Orí Kẹẹ̀dógún

1 Nígbà náà ni ìjọba ọ̀run yóò dàbi wúndíá mẹ́wǎ tí wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó. 2 Márǔn nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n márǔn sí jẹ́ aláìgbọ́n. 3 Nítorí nígbà tí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn, wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́. 4 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn. 5 Nígbàtí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn. 6 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbé ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó! ẹ jáde láti pàdé rẹ̀.’ 7 “Nígbànáà ni àwọn wúńdíá sì dìde, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe. 8 Àwọn aláìgbọ́n sọ fún àwọn ọlọ́gbọ́n pé, Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú epo yín nítorí fìtílà wa ń kú lọ.' 9 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n dáhùn wọ́n wípé, 'kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.' 10 “Nígbàtí wọ́n lọ ra epo, ni ọkọ ìyàwó dé, àwọn tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àsè ìgbéyàwó, a sì ti ìlẹ̀kùn. 11 Lẹ́yìn náà ni àwọn wúńdíá ìyókù dé wọ́n wí pé, ‘Olúwa, olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’ 12 Ṣùgbọ́n ó dáhùn ó wípé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò mọ̀ yín rí.’ 13 Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí. 14 Nitorí ó dàbí ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fún wọn ní ọrọ̀ rẹ̀. 15 Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn, ó fún òmíràn ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún òmíràn ni tálẹ́ǹtì kan. Ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀. 16 Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi ṣòwò ó sì jèrè márùn mìíràn. 17 Bákanáà èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn. 18 Ṣùgbọ́n ọmọ ọdọ̀ tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọlúwa rẹ̀ mọ́ ibẹ̀. 19 Nígbà náà lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀ ó sì bá wọn ṣírò. 20 Ọmọ ọdò tí ó gba tálẹ́ǹtì márǔn, mú márǔn mìíràn padà wá, Ó wí pé, Olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márǔn fún mi, mo sì ti jèrè márǔn mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’ 21 Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O kú isẹ́ ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́! ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀. Bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ 22 Ọmọ ọdọ̀ tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé, ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti. Wòó, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’ 23 Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O kú isẹ́, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ 24 Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe. Ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò fán ká sí. 25 Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí. 26 Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú àti ọ̀lẹ, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí. 27 Nítorí náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́. tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè. 28 Nítorí náà gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. 29 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, àni lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní, kódà ohun tí ó ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. 30 Ẹ gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’ 31 Nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run. 32 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́. 33 Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì. 34 Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 35 Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. 36 Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí; Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi; àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ 37 Nígbà náà ni olódodo yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu? 38 Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́? 39 Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’ 40 Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni. 41 Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀. 42 Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò fún mi ní oúnjẹ, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò fún mi ní omi láti mu. 43 Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò tọ́jú mí.’ 44 Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’ 45 Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, Nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’ 46 Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.