Orí Ìkejìdínlọ́gbọ̀n

1 Ó sì ṣe ní alẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ní àfẹ̀júmọ́ ọjọ́kínní ọ̀ṣẹ̀, Màríà ará Mágdálà àti Màríà kejì wá láti wo ibojì náà 2 Sìkíyèsi, ilẹ̀ ṣì mì gidigid, nítorí áńgẹ́lì Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó wá ó ṣì yí òkúta náà kúrò, ó ṣì jókòó lé e lórí 3 Ìrísí rẹ̀ dà bí iná, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú 4 Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà sì gbọ̀n jìnìjinì fún ẹ̀rù wọ́n sì dà bí òkú. 5 Áńgẹ́lì náà bá àwọn obìnrin náà sọ̀rọ̀ wípé "Ẹ má bẹ̀rù, nítorí mo mọ̀ wípé ẹ̀yin ń wá Jésù, tí wọ́n ti kàn mọ́ àgbélèbú. 6 Kòsí níbíyìí, ṣùgbọ́n ó ti jí dìde gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wò ibi tí wọ́n tẹ́ Olúwa sí. 7 Ẹ tètè lọ kí ẹ sì wí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, 'Ó ti jí dìde kúrò láàrin àwọn òkú. Ẹ wò ó, ó ń ṣiwájú yín lọ sí Gálílì. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i.' Ẹ wò ó, èmi ti so fún yín." 8 Àwọn obìnrin náà tètè kúrò níbi ibojì náà pẹ̀lú ẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá, wọ́n sì sáré lọ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. 9 Kíyèsi, Jésù pàdé wọn ó ṣì wípé, "Àlàáfíà fún yín!" Àwọn obìnrin náà wá, wọ́n dì í ní ẹṣẹ̀ mú wọ́n sì sìn ín. 10 Jésù sì wí fún wọn pé, "Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi kí wọn lọ sí Gálílì. Ibẹ̀ ni wọn yóò ti rí mi." 11 Nígbà tì àwọn obìnrin náà ńlọ, sì kíyèsi, àwọn díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ náà lọ sínú ìlú láti sọ fún àwọn olórí àlúfàà ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ 12 Nígbàtí àwọn àlúfáà náà ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn olórí tí wọn ṣì ti sọ ọ̀ràn náà pẹ̀lú wọn, wọ́n fún àwọn ọmọ ogun náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó 13 wọ́n sì sọ fún wọn, "Ẹ sọ fún àwọn tí ó kù, 'àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní òru wọ́n ṣì jí ara rẹ̀ gbé nígbà tí à ń sùn 14 Tí ìròyìn yìí bá dé ọ̀dọ̀ gómìnà, ẹ máṣe mikàn nítorí a ó bá a sọ̀rọ̀ láti má fìyà jẹyín." 15 Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun náà gba owó náà wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún wọn. Ìròyìn yìí tàn kálẹ̀ láàrin àwọn Júù ó ṣi tẹ̀ síwájú títí di òní. 16 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Gálílì, sí ibi àpáta náà tí Jésù ti sọ fún wọn. 17 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sìn ín, ṣùgbọ́n àwọn kan ṣe iyèméjì. 18 Jésù wá sí ọ̀dọ̀ wọn ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ ó wípé "Gbogbo àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti ní ayé. 19 Ẹ lọ nítorí náà kí ẹ ṣì máa sọ gbogbo orílẹ̀ èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ máa tẹ̀ wọ́n bọ omi ní orúkọ ti Baba, ti ọmọ, àti ti Ẹ̀mí mímọ́. 20 Ẹ máa kọ́ wọn láti máa gbọ́ràn sí ohun gbogbo wọnnì tí mo ti pa láṣẹ fún yín. Ẹ kíyèsi, mo wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, kódà títí ó fi dé òpin ayé.