Orí Ogún

1 Nítorí Ìjọba Ọ̀run dàbí onílé kan tí ó jáde ní òwúrọ́ lati lọ gba àwọn òsìsẹ́ sí ọgbà àjàrà rẹ̀. 2 Nígbà tí òhun àti àwọn òsìsẹ́ náà ti fohuǹ sọ̀kan lórí dénárì kan fún ọjọ́ kan, ó rán wọn lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀. 3 Ó tún jáde ní wákàtí kẹta ó sì rí àwọn òsìsẹ́ mìíràn tí wọn ń dúró láìní isẹ ní ibi ọjà. 4 Sí wọn ó wípé 'Èyin náà ẹ lọ sí ọgbà àjàrà náà, màá fún yín ní ohun tí ó bá tọ́.' Wọ́n sì lọ siṣẹ́. 5 Ó tún jáde ní wákàtí kẹfà àti ní wákàtí kẹsàán, ó sì ṣe bákan náà 6 Lẹ́ẹ̀kan síi ní wákàtí kọkànlá ó jáde ó sì tún rí àwọn mìíràn ti wọ́n ńdúró láìse ohunkóhun. Ó sì wí fún wọn pé 'kílódé tí ẹ fi ńdúró láì se ohunkóhun fún gbogbo ọjọ́' 7 Wọ́n sì wi fún un pé 'nítorí kòsí ẹni tí ó gbàwá síṣẹ́.' Ó wí fún wọn pé 'Ẹ̀yin náà ẹ lọ sí ọgbà àjàrà náà' 8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà wí fún alámòójúto rẹ̀ wípé, 'pe àwọn òsìṣẹ́ náà kí o sì san owó ọ̀yà wọn fún wọn, láti ẹni tí ó kẹ́hìn dé títí dé ẹni tí ó kọ́kọ́ dé.' 9 Nígbà tí àwọn òsìṣẹ́ tí wọ́n gbà ní wákàtí kọkànlá wá, ẹni kọ̀ọ̀kan wọn gba dénárì kọ̀ọ̀kan 10 Nígbà tí àwọn òsìṣẹ́ kìnní dé, wọ́n rò pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n àwọn náà gba dénárì kọ̀ọ̀kan. 11 Nígbàtí wọ́n gba owó ọ̀yà wọn, wọ́n fi ẹ̀hónú hàn sí olóko náà. 12 Wọ́n wípé, 'àwọn òsìṣẹ́ ìkẹyìn yìí siṣẹ́ fún wákàtí kan péré, ṣùgbọ́n ìwọ ti sọ wọn di ẹgbẹ́ pẹ̀lú wa, àwa tí a ti gbé bùkátà ọjọ́ yìí àti tí ó ti fi orí pa òòrùn látàárọ̀' 13 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà dáhùn ó sì wí fún ọ̀kan nínú wọn pé, 'Ọ̀rẹ́, èmi kò ṣe ó ní ìjàm̀bá. Ǹjẹ́ ìwọ kò dábàá pẹ̀lú mi fún dénári kan?' 14 Gbà ohun tí ó jẹ́ tìrẹ ki o sì bá ọ̀nà rẹ lọ. Mo yàn láti fún àwọn òsìṣẹ́ ìkẹyìn yìí ní ohun kan náà pẹ̀lú yín. 15 Ǹjẹ́ èmi kòní ẹ̀tọ́ láti ṣe bí ó ṣe wùmí pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ ti tèmi? Àbí sé ò ń jowú nítorí pé mo lawọ́? 16 Nítorí náà ẹni ìkẹhìn yóò di àkọ́kọ́, àti ẹni àkọ́kọ́ náà yóó di ìkẹyìn. 17 Bí Jésù ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó mú àwọn méjìlàá náà sẹ́gbẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ lójú ọ̀nà ó wí fun wọn, 18 Ẹ wòó, à ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọn yóò sì fi ọmọ ènìyàn lé ọwọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi sí iku 19 wọn yóò sì fi í fún àwọn kèfèrí láti fi í ṣe yẹ̀yẹ́, láti nà án, àti láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Ṣùgbón ní ọjọ́ kẹta a yóò jí i dìde. 20 Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọkùnrin Ṣébédè wá bá Jésù pèlú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ó tẹríba níwájú rẹ̀ ó ṣì bèèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀. 21 Jésù wí fún un pé, Kínni o fẹ́? Ó ṣì wí fún un pé 'Pàṣẹ kí àwọn ọmọkùnrin méjì mi wọ̀nyí le jókòó, ọ̀kan sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ìkejì sí ọwọ́ òṣì rẹ, ní ìjọba rẹ.' 22 Ṣùgbọ́n Jésù dáhún ó sì wípé, "Ìwọ kò mọ ohun tí ìwọ ń bèèrè. Ṣé ìwọ tó láti mu láti ife tí èmi yóò mu?" Wọ́n dáhùn pé "A tó bẹ́ẹ̀." 23 Ó wí fún wọn pé "lótìítọ́ ni ẹ̀yin yóò mu ife mi. Ṣùgbọ́n láti jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti ọwọ́ òṣì mi, kìíṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí Bàbá mi ti ṣètò rẹ̀ fún." 24 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́wàá ìyókù gbọ́ èyí, inú bíwọn sí àwọn arákùrin méjì náà. 25 Ṣùgbọ́n Jésù pè wọ́n sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, "Ẹ̀yin mọ̀ wípé àwọn olórí àwọn kèfèrí a máa fi tipá jọba lórí wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn gbajúmọ̀ wọn a máa lo agbára lórí wọn. 26 Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ rí báyìí láàrin yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá fẹ́ láti di gíga láàrin yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín, 27 bẹ́ẹ̀ náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ àkọ́kọ́ láàrin yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín, 28 gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kòṣe wá láti jẹ́ ẹni tí à ń sìn, ṣùgbọ́n láti sìn, àti láti fún ẹ̀mí rẹ̀ bí ìràpadà fún àwọn tí ó pọ̀. 29 Bí wọ́n ti ń jáde kúrò láti Jẹ́ríkò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tẹ̀ lé e. 30 Àwọn afọ́jú méjì kan ṣì wà tí wọ́n jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ wípé Jésù ń kọjá lọ́, wọ́n kígbe "Olúwa, Ọmọ Dáfídì, sàánú fún wa." 31 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà bá wọn wí, wọ́n sọ fún wọ́n ẹ dákẹ́ jẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n tún kígbe sókè jù bẹ́ẹ̀lọ "Olúwa, Ọmọ Dáfídí, ṣàánú fún wa." 32 Nígbà náà ni Jésù dúró sójú kan ó ké pè wọ́n, "Kínni ẹ fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?" 33 Wọ́n wí fún un pé, "Olúwa, kí ojú wa le là" 34 Nígbà náà Jésù, ẹni tí àánú ṣe, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ojú wọn la wọ́n ṣì tẹ̀ lé e.