọ̀run, o si n se ìwòsàn oniruurú àwọn àrùn àti àìlera láàrin àwọn ènìyàn. 24 Òkìkí i rẹ̀ si kàn káàkiri láàrin àwọn agbègbè Siria, àwọn ènìyàn si gbé oníkúlùkù àwọn ti o ni àìlera àti àìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ki o leè se dídá ara fún wọn, àwọn ti o ni ẹ̀mí àìmọ́, àrùn wárápá gbé wọn wá sọ́dọ̀ rẹ. Jésù si mú u gbogbo wọn láradá 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lo tọ̀ọ lẹ́yìn láti agbègbè Gálílì, Dèkàpólísì, Jèrúsalémù ati Jùdíà, àti rékọjá odo Jọ́dánì.