Orí Kẹtàdínlógún

1 Nígbàtí ó di òwúrò, gbogbo àwon olórí àlúfà àti àwon àgbàgbà àwon ènìyàn wón dìtẹ̀ món Jésù láti paá. 2 Won dèé,won tìí jade,won sì fi lé Pílátù tíṣe gómínà lọ́wọ́. 3 lẹ́yìn èyí Júdásì,ẹni tí ó ti dalẹ̀ Jésù,ríipé won ti dá Jésù lẹ́bi, óronúpìwàdà ósìdá ọgbòn owó fàdákà padá fún àlúfà àti àwon àgbàgbà pẹ̀lú. 4 ósìwípé "èmi ti ṣẹ̀ ní ti dídalẹ̀ ẹjẹ̀ aláìṣẹ̀ yí."Sùgbón won wí fún pé,"Kínin èyí jẹ́ fún wa? ówà ní ìkáwọ́ rẹ ." 5 Nígbànáà ni ó wá da owó fàdákà nàn sílẹ̀ nínú témpìli,ósì kúrò níbẹ̀,ójáde ósìlọ fi okùn so ara rẹ̀ món igi 6 Àwon olórí àlúfà kó owó fàdákà nàn wón sì wípé,"kòdára kí átún kó owó yìí sí ibi tí à má ń kó owó sí,nítóripé owó burúku ni." 7 Wón wá sọ ọ̀rọ̀ yìí láàrin ara won pẹ̀lú owó nàn wón ra ilẹ̀ kan láti ma fi sin òkú àwon àlejò sí. 8 Nítorí ìdí èyí ilẹ̀ nàn ni won ńpè ní,"ilẹ̀ ẹ̀jẹ̀" títí di àkókò yí. 9 Ki èyí tí a ti ẹnu wòlí Jeremáyà sọ sajú kí o le wá sí ìmúṣẹ, wípé, "Wóngba ogbòn owó fàdákà,èyí tí àwon ọmọ Îsírẹ́lì bèrè fú, 10 wón sì fi fún ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti amokòkò, gẹ́gẹ́ bí Olúwa se darí mí." 11 Jésù dúró níwájú gómìnà,gómìnà sì bílèrè pé,"sé ìwọ ni ọba àwon Juu?"Jésu wá da lóhùn pé "ìwọ nàn ti wí bẹ̀." 12 sùgbón nígbàtí àwon olórí àlúfà àti àwon àgbàgbà fi ẹ̀sùn kànán,kò dá won lóhùn rárá. 13 Nígbànàn ni Pílátù sọ fún pé," sé kò gbọ́ gbogbo ẹ̀sùn tí wón fi kàn Ọ́?" 14 Sùgbón kò dáhùn rara,èyí wá tún jẹ́ ìyàlénu ńlá fún gómìnà. 15 Ní àkókò àjọ́dún ó jẹ́ ojúse fún gómínà láti dá ẹlẹ́wòn kan sílẹ̀ èyí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwon ènìyàn bá fi ọwọ́ sí. 16 Ní àkókò yí ọ̀daràn ẹlẹ́wòn kan wà tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ bárábà. 17 Nígbàtí wón sìtún pàdépọ̀,pílátù wí fún won,"tani ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ó dá sílẹ̀ fún yín ?Bárábà ni àbí Jésù tí óhúnjẹ́ Kírísítì?" 18 Ó mòn pé wón fi Jésù lé òhun lọ́wọ́ nítóripé wón kórìra rẹ̀ ni. 19 Nígbàtí Ó jòkó lórí àga ìdájọ́,ìyàwó rẹ̀ ránsẹ́ si ó sọ fún pé "kó má sese ohunkóhun sí aláìsẹ̀ ọkùnrin yí.nítorí òhúnti dàmú púpọ̀ lójú orun lóní fún irú àlá tí òhúnti lá níparẹ̀." 20 Nígbàyí ni olóró àlúfà àti àwon àgbàgbà rọ àwon ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn láti bèrè fún Bárábà,kí won ógbà kí wón pa Jésù. 21 Gómìnà wá biwón lèrè,"eléwo nínú àwon méjèjì ni ẹfẹ́ kí èmi ó dásílẹ̀ fún yín?"Wón sọwípé ,"Bárábà." 22 Pílátù wá sọ fún won pé,"kínin kí èmi kó se sí Jésù tíse Kírísítì."Gbogbo won sì dáhùn pé,"kàn mó àgbélèbú." 