Orí kejì lélógún.

1 Jésù sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ́kàn si wípé. 2 ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí o se àsè ìgbeyàwó fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 3 ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde láti lọ pe àwọn tí a ti pè sí ibi àsè ìgbeyàwó náà, ṣùgbọ́n wọn kò ní wá. 4 Lẹ́ẹ̀kan si ọba rán àwọn ìránsẹ́ rẹ̀ míràn jáde, wípé, 'sọ fún àwọn tí a pè, "wòó, mo ti pèsè óunjẹ alẹ́ mi. Mo ti pa àwọn màálù mi sísanra, oun gbogbo sì ti setán. E máa bọ̀ íi ibi `sè iìgbeyàwó." 5 Ṣùgbọ́n wọn kò fiyèsi wọ́n sì bá ti wọn lọ, ọ̀kan sí oko, àti ómíràn sí ibi òwò rẹ. 6 àwọn tó kù sì kó àwọn ìránsẹ́ ọba ní papámọ́ra, wọn yẹ̀yẹ́ wọn, wọ́n jẹ wọ́n níyà, wọ́n sì pa wọ́n. 7 Inú bí ọba ó sì rán àwọn jagunjagun rẹ̀, wọ́n pa àwọn apànìyàn náà, bẹ́ẹ̀ni wọ́n sun ìlú wọn. 8 Nígbànáà ó wí fún àwọn ìránsẹ́ rẹ̀, 'ìgbeyàwó ti se tán, sùgbọ́n àwon tí a pè wọn kò yẹ. 9 Nítorí náà ẹ lọ sí ìkóríta àwọn òpópó ọ̀nà kí e sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹ bá le ríwá sí ibi àsè ìgbeyàwó.' 10 àwọn ìránsẹ́ sí jáde lọ sí òpópó ọ̀nà wọ́n sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n rí, àti búburú àti rere. Gbọ̀ngàn ìgbeyàwó náà sì kún fún àwọn àlejò. 11 Ṣùgbọ́n nígbàtí ọba wọlé wá láti wo àwọn àlejò, ó rí ọkùnrin kan níbẹ̀ tí kò wọ asọ ìgbeyàwó. 12 ọba wí fún-un pé, 'ọ̀ré, bá wo lo se wọ gbọ̀gàn yi wá láì ní asọ ìgbeyàwó?' Sùgbọ́n ọkùnrin náà kò sọ ọ̀rọ̀ kankan. 13 Nígbànáà ni ọba pàsẹ fún àwọn ìránsẹ́ rẹ̀ 'ẹ de ọkùnrin yí ní ọwọ́ àti ẹsẹ́, ẹ gbée jù sí ìta nínú òkùnkùn, níbi tí ẹkún òun ìpayín keke yó wà.' 14 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn la pè, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ la yàn. 15 Lẹ́yìnnáà àwọn Farisí lọ gbìmò bí wọn yó se mú Jésù nípa ọ̀rọ̀ ẹnu òun fúnrarẹ̀. 16 Nígbànáà ni wọ́n rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn síi pẹ̀lú àwọn ará Hẹ́rọ́dù. Wọ́n wí fún Jésù pé "Olùkọ́ni, àwa mọ̀ pé olóòótọ́ ni ìwọ àti pé o sì ńkọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. O kò bìkítà fún èró enìkankan àti wípé ìwọ kìíse ojúsàájú láàrín àwọn ènìyàn. 17 Nítorínà sọ fún wa, kínni èrò tì rẹ? Sé ó bà òfin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí kò bá òfin mu?" 18 Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà búburú wọn ó wí f´n wọn pé , "èése tí ẹ̀yin ńdán mi wò, ẹ̀ yin alágàbàgebè? 19 ẹ fi owó idẹ kan fún owó-orí hàn mí". Nígbànáà ni wọ́n mú owó idẹ mẹ́ẹ̀wá wá sọ́dọ̀ọ rẹ̀. 