Orí

1 Jésù sì jáde kúrò nínú tempili ó sì ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀. Awọ̀n ọmọ ẹ̀yìn rẹ sí tọ́ wà láti fi àgọ́ tempili hán. 2 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhuǹ ósì wípé, " Ẹ̀yin kò a rí nǹkan wọ̀nyí? Lótìítọ́ ni mo sọ fún yin, kò sí òkuta kan tí yíó wà lórí èkejí tí a kì yíò bì ṣubú." 3 Bí ò sìti jókò ní orí òkè ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ sí tọ́ wà ní ìkọ̀kọ̀ wọ́n sì wípé, "Sọ fún wa ìgbà wo ti nǹkan wọ̀nyí o ṣẹlẹ̀? kíni yíò jẹ́ àmìn bíbọ̀ rẹ àti òpin ìkẹyìn?" 4 Jésù sì dáhùn ósì wí fún wọn pé, Ẹ kíyèsara kí ẹnikẹ́ni mà ba ṣì yín darí. 5 Nítorí ọ̀pọ̀ yíò wá ní orúkọ mi. Wọn a sì wípé, "Èmi ni Kristi", wọn a sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn darí. 6 nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni yíò ṣẹlẹ́, ṣùgbọ́n òpin kò tíì dé. 7 Nítorí orílẹ́ èdè yíò dìde sí orìlẹ́ èdè, àti ìjọba sí ìjọba. Ìyàn yíò mún àti ilẹ̀ mínmìn ní ibi gbogbo. 8 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú. 9 Bẹ́ẹ̀ni a ó fà yín fún ìpọ́njú a ó sì pa yín. Gbogbo orílẹ̀ èdè yíò kórira yín nítorí orúkọ mi. 10 Bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ ènìyàn yíò ṣubú, wọn ó sì dalẹ́ ara wọn bẹ́ẹ̀ni won oó sì kórira ara wọn. 11 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì ni yíò dìde wọn ó sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ darí. 12 Nítorí àisedédé yíò di púpọ̀, ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ á sì tutù. 13 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítî ni a ó gbàlà. 14 ìyìnrere ìjọba yíò yí ni a ó wàásù ká gbogbo ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀ èdè. Nígbànâ ni òpin yíò dé. 15 Nítorìnà nígbà tí ẹ̀yín bá rí ìríra ìṣọdahoro, tí a ti ẹnu wólì Dáníẹ́lì ṣọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́(ẹni tí óbá ka kí òye kí ó yé e). 16 Nígbànà ni kí àwọn tí nbẹ ní Judea kí ó ṣàlọ sí orí òkè. 17 Kí ẹni tí nbẹ lórí ilé máṣe ṣọ̀kalẹ̀ wá ímú ohunkohun jáde nínú ilé rẹ̀, 18 Kí ẹnití ń bẹ ní oko máṣe padà ṣẹ́hìn wá láti mún aṣọ rẹ̀. 19 Ṣùgbọ́n ẹ̀gbé ni fún àwọn tí ó wà pẹ̀lú ọmọ àti àwọn tí ó n tọ́ju ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ yìí. 20 21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yìó wà, èyí tí kò sẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsisìnyí, tí, kò sì sí èyí tí yíò dàbí rẹ̀ láí. 22 Àfi tí a bá fa àkókò nâ sẹ́yìn, kò sí o n kan tí yíò yè, ṣùgbọ́n nitorí àwọn àyànfẹ́, a ó fa àkókò nâ sẹ́yìn. 23 Nítorínâ tí ẹnìken bá wí fún yín pé, 'Wo Kristi wà ní ibíyî!' tàbí 'Ní ọ̀ún ni Kristi wà' ẹmá ṣe gbàgbọ́ 24 Nítorí Kristi èké àti wòlî èké yíò wà wọn ó sì fi isẹ́ àmì àti isẹ́ ìyanu hàn, kí wọn ó lè bà mú ni ṣìnà, bí ó bá ṣéṣe, àwọn àyànfẹ́. 25 Wô, èmí sọ fún yín ṣájú àkókò nâ. 26 Nítorínà, tí wọ́n bá sọ fún yín pé, 'Wô, ó wà ní ijù'. Tàbí, 'Wô, ó wa ní yàrá òkè,' ẹmá ṣe gbà wọ́n gbọ́. 