23 Ni ó bá sọpé,"kínlódé,kínin ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ gan?"wón wá tún kígbe sókè daadaa,pé kànmóàgbélèbú." 24 Nígbàtí Pílátù ripé òhun kò ní agbára mó,àtipé wón ti dá wàhálà sílè,ó gbé omi,ó wẹ ọwọ́ rè níwájú gbogbo won,ósì wípé,"kòsí ohun tó kàn òhun mó níti ọkùnrin aláìsẹ̀ yí.Ẹ fise ohun tí ẹ bá fẹ́." 25 Gbogbo wón bá wípé,kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kó wá sí orí wa àti sí orí àwon ọmọ wa." 26 Ó bá dá Bárábà sílẹ̀ fún won,ni ó bá na Jésù ní ẹgba ósì fi lé won lọ́wọ́ láti kànmóàgbélèbú. 27 Nì àwon ọmọogun gómínà bá mún Jésù lọ sí ibi tí ójẹ́ ibi orí fún ìjọba wón sì kó gbogbo àwon ọmọogun jọ. 28 Wón ja sí ìhòhò wón sìfi asọ pupa bò lára. 29 wón se adé tó jẹ́ ẹ̀gún wón sì gbe lé ní orí,wón sí fi ọ̀pá kan sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.wón kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ wón sì fi ń se yẹ̀yẹ́,wípé,"ókúsẹ́,ọba àwon Juu!" 30 Wó tutọ́ sí lára, wón mú igi wón sì ń nàn lórí nígbàgbogbo. 31 Nígbà tí wón fi se yẹ̀yẹ́ tán,wón bọ́ asọ tí wón fi wọ wón si fi asọ rẹ̀ gangan wọ,wón wa ń mú lọ síbi tí wón óti kànmóàgbélèbú. 32 Bí wón se dé ìta, ni wón rí ọkùnrin kan ará kírénì tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Símónì,wón fipá mú kí ó le tẹ̀lé won láti gbé àgbélèbú Jésù. 33 Wón mu wá sí ibìkan tó ǹjẹ́ gọ́ngọ́ntà,èyí tí ìtumò rẹ̀ ni"ibi agbárí," 34 Wón fún ní ọtí tókorò mu tí wón ti fi òróǹro sí. Sùgbón nígbàtí ómuń,ókorò kò le mú. 35 Nígbàtí wón ti pá tán, wón pín asọ rẹ̀ nípa ìbò dídì, 36 wón wá jòkó wón ń sọ́ọ. 37 Ní ibi orí rẹ̀ wón kọ àkọlé kan síbẹ,pé"èyí ni Jésù ọba àwon juu." 38 olè méjì ni wón kàn mó àgbélebú pẹ̀lú rẹ̀,ọ̀kan wà ní apá ọ̀tún àti ọ̀kan ní apá òsì rẹ̀. 39 Gbogbo àwon tó ńkọjá lọ fise ẹléyà,wón sí ń min orí fu . 40 wón ńwípé,"ìwọ ẹni tí yò wó tẹ́mpìlì tí yò sì tunkọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta,gba aràrẹ là. Tí ìwọ bá jẹ pé ọmọ Ọlórun ni Ọ, sọ̀kalẹ̀ wá kúrò lórí àgbélèbú!" 41 Bákánnà olórí àlúfà pẹ̀lú fi se yẹ̀yẹ́, pẹ̀lú àwon akọ̀we àti àwon àgbàgbà, wón ń wípé, 42 ógba àwon kan là, sùgbón kòle gba ara rẹ̀ là. Òhun sá ni ọba ísírẹ́lì. Jẹ́kósòkalẹ̀ kúrò lúrí àgbélèbú, nígbànàn àwánàn a ó gbàgbọ́. 43 Ó gba Ọlọ́run gbọ́,kí Ọlọ́run kówá gbà sílẹ̀ nísinsìnyí,bóbá jẹ́pé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ̀ lótítọ́.Ó kúkú ti sọpé,'ọmọ Ọlọ́run ni òhun jẹ́." 