Orí Kẹrìndínlọ́gbọ̀n

1 Ó sì sẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé, 2 "bí ẹ ti mọ pé àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ méjì, àti pé ní ọjọ́ náà ni wọn yóò fà ọmọ ènìyàn lé àwọn tí yóò kàn mí mọ́ àgbélèbú lọ́wọ́" 3 Lẹ́yìn náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà parapọ̀ péjọ ní ààfin Kéfà, tii se olú àlùfáà 4 Wọ́n gbìmọ̀pọ̀ láti mú Jésù ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ àti làti pá 5 Nítorí wọ́n wípé, "Yí ó sòro láti mu ní àsìkò àjọ ìrékọja kí ìrúkèrúdò má baà sẹlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn" 6 Nísinsìnyí, nígbàtí Jésù wà ní Bẹ́tánì, nínú ilé Símónì adẹ́tẹ̀ 7 Bí Ó ti jókòó tí Ó fara lé tábìlì, arábìnrin kan wá pẹ̀lú òróró olóòórùn dídùn tí ó wọ́n jọjọ, ó dàá sí ori rẹ̀ 8 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí ǹkan yìí, wọ́n bínú, wọ́n sì bèèrè pé, "Irú òfò ńlá wo ni èyí? 9 Òróró yí leè se àfàní púpọ̀ fún àwọn aláiìní, tí a bá tàá ní owó iyebíye" 10 Ṣùgbọ́n Jésù mo èrò ọkàn wọn, Ó sì bá wọn wí, Ó wí pé, "kílódè tí ẹ fi ń da arábìnrin yí láàmú? Nítorítí ó se ohun ribiribi tí ó dára fún mi. 11 Àwọn aláìní yóò máa wà ní àrọ́wọ́tó yín ní ìgbá gbogbo, ṣùgbọ́n ìgbà péréte ni mo ní láti lo síi pẹ̀lú yín. 12 Nítorípé òróró yìí ni arábìnrin yìí dà sí ara mi fún ìsìnkú mi 13 Mo fẹ́ kí ẹmọ̀ dájú pé, akòní gbàgbé ohun tí arábìnrin yí se ní gbogbo ibití a bá ti ń wàásù ìhìnrere yìí, ní igun mẹ́rẹ̀ẹrin ayé." 14 Nígbà náà ni Júdásì Ìsìkáríọ̀tù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá tọ àwọn olórí àlùfáà lọ 15 Ó bèèrè pé, "kíni ẹ̀yin yóò fún mi tí mo bá fà Á lé yín lọ́wọ́?" Wọ́n sì gbé òdiwọ̀n ọgbọ̀n owó fàdákà le lọ́wọ́. 16 Láti ìsẹ́jú náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní wá gbogbo ọ̀nà láti fàá lé wọn lọ́wọ́. 17 Nísisìnsìyí, ní ọjọ́ kínní tí àjọ àìwúkàrà bẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tọ Jésu wá, wọ́n bèèrè pé, "Níbo ni kí á pèsè sílẹ̀ láti jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá?" 18 Ó dáwọn lóhùn pé, "Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin kan ní àarin ìlú, kí ẹ sọ fun pé, 'Olùkọ́ni sọ wípé, "Àsìkò mi titó. Èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ń bọ̀ láti jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá ní ilé rẹ." 19 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sìse gẹ́gẹ́ bí Ó ti wí, wọ́n pèsè oúnjẹ àjọ ìrékọjá. 20 Ní àsáálẹ́, Ó jókòó làti jùmọ̀ jẹun pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ 21 Bí wọn se ń jẹun lọ, Ó wípé, "Ní òtítọ́ ni mo sọ fún yín pé, ẹnìkan nínú yín yóò dà mí." 22 Inú gbogbo wọn sì bàjẹ́ gidigidi gan, wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ lọ́kọ́ọ̀kan pé, "Olúwa, ódájú pé kìí se èmi?" 23 Ó dáwọn lóhùn wípé, "Ẹniti yóò fi mí hàn ni ó ń jẹun pẹ̀lú mi nínú igbá kan náà" 24 Ọmọ ènìyàn yóò kọjá lọ gẹ́gẹ́ bí ati kọọ́ sílẹ̀ nípa Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún arákùnrin náà, tí ó da ọmọ ènìyàn! Kò bá sàn kí ìyá rẹ̀ má bíi. 25 Júdásì, ẹniti yóò fií hàn bèèrè pé, "Olùkọ́ni, sé èmi ni bí?" Ó sì dáà lóhùn pé, "Ìwọ fúnra rẹ ti dáhùn" 26 Bí wọn ti ń jẹun lọ, Jésù mú àkàrà, Ó yàá sí mímọ́, Ó si pin fún àwọn ọmọ ẹyin rẹ, Ówipe, "Ẹ gbà, ara mi ni eyi." 27 Ò mú ife tí wáìnì wà nínú rẹ̀, Ó dúpẹ́, Ó sì gbe e fùn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wípé "Gbogbo yín, ẹmu wáìnì tí ó wà nínú ife yí. 28 Nítorípé, èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí a ta sílẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀. 