Orí Kẹtàlélógún

1 Nígbà náà ni, Jésù bá ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ sọ̀rọ̀. 2 Ó wí pé, àwọn akọ̀wé àti àwọn farisí jòkó ní ipò Mose . 3 Nítorì náa, ẹ máa gbọ ohun gbogbo tí wọ́n ń sọ fún yín, ẹ máa fiyè sí wọn kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Ẹ máse tẹ̀lé ìṣe wọn, nítorí wọn a máa sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kìí fi sí ìṣe. 4 Bẹ́ẹ̀ni, wọn a máa di ẹ́rù wúwo tí ó nira láti gbé lé áwọn ènìyàn ní èjìká, ṣùgbọ́n, àwọn tìkalára won kìí gbìyànjú láti ṣe ìrànwọ́ láti gbé wọn. 5 Wọ́n fẹ́ láti máa ṣe àṣehàn. Nítorí wọ́n a máa ṣe fìláktẹ́rì wọn kí ó tóbi, kí àwọn ìṣẹ́tí àwọn aṣọ wọn sì ṣe gẹ̀rẹ̀yẹ̀. 6 Wọ́n a máa fẹ́ áwọn àyè pàtàkì ní ibi àsè àti àwọn ibujoko pàtàkì nínú Sínágọ́gù 7 Wọ́n sì tún fẹ́ kí a máa kí wọn ní ìkí ẹ̀yẹ nínú ọjà, kí àwọn ènìyàn sí màa pè wọ́n ní 'Rábì.' 8 Sùgbọ́n kí ẹ máṣe jẹ́ kí á pè yín ní 'Rábì', nítorí 'Rábì' kan ṣoṣo ni ẹ ní, ará sì ni gbogbo yín jẹ́. 9 Ẹ máṣe pe ẹnìkẹ́ni láyé yi ní bàbá yin, nítorí Bàbá kan ṣoṣo ni ẹ ní, ọ̀run ni ó sí wá. 10 Bákan náà, kí ẹ máṣe jẹ́ kí á pè yín ní 'olùkọ́ni,' nítorí olùkọ́ni kan ṣoṣo ni ẹ ní, tíí ṣe Krístì. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí o gajù lọ láàrin yín ni yóò jẹ́ ìránsẹ́ yín. 12 Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnití ó bá si rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a ó gbé ga. 13 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹ̀yin Akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! ẹ̀yin a máa tìlẹ̀kùn ọ̀run mọ́ ènìyàn. Nítorí ẹ̀yin tìkalára yín kọ̀ láti wọ̀ ọ́, ẹ kò sì gba àwọn tí ó fẹ́rẹ̀ wọlé láti ṣe bẹ́ẹ̀. 14 Ègbé ni fún ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! Ẹ̀yin ń lu àwọn opó ní jìbìtì nígbàtí ẹ̀ ń ṣe kárími pẹ̀lú àdúrà gìgùn. Nítorínà ẹ ó gba ìdálẹ́bi tó pọ̀jù lọ 15 Ègbé ni fún ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorítí ẹ̀ ń lọ sókè sódò láti yi ẹyọ ènìyàn kan padà, nígbà tí ó bá sì di ọmọ ẹ̀yìn n yín, ẹ ó sọ ọ́ dí ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìsẹ́po méjì ti yín. 16 Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ̀jú tí ó ń tọ́ ẹlòmíràn sọ́nà, ẹ̀yin wípé, 'Bí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́mpílì búra, kò já mọ́ nkankan. Sùgbọ́n ó pọn dandan fún ẹnití ó bá fi wúrà tẹ́mpílì láti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ.' 17 Ẹ̀yin afọ́jú aláìlóye, èwo ló ṣe pàtàkì, wúrà tàbí tẹ́mpílì tó sọ wúrà di mímọ́? 18 Àti wípé, 'Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pẹpẹ búra, kò já mọ́ ǹkankan. Ṣùgbọ́n ó pọn dandan fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àwọn ẹ̀bùn orí pẹpẹ búra láti mú ìbúra rẹ̀ ṣẹ. 19 Ẹ̀yin afọ́jú ènìyàn! Èwo ló ṣe pàtàkì jù, ẹ̀bùn tàbí pẹpẹ tí o sọ̀ ẹ̀bùn di mímọ́? 