Mátíù Orí Kẹta

1 Ni ọjọ wọnnì, Johanu Onítẹ̀bọmi bẹrẹ si i wàásù ní aginjù Jùdíà, ó ń wípé: 2 "Ẹ ronupìwàpà, nitori pé ìjọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀." 3 Èyí ni ohùn ẹni tí ó kígbe nínú aginjù, gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ wolii Àísáyà wípé: "Ẹ tún ọ̀nà Olúwa se, Ẹ mú kí ònà rẹ̀ kí o tọ́." 4 Johánù a máá wọ aṣọ ti a fi awọ Ràkúnmí se pẹ̀lùu ọ̀já igbànú aláwọ. Eéṣú ati oyin ìgàn ni ouńje rẹ. 5 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tọ Johanu wá láti Jèrúsalẹmù, Jùdíà àti àwọn agbègbè ti o wà ni Odò Jọ́dánì tọ̀ọ́ lọ. 6 Bi wọn ti ńjẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wọn, Johánù baptisí gbogbo àwọn èniyàn nínú Odò Jọ́dánì. 7 Ṣùgbọ́n nígbà ti o rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Farisí àti Sadusí ti wọn n wá fún ìbaptisí lọ́dọ̀ rẹ̀, O w´ fún wọ́n wípé: "Ẹ̀yin ọmọ ejò olóró, taani o kilọ̀ fún yín láti sá fún ìjìyà ti o ńbọ̀? 8 Ẹ so èèso ti o yẹ fún ìrònúpiwàdà. 9 Ẹ máse rò ninú ara yín pé, 'Àwa ní Ábráhámù gẹ́gẹ́ bíí bàbá wa'. Mo wí fún yín wípé, Ọlọ́run leè mú àwọn ọmọ jáde fún Ábráhámù lati inú àwọn òkúta wá. 10 A ti fi ááké lé àwọn gbòǹgbò igi. Nítorínáà, gbogbo igi ti ko bá so èeso rere ni a o gée lulẹ̀, ti a o si kóo jọ sinu iná. 11 Omi ni emi fi ń baptisí yin fun ìrònúpiwàdà, ṣùgbọ́n ẹnití o bọ́ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mi lo; okùn sálúbàtà ẹni ti èmi kò tó láti tú. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná baptisí yín. 12 Ohun èèlò ìpakà ńbẹ lọwọ́ ọ rẹ̀ láti fi gbá ibi ìpakà rẹ mọ. Yóó si kó àwọn àlìkámà jọ sínú àká a rẹ. Ṣùgbọn àwon èèpò ni oun yóóò fi iná jó run pátápátá. 13 Lẹ́yìn náà ni Jésù wá láti Gálílì si ọ̀dọ̀ Johánù ní Odò Jọ́dánì ki o leè baptisí rẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n Johánù kọ̀ fún un, ó wípé, "Èmi ní o yẹ látii wá fún ìbaptisí lọ́dọ̀ rẹ, èése tí ìwó si fi tọ̀ mí wá?" 15 Jésù dáhùn o wi fun un pe, "Jọwọ̀ọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, o yẹ kí á mú gbogbo àwọn òfin sẹ béè. Bẹ́ẹ̀ni Jòhánù si gbà bẹ́ẹ̀ fún un. 16 Lẹ́yìn ti a ti baptisí Jésù tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ o gòkè jáde kúrò nínú omi, si kíyèsíi, awọn ọ̀run sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Ọlọ́run si bà lée lórí bi àdàbà. 17 Kíyèsíi, ohùn kan jàde láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pé, "Èyíi ni àyànfẹ́ ọmọ mí, ẹni tí inú mí dùn sí gididgidi."