ORÍ KỌKÀNLÉLÓGÚN

1 Bí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ ti dé Jerúsálẹ̀mù, wọ́n lọ sí Bẹ́tífájì ní orí òkè Ólífì, nígbànáà ni Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn méjì, 2 ó wí fún wọn pé, "ẹ lọ sí ìlú kejì, ní kété ni ẹ̀yin ò rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ àti ọmọ ẹṣin pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. 3 Tí ẹnikẹ́ni bá sọ ohunkóhun, ẹ wípé, 'Olúwa ní fi í ṣe', nígbànáà ni yóò jọ̀wọ́ rẹ̀ fún yín" 4 Báyìí ni ó wá sí ìmúṣe ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòólì. Wípé, 5 ''Sọ fún ọmọbìnrin Ṣíónì, 'wòó, Oba yín n bọ̀, ní ìrẹ̀lẹ̀, ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́-- ní orí ọmọ ẹṣin,'' 6 Nígbànáà ní àwon ọmọ ẹ̀yìn lọ ṣe gẹ́gẹ́bí Jésù ti sọ fún wọn. 7 Wọ́n mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ọmọ ẹṣin náà, pẹ̀lú aṣọ wọn lórí wọn, Jésù síì jókò lóríi aṣọ náà. 8 Ọ̀pọ̀ ènìyàn síì tẹ́ aṣọ sí ọ̀nà, àwon mìíràn gé ẹ̀ka láti ara igi, wọ́n sì tẹ́ẹ sí ọ̀nà. 9 Nígbànáà ní ọ̀pọ̀ ènìyàn tó n lọ ní iwájú àti lẹ́yìn Jésù ń pariwo, ''Hòsánà sí ọmọ Dáfídì! Ìbùnkún ni fún ẹni tí ó wá ní orúkọ Olúwa, Hòsánà lókè ọ̀run! 10 Bí Jésù ṣe dé Jerúsálẹ́mù, gbogbo ìlú ṣíì ru, wọ́n síì sọ pé, "Tani èyí?" 11 Ọ̀pọ̀ ènìyàn síì dáhùn, "Èyí ni Jésù wòólì láti Násárẹ́tì ti Gálílì." 12 Lẹ́yìn náà ni Jésù wọ inú Tẹ́mpílì. Ó sì lé gbogbo àwọn tó n tà, tó n rà nínú Tẹ́mpílì, Ó da tábílì àwọn tó n ṣe pàsípárọ̀ owó pẹ̀lú ibùjókò àwọn tó n ta àdàbà. 13 Ó sọ fún wọn pé, ''Ati kọ ọ́ pé, 'ilé àdúrà ni a ó ma pe ilé Mìi,' ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeé ní ihò àwọn adigunjalè.'' 14 Nígbànáà ni àwọn afójú àti àwọn arọ tọ̀ọ́ wá nínú Tẹ́mpílì, ó sì wò wọ́n sàn. 15 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn olú àlùfáà àti àwọn akòwé rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, àti ariwo àwọn ọmọ nínú Tẹ́mpílì wípé, ''Hòsánà sí ọmọ Dáfídì,'' inú bí wọn gidigidi. 16 Wọ́n sọ fún wípé, ''Ǹ jẹ́ ìwọ gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yìí ń sọ?'' Jésù wí fún wọn pé, ''Bẹ́ẹ̀ni! ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ẹ̀yin kò tí kà rí, 'Láti ẹnu àwọn ọmọ kékèké àti ọmọ ọwọ́ ni a ti ṣe àṣepé ìyìn'?'' 17 Jésù fi wọ́n sílẹ̀, ó sì lọ sí Bẹ́thánì, ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. 18 Bí Ó ti padà sí ìlú ní òwúrọ̀, ebi ń paá. 19 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ ní ẹ̀baa ojú ọ̀nà, Ó lọ sí bẹ̀, kò sì rí ohunkóhun lórí rẹẹ̀ bíkòse ewé. Ó wí fún igi ọ̀pọ̀tọ́ náà, ''kì yóò sí èṣo láti ara rẹ̀ mọ́,'' ní kété igi ọ̀pọ̀tọ́ náà síì gbẹ. 20 Nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yín ríi, ẹnú yà wọ́n, wọ́n sì sọ pé, ''báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíakía?'' 21 Jésù síì dáhùn, Ó wí fún wọn pé, ''lótìtọ́ ni mo wí fún yín, tí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ tí ẹ kò sì ṣe iyéméjì, ẹ̀yin ò ní ṣe ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan ṣùgbọ́n ẹ̀yin ô wí fún òkè, 'Dìde kí o sì bọ́ sínú òkun,' yóò sí rí bẹ̀. 22 Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá bérè nínú àdúrà, pẹlú ìgbàgbọ́, ẹ ó ríigbà.'' 