29 Ṣùgbọ́n mo sọ èyí fún yín pé, èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí tí èmi yóòfi muú pẹ̀lú yín lọ́tun ní ìjọba Bàbá mi." 30 Nígbàtí wọ́n sì ti kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí orí òkè Ólífì. 31 Nígbànáà ni Jésù sọ fún wọn pé, "Gbogbo yín yóò fi èmi nìkan sílẹ̀ ní àsáálẹ́ òní, nítorí ati kọọ́ pé, 'Èmi yí ò kọlù Olùsọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn inú agbo rẹ̀ yí ò sì tú ká káàkiri' 32 Sùgbọ́n, lẹ́yìn ìgbàtí Ọlọ́run bá ti jí mi dìde kúro nínú ipò òkú, Èmi yóò síwájú yín lọ sí Gálílì. 33 Ṣùgbọ́n Pétérù sọ fun wípé, "Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìyókù bá tilẹ̀ sá lọ, èmi kì yóò fi Ó sílẹ̀." 34 Jésù da lóhùn pé, "Ó dámi lójú pé ní àsálẹ́ òní, ìwọ Pétérù yóò sẹ́ mi ní ìgbà mẹ́ta kí àkùkọ tó kọ." 35 Pétérù tún da lóhùn pé, "Tó bá jẹ́ ti ikú ni, mo se tán láti kú pẹ̀lú Rẹ," Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ìyókù náà sì sọ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. 36 Nígbà náà ni Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibi tí a ń pè ní Gẹ́símánì. Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wípé, "Ẹ jókòó sí ibíìyí, Nígbàtí èmi yóò lọ síwájú síi láti gbàdúrà." 37 Ó mú Pétérù àti àwọn ọmọ Sébédè méjèjé pẹ̀lú rẹ̀, inú rẹ̀ bàjẹ́ ọkàn rẹ̀ pòruùrú. 38 Nígbà náà ni Ó sọ pé, "Ẹ̀mí mi gbọgbé gidi gan, títí dé ojú ikú. Ẹdúró sí ibí yìí, kí ẹ sì máa bá mi sọ́nà." 39 Ó sì lọ síwájú díẹ̀ si, Ó dojú bolẹ̀, Ó gbàdúrà. Ó wípé, "Bàbá, tí ó bá seése, mú ìjìyà àti ikú yìí kúrò lọ́nà mi.Ṣùgbọ́n kìí se ìfẹ́ mi, bi kò se ìfẹ́ Rẹ." 40 Ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, Ó báwọn tí wọ́n ń sùn, Ó bèèrè lọ́wọ́ Pétérù pé, "Kílódé, ṣe ẹ̀yin kò le bámi sọ́nà fún wákàtí kan ni? 41 Ẹ sọ́ra, kí ẹ sì tún gbàdúrà kí ẹ má bọ́ sínú ìdẹwo. Ẹ̀mí yín ń fẹ́ ní tòótọ́, ṣùgbọ́n ara yín kò gbàá. 42 Ó padà lọ ní ìgbà kejì láti gbàdúrà. Ó gbàdúrà pé, "Bàbá mi, tì ìjìyà àti ikú yìí kò bá leè ye lórí mi, ìfẹ́ Rẹ ni Èmi yí ò se." 43 Ó padà wá, Ó sì báwọn lójú oorun lẹ́ẹ̀kan si, nítorí tí oorun ń kùn wọ́n gidigidi 44 Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan si, Ó lọ láti gbàdúrà bí Ó se gbàá tẹ́lẹ̀. 45 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jésù wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, "Sé ẹ̀yin tún ń sùn ni?" Ẹ kíyèsi, wákàtí náà ti dé, tí a ó fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́ 46 Ẹ dìde, ẹjẹ́ kí á lọ. Kíyèsi, ẹni tí yóò dà mí ti dé tán." 47 Nígbàtí Ó ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì ọ̀kan lára àwọn méjìlá dé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n tẹ̀ lée wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà. Wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání. 48 Ní àsìkò yí, arákùnrin tí yóò fií hàn ti sọ àmì fún wọ́n pé, "Òhun ni ẹni tí mo bá ti fi ẹnu kò ní ẹnu, kí ẹ mu lọ́gán." 49 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, ó wípé, "Olùkọ́ni, mo kí Ọ!" Ó sì fi ẹnu kòó lẹ́nu. 50 Jésù sọ fún pé, "Ọ̀rẹ́, se ohun tí o wá se." Nígbà náà ni wọ́n mú Jésù. 51 Kíyèsi, ẹnìkan lára àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù fa idà rẹ̀ yọ, ó sì gé etí ọmọ ọ̀dọ̀ olú àlùfáà kan. 52 Nígbà náà ni Jésù wí fun pé, "Fi idà rẹ sínú àkọ̀ rẹ̀, nítorípé gbogbo ẹni tí ó bá fi idà pa ènìyàn, ni yóò kú nípa idà" 53 Sé ìwọ rò pé èmi kòleè pe Bàbá, òhun yóò sì rán àwọn ángẹ́lì méjìlá tí ó jẹ́ légíóni ni? 54 èyí gbọdọ̀ sẹlẹ̀ kí àwọn ohun tí ati kọ sínú ìwé mímọ́ le wá sí ìmúse. 