Orí Kejì

1 Léyìn ìgbà tí a ti bí Jésù ni Bẹ́thẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, àwon amòye láti ìlà-oòrùn wá láti wádìí wípé: 2 "Níbo ni enití a bí gégébí Ọba àwon Júù wà? A ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ láti ìlà-oòrùn, a sì ti wá láti jọ́sìn síi." 3 Nígbàtí Hẹ́rọ́dù ọba gbọ́ èyí ọkàn rẹ̀ dàrú, àti gbogbo Jérúsálẹ́mù. 4 Hẹ́rọ́dù si kó àwon olori àlùfáà àti àwọn akọ̀wé jọ, ó sì bi wọ́n léèrè wípé, "Níbo ni ó yẹ kí ìbí Krístì ti wáyé?" 5 Wọ́n wí fun un pé, "Ní Bẹ́thẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ni, nítorí báyìí ni a ti kọ̀wé rẹ̀ láti ọwọ́ àwon Wòlíì pé: 6 'Sùgbọ́n ìwọ, Bẹ́thẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Júdà, ìwọ kò kéré jùlọ láàrin àwon ọmọ aládé Júdà, nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni alákoso tí yóò se olùsọ́-àgùntàn àwon ènìyàn Ísráẹ́lì yoo ti jade wá.' 7 Nígbànà ni Hẹ́rọ́dù pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀ láti se ìwádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà fi ara hàn? 8 Ó rán wọn lọ sí Bẹ́thlẹ́hẹ́mù, wípé "Ẹ lọ kí ẹ se ìwádìí dájúdájú fún mi nípa ọ̀dọ́modé náà. Nígbàtí ẹ bá sì ti ríi, ẹ padà wá sọ fún mi kí èmi pẹ̀lú le lọ láti fi orí balẹ̀ fún un. 9 Nígbàtí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n bá ọ̀nà won lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n rí láti ìlà-oòrùn sì ń lọ níwájú wọ́n títí ó fi dúró ní ọ̀gángan ibi tí ọmọ ọwọ́ náà gbé wà. 10 Nígbàtí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, wọ́n yọ̀ ayọ̀ gidigidi. 11 Wọ́n wọ inú ilé, wọ́n sì rí ọmọ ọwọ náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀. Wọ́n wólẹ̀, wón sì fi orí balẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn fún un. Wọ́n tú àpò ìsura wọ́n láti fún un ní ẹ̀bùn wúrà, tùràrí, àti òjìá. 12 Ọlọ́run kìlọ́ fún wọn ní ojú àlá láti máse padà sí ọ̀dọ̀ Hẹ́rọ́dù, nítorínáà, wọ́n padà sí orílẹ́-èdè tiwon nípa ọ̀nà ibòmíràn. 13 Nígbàtí wọ́n ti lọ tán, ángẹ́lì Olúwa yọ sí Jósẹ́fù ní ojú àlá, ó sì wípé: "Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí o sí máa sá lo sí Íjíbítì. "Dúró síbẹ̀ títí n o fi bá o sọ̀rọ̀, nítorí Hẹ́rọ́dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà run." 14 Ní òru náà, Jósẹ́fù dìde ó sì mú ọmọ ọwọ́ náà, àti ìyá rẹ̀, ó sì sá lọ sí Íjíbítì. 15 Ó wà níbẹ̀ títí Hẹ́rọ́dù fi kú. Eyi jẹ́ ìmúse ohun tí Olúwa ti sọ láti ẹnu wòlíì: "Láti Íjíbítì ni mo ti pe Ọmọ mi." 16 Nígbànáà, nígbàtí Hẹ́rọ́dù ri wípé òun ti di ẹlẹ́yà láti ọwọ́ àwọn ọkùnrin amòye, ó bínú gidigidi. Ǒ ránsẹ́, ó sì pa gbogbo ọ̀dọ́modé tí ó wà ní Bẹ́thlẹ́hẹ́mù, àti gbogbo ìgbèríko láti ọmọ ọdún méjì tàbí kéré jù bẹ́ẹ̀ lo, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àkókò tí àwon amòye se alábàpáàdé rẹ̀. 17 Nígbànáà ni ọ̀rọ̀ tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Jeremáyà wá sí ìmúse wípé: 18 "Ní Rámà ni ati gbọ ẹkún, àti ìpohùn réré ẹkún ńlá. Rákélì ńsọkún fún àwon ọmọ rẹ̀ nítorí wọn kò sí, ó kọ̀ láti gba ìsìpẹ̀. 19 Nígbàtí Hẹ́rọ́dù kú, ángẹ́lì Olúwa yọ sí Jósẹ́fù ní ojú àlá ní Ǐjíbítì ó sì wípé: 20 "Mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ kí o sì lọ sí ilẹ̀ Ǐsráẹ́lì nítorí àwon tí ń wá ẹ̀mì ọmọ naa ti ku. 21 Jósẹ́fù si dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, ó sì wá sí ilẹ̀ Ǐsráẹ́lì. 22 Sùgbón nígbàtí ó gbọ́ wípé Akelaúsì ni ó njọba lórí Jùdíà ní ipò bàbá rẹ̀, Hẹ́rọ́dù, ẹ̀rù bàá láti lọ sí ibẹ̀. Nígbàtí Olúwa sì ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá ó gba ilẹ̀ agbègbè Gálílì lọ. 23 Ǒ sì lọ gbé ní ìlú kan tí a n pè ní Násárẹ́tì. Êyí jẹ́ ìmúse ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlíì wípé, "ará Násárẹ́tì ni a ó máa pèé."