20 Nítorí náà, ẹni tí ó bá búra pẹ̀lú pẹpẹ, búra pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó wà lóríi rẹ̀. 21 Ẹni tí ó bá fi tẹ́mpílì búra, búra pẹ̀lú rẹ̀ àti ẹni tí ń gbé nínú rẹ̀ 22 Ẹni tí ó bà sì fi ọ̀run búra, búra pẹ̀lú ìtẹ́ Ọlọ́run àti Ẹni tí ó jòkó lórí ìtẹ́ naa. 23 Ègbé ni fún ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! Ẹ̀ ń san ìdáméwàá lórí minti, dili ati kumini, ṣùgbọ́n ẹ kọ̀ láti ṣe àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú òfin - tí ń ṣe ìwọ̀nyí, ìdájọ́ òdodo, àánú àti ìgbàgbọ́. Àwọn wọ̀nyi ni ó yẹ kí ẹ máa ṣe láì kọ àwọn ìyókù sílẹ̀. 24 Ẹ̀yin afọ́jú tí ń tọ́ni sọ́nà, ẹ fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ ẹ̀ ń pa làpálàpá! 25 Ègbe ni fún ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! Nítorítí ẹ̀yin ń fọ ìta kọ́ọ̀bù àti abọ́ ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ọ̀kánjùa àti àìlèkóra ẹni ní ìjánu. 26 Ẹ̀yin afọ̀jú Farisí, ẹ kọ́kọ́ fọ inú kọ́ọ̀bù àti abọ́ ná, kí ìta wọn náà sì mọ́. 27 Ègbé ni fún ẹ̀yin akòwé àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́, èyí tó lẹ́wà ní òde ṣùgbọ́n tí inú rẹ̀ kún fún egungun òkú àti ohun àìmọ́ gbogbo 28 Bákan náà, ẹ̀yin fara hàn bíi olódodo níwájú àwọn ènìyàn ṣùgbọn ẹ kún fún àgàbàgebè ati àìṣedéédé gbogbo. 29 Ègbé ni fún ẹ̀yin akọ̀wé àti ẹ̀yin Farisì, alágàbàgebè! Nítorítí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì, ẹ̀ sì ṣé ibojì àwọn eni mímọ́ lọ́ṣọ̀ọ́. 30 Ẹ̀yin wípé, 'Bí ó bá ṣe pé a wà ní àkókò àwọn baba wa ni, àwa ìbá má ti dara pọ̀ mọ́ wọn láti pa àwọn wòlíì náà.' 31 Nítorí náà, ẹ̀ ń jẹ́rìí ta ko ara yín wípé ọmọ àwọn ẹni tí ó pa àwọn wòlíì ni yín. 32 Ẹ̀yin fi ohun gbogbo jọ àwọn bàbá yín ní àjọtán 33 Ẹ̀yin ejò àti ọmọ paramọ́lẹ̀, bá wo ni ẹ̀yin ó ṣe bọ́ lọ́wọ́ ewu ìdájọ́ ọ̀run àpáádì? 34 Nítorí náà, kíyèsi, Èmi ń rán àwọn wòlíì, àwọn ọlọgbọ́n àti àwọn akọ̀wé síi yín. Ọ̀pọ̀ wọn ni ẹ ó pa, tí ẹ ó sì kàn mọ́ àgbélèbú, ọ̀pọ̀ wọn ni ẹ ó nà ní ẹgba nínú sínágọ́gù yín, ẹ o sì lé wọn jáde kúrò láti ìlú de ìlú 35 Orí yín ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ tí a ti pa ní gbogbo orílẹ̀ ayé yóò wà, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀jẹ̀ Ábẹ́lì títí dé ẹ̀jẹ̀ Sakaráyà ọmọ Barakia tí ẹ pa sí agbede méjì pẹpẹ àti ibi mímọ́. 36 Lóòtọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nkan wọ̀nyí yóò wá sí ìmúṣẹ lórí ìran yín. 37 Jèrúsalẹ́ẹ̀mù, Jèrúsalẹ́ẹ̀mù, ìwọ ẹni tí ń pa àwọn wolíì, tí o sì ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta! Mo gbìyànjú láti kó yín jọ bí adìrẹ ṣe máa ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sí abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò fi àyè gbà mí! 38 Kíyèsíi, ilé yín ti di ahoro. 39 Èmi wí fún yín pé, ẹ kì yóò rí Mi mọ́ títí ẹ ó fi wípé, 'Alábùkún ni fún ẹni tí o ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.'"