44 Bẹ́nàni àwon arúfin tí wón kàn mó àgbélèbú pẹ̀lu rẹ̀ nan ń sọ̀rọ̀ burúkú si. 45 láti wákàtí kẹfà òkùnkùn sì bò ilẹ̀ títí ófi di wákàtí kẹ̀sán. 46 ní dédé wákàtí kẹ̀sán, Jésù kígbe sókè gan Ó wípé, "Élì, lama sàbátàní?" ìtumò rẹ̀ ni pé, "Ọlọ́run mí, Ọlọ́run mí, kí lódé tí ofi kọ̀ mí sílẹ̀?" 47 Nígbàtí ọ̀pọ̀ nínuú àwon tó wà níbẹ̀ gbọ́ èyí, wón ní, "Ó mà ńpe Èlíjà." 48 Lójijí ọ̀kan nínú won sáré lọ mú kànìnkànìn, tó ti fi sínú ọtí tóti kan, ófi sí orí ọ̀pá ìyè,ó sì fún pé kí ómún. 49 Àwon ìyókù rẹ̀ sọ fún pé, "Fisílẹ̀ jẹ́ kí ámá wo bóyá Èlìjà ni yó wa gbàálà." 50 Nígbànàn ni Jésù tún kígbe sókè gan pẹ̀lú oùn òkè ni ó bá kú. 51 wòó,asọ tówà lẹ́nu ọ̀nàn tẹ́mpìlì ya sí éeìi láti òkè dé ìsàlẹ̀,ayé sì mìn tìtì ,àwon àpáta sì pín sí méjì. 52 Àwon ibojì sí di sísí sílẹ̀,ọ̀pọ̀ òkú àwon ènìyàn mímó tóti kú ló tún di alàyè. 53 wón jade kúrò nínú ibojí won lẹ́yìn tí Jésù jídìde,tí wón rìnwá sí ìlú mímó,tí wón sì fi ara hàn fún àwan ọ̀pọ̀ ènìyàn. 54 Nígbàtí,adarí àwon ọmọọgun ọgọrùń àti gbogbo àwon tó ń wo Jésù rí bí ìlẹ̀ se mìn àti àwon ohun tó sẹlẹ,ẹ̀rù wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ńbà wón wón wá sọpé, "lótítọ́ ọmọ Ọlọ́run ni eléyìí." 55 ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwon obìnrin tó tẹ̀lẹ́ Jésù láti gálílì wón wà níbẹ̀ tí wón ńwo Jésù ní ọ̀nà tó jìnà. 56 lára won ni Màríà Magidaleni wà, Màríà tó jẹ́ ìyá Jemisi àti Josefu, àti ìyá àwon ọmọ sébédè nan wà níbẹ̀. 58 nígbàtí ìlẹ̀ ń sú lọ,ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wá láti aremátìa,tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ jósẹ́fù,tí òhun nàn sì jẹ́ ọ̀kan lára àwon ọmọ ẹ̀hìn Jésù. 57 Ó bá Pílátù sọ̀rọ̀ ísì bèrè fún òkú Jésù.Pílátù bá pa àse pé kí wón gbé fun. 59 Jósẹ́fù bá gbé òkú Jésù,ósìfi asọ tó dára yí, 60 ósì tẹ sí bojì òkú ti ara rẹ̀ tí ó fi àpáta ṣe lọ́sọ̀ọ́.lẹ́yìn nàn ni óyí òkúta nínlá lé ìlẹ̀kùn ibojì nàn ósì bá tirẹ̀ lọ 61 Màríà magidálènè àti Màríà míràn wàníbè, tí wón jòkó kọjú sí bojì nà. 62 Ní ọ́jọ́ kejì, lẹ́yìn ọjọ́ ìpalẹ̀mó, olórí àlúfà àti àwon farisí wón kórajọ̀pọ̀ pẹ̀lú pílátù. 63 wón wípé,"ọ̀gá arántí pé nígbàtí ẹlẹ̀tàn ń wà láyé,ó sọpé, "lẹ́yìn ọjọ́ kẹ̀ta òhun ó jídìde, 64 nítorínà pàsẹ pé kí àbò tó péye kówà ní ibòjì nàn fún ọjọ́ mẹ́ta,bíbẹ̀kọ́ àwon ọmọèhìn lewá kí won ójigbé kíwón ówá ma sọpé ó ti jí dìde ìtìjú ti ìkẹyìn yó wàá burú jù ti ìsájú lọ. 65 Pílátù wá sọ fún won pé, "ẹyan ẹ̀sọ́.ẹlọ kí ẹsì lo gbogbo agbára yín láti fi se bẹ" 66 wón sìlọ láti dàbòbò ibòjì nàn, wón fi àmìn síbi òkúta nán wón sì fi àwon ẹ̀só alábò síbẹ̀.