55 Ní àkókò náà Jésù sọ fún àwọn èrò tí ó wá láti mu pé, "Sé èmi ni ẹ̀yin wá mú pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ bi ọlọ́sà? Mò ń jókòó pẹ̀lú yín lójojúmọ́ nínú tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò mú mi. 56 Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ń sẹlẹ̀, kí àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòólì leè wá sí ìmúsẹ ni." Nígbànáà ni gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn fií sílẹ̀, wọ́n sì sálo. 57 Àwọn tí wọ́n mú Jésù sì mu lọ síwájúu Kéfà olú àlùfáà, níbití àwọn akọ̀wé àti àwon àgbààgbà péjọ pọ̀ sí. 58 Ṣùgbọ́n Pétérù tẹ̀ lée ní òkèèrè dé àgbàlá olú àlùfáà. Nígbàtí wọ́n dé inú àgbàlá olú àlùfáà, Pétérù wọlé, ó jókòó pẹ̀lú àwọn ẹ̀sọ́, kí ojú rẹ̀ le tó gbogbo ǹkan tí ó ń sẹlẹ̀. 59 Nísinsìnyí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ìgbìmọ̀ wọn ń wá ẹ̀rí èké tí wọn yóò wé sí Jésù lọ́rùn kí wọn le pá. 60 Wọ́n kò rí ẹ̀sùn kankan kà síi lẹ́sẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí èké ni wọ́n jáde. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó yá, àwọn méjì kan jáde 61 wípé, "Arákùnrin yìí sọ pé, 'Mo leè wó tẹ́mpìlì Ọlọ́run yí, N ó sì tún un kọ́ padà ní ọjọ́ mẹ́ta." 62 Olú àlùfáà dìde ó wí fun pé, "Sé ìwọ kò ní èsì sí àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí ni? Kínni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n ń kà sí Ọ lẹ́sẹ̀ wọ̀nyí?" 63 Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́ síbẹ̀, kò fọ èsì kankan. Olú àlùfáà sọ fun pé, "Mo paá lásẹ fún Ọ, ní orúkọ Ọlọ́run alààyè, sọ fún wa tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Krístì, ọmọ Ọlọ́run" 64 Jésù dáa lóhùn pé, "Bí o se wí, bẹ́ẹ̀ lórí. Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín pé, lati ísinsìnyí lọ, ẹ̀yin yóò rí Ọmọ ènìyàn tí Ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, yóò sì gun sánmà bíi ẹṣin." 65 Nígbànáà ni olú àlùfáà fa asọ Rẹ̀ ya, ó sí wípé, "O ti sọ̀rọ̀ òdì! Kínni a tún fẹ́ fi ẹlẹ́rìí se mọ́? Kíyèsi, gbogbo yín ni ẹ ti gbọ́ bí Ó se sọ̀rọ̀ òdì. 66 Kínni ẹ ní lérò?" Wọ́n sì da lóhùn pé," Ó tọ́ sí ikú." 67 Nígbànáà ni wọ́n tu itọ́ síi lójú, wọ́n nàá wọ́n tún da àbàrá bòó 68 wọ́n sì wípé, "Sọ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwọ Krístì. Tani ẹnití ó gbá Ọ?" 69 Ní àkókò yí ni Pétérù jókòó sí ìta àgbàlá ilé olú àlùfáà, ẹrúbìnrin kan sì tọ̀ọ́ wá, ó wí fun pé, "Ìwọ wà pẹ̀lúu Jésù ní Gálíliì." 70 Ṣùgbọ́n ó sẹ́ jálẹ̀ níwájú gbogbo ènìyàn, ó wípé, "Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí gbogbo yín ń sọ" 71 Nígbàtí ó jáde lọ sí ẹnu ìloro, ẹrúbìnrin mínràn ri, ó sọ fun àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, "Arákùnrin yí náà wà pẹ̀lúu Jésù ti Násárẹ́tì." 72 Ó sí tún sẹ́ Ẹ lẹ́ẹ̀kansi pẹ̀lú ìbúra. Ó ní, "Èmi kò mọ arákùnrin yí rí" 73 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ sii, àwọn tí wọ́n dúró ní àyíká tọ Pétérù wá, wọ́n wí fun pé, "Lótìtọ́, o jẹ́ ọ̀kan lara wọn, pàápàá jùlo ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ fi ọ́ hàn gbangba pé o wà lára wọn." 74 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara rẹ̀ gé ègún, ó tún búra pé, "Èmi kò mọ ọkùnrin yí rí." Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àkùkọ kan kọ. 75 Ó sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ fun tẹ́lẹ̀ pé, "kí àkùkọ ó tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi ní ẹ̀mẹta." Ó sì jáde lọ, ó sun ẹkun kíkorò.