23 Nígbàtí Jésù ti wọ inú Tẹ́mpílì, àwọn olú àlùfáà àti àwọn àgbàgbà tọ̀ọ́ wá bí ó ti ń ṣe ìdánilệkọ́, wọ́n bií pé, ''Nípa àsẹ wo ni ìwọ fi se nǹkan wọ̀nyíi, àti tani ó fún ọ ní àṣẹ yìí?'' 24 Jésù síì dáwọn lóhùn wípé, ''Èmi pẹ̀lú yóò bi yín ní ìbéerè kan. Tí ẹ̀yin bá sọ ọ́ fún mi, èmi yóò sọ nípa àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyíi. 25 Ìtẹ̀bọmi ti Jòhánù- níbo lotí wá? Láti ọ̀run àbí láti ọwọ́ ènìyàn?'' Wọ́n jíròrò láàrin ara wọn, wípé, ''bí àwá bá sọ pé, 'láti ọ̀run,' yóò sọ fún wa pé, 'kínni ìdí tí ẹ̀yin kò fi gbàgbọ́?' 26 Ṣùgbọ́n bí àwá bá sọ pé, 'láti ọwọ́ ènìyàn,' àwá bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn, nítorí wọ́n rí Jòhánù gẹ́gẹ́bíi wòólì.'' 27 Wọ́n sì dá Jésù lóhùn wípé, ''àwa ò mọ̀.'' Oun pẹ̀lú sì sọ fún wọn, ''bẹ́ẹ̀ni èmi kò ní sọ nípasẹ̀ àṣẹ tí mo fi ṣe nǹkan wọ̀nyíi. 28 Ṣùgbọ́n kínni ẹ̀yin ń rò? Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ótọọ àkọ́kọ́ lọ ó sì wípé, 'ọmọ mìi, lọ ṣiṣẹ́ ní ọgbà àjàrà lónǐ. 29 Ọmọ náà dáhùn wípé, 'mi ò lọ,' ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà ó yí ọkàn rẹ padà ó sí lọ. 30 Lẹ́yìn náà ni ó tọọ èkejì lọ ó sì sọ nkankanna fûn. Ọmọ síì dáhùn wípé, 'èmi ó lọ,' ṣùgbọ́n kò lọ. 31 Èwo nínú àwọn ọmọ méjéjì ló ṣe ìfẹ́ baba?'' wọ́n wípé, ''ọmọ àkọ́kọ́.'' Jésù ṣọ fún wọn pé, ''lótìtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowóòde àti àwọn alágbérè yóò wọ ìjọba Ọlọ́run sájú yín. 32 Nítorítí Jòhánù wá ní ọ̀nà òdodo, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàágbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn alágbérè gbàágbọ́. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ ríi èyí, ẹ kò ronúpíwàdà, ẹ kò tún gbàágbọ́. 33 Ẹgbọ́ òwe mìíràn. Ọkùnrin onílẹ̀ kan wáà, ó gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì mọ odi yíi ká, ó gbẹ́ ìfún èṣo sínú rẹ̀, ó kọ́ ìṣọ́, ó sì tún fi yá àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún. Ó sì lọ sí ìlú òdì kejí. 34 Nígbàtí àkókò ìkórè sún mọ́, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún láti bèrè èṣo àjàrà. 35 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún rí wọn, wọ́n lù ọ̀kan, wọ́n pa òmíràn, wọ́n sì sọ òkò fún òmíràn. 36 Ọkùnrin onílẹ̀ náà rán àwọn òjíṣẹ́ míràn, ju ti àkọ́kọ́ lọ, ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún náà tún ṣe bí wọ́n ti ṣe àwọn ti ìsájú. 37 Lẹ́yìn náà, ó rán ọmọ rẹ́ lọ sí wọn, wípé, 'Wọn ó ò bu ọlá fún ọmọ mìí.' 38 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún rí ọmọ náà, wọ́n sọ láàrin ara wọn, Èyí ni àrólé. Ẹwá, ẹ jẹ́ kí á paá, kí á gba ilẹ̀ ìní.' 39 Wọ́n sì mu, wọ́n jùú sí odi àjàrà, wọ́n sì pá. 40 Nígbàtí okùnrin tí ó ni àjàrà náà bá dé, kínni yóò ṣe fún àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún?'' 41 Wọ́n sọ fun; ''yóò pa àwọn òtòsì okùnrin náà ní ọ̀nà aìda, yóò sì fi àjàrà náà fún àwọn àgbẹ̀ oníṣẹ́ odún míràn, àwọn tí yóò fún un ní ẹ̀tọ́ rẹ̀ ní àkókò ìkórè.'' 42 Jésù síì wí fún wọn, ''Ǹjẹ́ ẹ̀yin ò tí kà nínú Ìwé Mímọ́, 'Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílè ti di pàtàkì igun ilé. Èyí wá láti ọ̀dọ Ọlọ́run wa, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa'? 43 Nítorí náà mo wí fún yín, a ô gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ́ èdè tí ó so èso rẹ̀. 44 Ẹnikẹ́ni tó bá kọlu òkúta yìí yóò fọ sí wẹ́wẹ́. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òkúta yìí bá wólù yóò rún sí wẹ́wẹ́.'' 45 Nígbàtí àwọn olú àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ òwe rẹ̀, wọ́n síì wòye pé àwọn ni ó ń bá wí. 46 Wọ́n wá láti múu, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn n bà wọ́n, nítorí àwọn ènìyán gbàá bíi wòólì.