20 Jésù wí fún wọn "àwòrán àti orúkọ tanì yí?" 21 Wọ́n wí fún un pé "Késárì" Jésù síì wí fún wọn pé, "nítorínà, ẹ fi fún Késárì ohun tí se ti Késárì àti fún Ọlọ́run ohun tí se tí Ọlọ́run" 22 Nígbàtí wọ́n gbọ́, ẹnú yà wọ́n. Wọ́n fi sílẹ̀ ,wọ́n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ọ̀ rẹè. 23 Ní ọjọ́ náà díẹ̀ nínú àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde wá sọ́dóọ rẹ̀. Wọ́n bií 24 wípé, "Olùkọ́ni, Mósè wípé "bí ọkùnrin kan bá kú láì ní ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀ kí ó sì bí ọmọ fún arákùnrin rẹ` ní dandan. 25 Ọkùnrin méje kan wà. ẹnì kínní fẹ́ ìyàwó ó sì kú. Láì ní ọmọ, ó fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀. 26 Nígbànáà ni arákùnrin kejì se bákannáà, bẹ́ẹ̀sì ni arákùnrin kẹ̀ta, títí lo dé arákùnrin keèje. 27 Lẹ́yìn gbogbo wọn , obìnrin náà kú. 28 Nísinsìnyí ní àjíǹde, ìyàwó ti tani yóò je nínú àwọn ọkùnrin méjèèje? Nítorí gbogbo wọn ló ti fẹ́ẹ n´ ìyàwó." 29 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó wí fún wọn pé, è yin ńse àsìse, nítorí tí e kò mọ ìwé mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run. 30 Nítorí ní àjíǹde a kìí gbé ìyàwó bẹ́ẹ̀sì ni á kìí fa ọmọ f'ọ́kọ. nípò bẹ́ẹ̀, wọ́n dàbí ángẹ́lì lọ́run. 31 Ṣùgbọ́n ní ti àjíǹde àwọn òkú, ẹ̀ yin kò a ti kà nípa ohun tí Ọlọ́run bá yin sọ wípé, 32 èmi ni Ọlọ́run Ábráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù? Ọlọ́run kìí se Ọlọ́run òkú bí kò se Ọlọ́run alàyèe." 33 Nígbàtí àwọn èrò gbó è yí, ẹnú yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ọ rẹ̀. 34 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn Farisi gbọ́ pé Jésù ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀. 35 ọ̀kan nínú wọn tí se amòfin, bèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ̀, ó ńdán-an wò. 36 "Olùkọ́ni, è wo ló tóbi jù nínú àwọn òfin?" 37 Jésù wí fun pé , "fẹ Olúwa Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ." 38 è yí ni ó tóbi jù àti èkínní nínú òfin. 39 àti èkejì nínú òfin sì dàbí rẹ̀, 'fẹ́ aládúúgbò rẹ bí ara rẹ' 40 Lórí òfin méjì yí ní gbogbo òfin àti àwọn wòlíì dúró lé." 41 Nísinsìnyí tí àwọn Farisí ti kó ara wọn jọ pọ̀, Jésù bèrè ìbéérè kan lọ́wọ́ wọn. 42 ó wípé, "kínni ntí ẹ̀ yin rò nípa Krístì náà? ọmọ taa ní se?" Wọ́n wí fun pé , "ọmọ Dáfídì." 43 Jésù wí fún wọn pé, "báwo ni Dáfíd` nínú ẹ̀mí fi pèé ní Olúwa wípé, 44 'Olúwa sọ fún olúwa mi, "jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí tí èmi yó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ" 45 Bí Dáfídì bá pe Krístí náà ní 'Olúwa' báwo ló se jẹ́ ọmọ Dáfídì?" 46 Kò sí ẹni tí ó le fún ní èsì ọ̀rọ̀ kan, bẹ́ẹ̀ni kò sì sí ẹni tí ó tún bèrè ìbéèrè kankan mọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ láti ọjọ́ náà lọ.