27 Nítorí bí ìtànná ṣe tàn láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ni dídé ọmọ ènìyàn yíò rí. 28 Nítorí níbi tí òkú ẹranko gbéwà ni igúnnungún a máa péjọ si. 29 Sùgbọ́n lọ́gán lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ náà' òòrùn yóó dúdú,òsúpá kòní tan iná rẹ̀,ìràwọ̀ yóò jábọ́ láti ojú ọ̀run, gbogbo agbára ọ̀run yóò mì tì tì. 30 Nígbànâ ni àmà ọmọ ènìyàn yíò hàn nì àwọn sánmọ̀, bẹ́ẹ̀ni gbogbo ẹ̀yà ní orílẹ́ ayé yíò sọ̀fọ̀. Wọ́n ó rí ọmọ ènìyàn tí ó ń bọ̀ ní àwọ̀ sánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ógo ńlá. 31 Yíò rán àwọn ángélì rẹ̀ pẹ̀lú ariwo ìpè ńlá, wọ́n ó sì kó àwọn àyàfẹ́ jọ láti orígun mẹ́rẹ̀rin, láti òpin kan dé èkeji. 32 Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ara igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbàtí ẹ̀ka rẹ̀ bá yọ titun tí ó bá sì rúwé, ẹ̀yín ó mọ̀ pé ẹ̀rùn súnmọ́ atílé. 33 Bákannâ pẹ̀lú, nígbàtí ẹbá rí nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pe òhún súnmọ́ etílé tán, ní ẹnu ìlẹ̀kùn. 34 Lótìtọ́ọ́ ni mo wi fún yín, ìran yî kì yíò lọ títí tí nńkan wọ̀nyí yíò fi sẹlẹ̀. 35 Ọ̀run àti ayé yíò kọjálọ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yíò kọjá lọ. 36 Ṣùgbọ́n nípa ìgba àti àkókò kò sí ẹni tí ó mọ́, àwọn angẹli ti ọ̀run kò tilẹ̀ mọ́, tábì ọmọ, bí kò ṣe Baba nìkan. 37 Bíi ọjọ́ Noaha ti wá, bệni dídé ọmọ ènìyàn. 38 Bí ó ti rí sáju ìkun omi wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mun, wọ́n ń gbéyàwó bêni à ń fa ìyàwó fún ni títí ọjọ́ tí Noaha fi wọ inú ọkọ̀, 39 wọ́n kò sì mọ ohun kó hun títí ìkún omi fi dé tí ó si gbé wọn lọ- bệni díde ọmọ ènìyàn yíò rí. 40 Nígbànâ ni okùnrin meji yíò wa lórí pápá- a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 41 Obìrin méjì yíò ma lọ̀ pẹ̀lú ònlọ̀- a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀. 42 Nítorínâ ẹ má ṣọ́nà, nítorí ẹ̀yín kò mọ ìgbà tí olúwa yín yíò dé. 43 Sugbon mo eyi, pe ti oluwa ile n a ba mo siko ti ole yio wa ni ale, o n iba si ti so na ki aba ko ile re. 44 Nitorinan e gbodo wani imura sile, nitori omo eniyan yio de ni wakati ti eyin ko mo 45 Nitorina tani oloto ati ologbon omo odo na ti olowa re yio fi se alakoso ile re lati ma fun won ni ounje ni asiko ti o ye? 46 Ibukun ni fun omo odo nan ti oluwa re ba ti o n se won nogbati o ba de. 47 Lotito ni mo wi fun yin pe oluwa re yio fi se olori gbogbo hun ti o ni. 48 Ṣùgbọ́n tí ọmọ ọ̀dọ̀ búburú náà bá wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, 'Olúwa mí pẹ́', 49 bẹ́ẹ̀ni ó sì n ni àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ lára òhún sì ń jẹ ó sì ń mu àmupara; 50 nígbàná ni olúwa ọmọ ọdọ náà yíò dé ní ọjọ́ tí ọmọ ọ̀dọ̀ náà kò rò àti wàkàtí tí kò mọ̀ 51 Nígbàná ni olúwa rẹ̀ yíò jẹ ẹ́ ní ìyà yíò sì yan ìpín rẹ̀ láàrin àwọn alágàbàngebè, níbi ti ẹkún òhun ìpayín keke gbẹ́wà.