Orí Kokándínlógún

1 Ó sì se nígbàtí Jésù parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ó kọjá lọ sí Gálílì, Ó sì wá sí agbègbè Jùdíà ní ìkojá odò Jọ́dánì. 2 Ọ̀pọ̀ èrò si tèlé e, ó sì wò wọ́n sàn níbẹ̀. 3 Àwọn Farisí tǒ wá, wọ́n danwò, wón wípé, "Ǹjẹ́ ó yẹ kí okùnrin kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí kan bí? 4 Jésù sì dá wọn lóhùn wípé, "Sé ẹ̀yín kò kǎ wípé ẹnití ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ takọ tabo ni ó dá wọn? 5 Enití ó dá wọn tún sọ wípé, "Nítorí ìdí èyí ni okùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dara pọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèjì yóò sí di ara kàn na?" 6 Nìtorínà wọn kǐ se méjì mọ, sùgbọ́n ara kàn niwọ́n. Nítotínà ohun tí Ọlọ́run bá ti so pọ́, kí ẹnikẹ́ni másè tú wọn ká. 7 Wọ́n wí fun pé, "Kí ni ìdí tí Mósè fi pàṣe fún wa kí á fún wọn ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀ àti kí á sì lé wọn jáde?" 8 Ó sì dáwọn lóhùn wípé, "Nítorí ọkàn líle yín ni Mósè fi gbà yín lâyè láti kọ àwọn ìyàwó yín sílẹ̀, sùgbọ́n kòrí bệ láti ìbẹ̀rẹ̀. 9 Mo wí fún yín, ẹni tó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, àyàfi fún ìwà àgbèrè, tí ò sì lọ fẹ́ ẹlòmíràn, irú ẹni bệ dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè; àti ọkùnrin tí ó fẹ́ ìyàwó tí a ti kọ̀ sílẹ̀, òhun nâ dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè." 10 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì sọ fún Jésù pé, "Tí ó jẹ́ bí ìpín ọkùnrin se rí pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ nì yí, kò dára láti gbéyàwó." 11 Jésù wí fún wọn, "Kì ń se gbogbo ènìyàn ni ó le gba ẹ̀kọ́ yǐ, àyàfi àwọn tí a fi yòǹda láti gbà. 12 Nítorí àwọn ìwọ̀fà kan wà bệ láti inú ìyá wọn wá, àwọn ìwọ̀fà kan sî wí tí a sọ di ìwọ̀fà láti ọwọ́ ènìyàn wá, àwọn ìwọ̀fà kán sì wá tí wọ́n sọ ara wọn di ìwọ̀fà nítorí ìjọba Ọlọ́run. Ẹnití ó bá setán láti gba ẹ̀kọ́ yǐ, jẹ́ kí ó gbǎ." 13 Nígbànáà ni wọ́n gbé àwọn ọmọdé tǒ wá kí ó le gbé ọwọ lé wọn àti kí ó gbàdúrà fún wọn, sùgbọ́n àwọn ọmo ẹ̀yín rẹ̀ báwọn wí. 14 Ṣúgbọ́n Jésù wípé, Fún àwọn ọmọdé na láàyè, másě dáwọn lẹ́kùn láti tọ̀ mí wá, nítorítí irú wọn ni ìjọba ọrun." 15 Ó gbé ọwọ́ Rẹ̀ lé àwọn ọmọ nâ, ó sì ti bẹ̀ lọ. 16 Sì kíyèsi, arákùnrin kan tọ Jésù wá wípé, "Olùkọ́ni, ohun rere wo ni èmí lese kí èmi lení ìyè àìnípẹ̀kun?" 17 Jésù wí fún pé, "Ěṣe tí ìwọ fi b mí nípa ohun tí ó dára? Nkàn soso ni ó dára, tí ìwọ bá fẹ́ wọ inú ìyè àìnípẹ̀kun, pa òfin nâ mọ́." 18 Arákùnrin nâ sọ fun, "Òfin èwo?" Jésù wípé, Másě pa, másě àgbèrè, másě jí, másě jẹ́rǐ èké, 19 bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá, kí o sì fẹ́ aládùúgbò gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̌." 20 Ọ̀dọ́mọkùnrin nâ sọ fun, "Gbogbo ǹkan wònyí ni mo ti ń pamọ́. Kínni mo tún nílò?" 21 Jésù wí fún, "Tí o bá fẹ́ láti di pípé, lọ, ta ohun tí o ní, kí o sì fún àwọn tálákà, wǎ sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá, kí o sì tẹ̀lé mi." 22 Ṣùgbọ́n nígbàtí arákùnrin nâ gbọ́ ohun tí Jésù sọ, ó kúrò pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀. 23 Jésù sọ fún áwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, "Lótìtítọ́ ni mo wí fun yín, ó sòro fún ọlọ́rọ̀ wọ ìjọba ọ̀run. 24 Lẹ́kànsi mo wí fun yín, ó rọrùn fun ìbákasíẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ ju kí ọlọ́rọ̀ wọ ìjọba Ọlọ́run." 25 Nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́, ẹnú yà wọn wọ́n sì wípé, "Tani ó ha le là?" 26 Jésù wò wọ́n ó sì wípé, Ènìà ní èyí sòro fún, ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe." 27 Pétérù dáhùn ó sì wípé, "Wòó, àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ a sì ti tọ̌ lẹ́yìn. Kínni àwa ô ha ní?" 28 Jésù sọ fún wọn, "Lótìtọ́ ni mo wí fun yín, nígbà ọ̀tun tí Ọmọ Ènìà bá jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀le yô jókòó lórí ìtẹ́ méjéjìlá, láti dájọ́ ẹ̀yà méjìlá ti Ísráẹ́lì. 29 Gbogbo ẹni tí ó fi ilé sílẹ̀, arákùnrin, arábìnrin, baba, ìyá, tàbí ilẹ́ nítorí orúkọ mi, yô rí ọrọrún gbà yóò sì jogún ayérayé. 30 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tó síwájú yóò kẹ́hìn, àwọn tó kẹ́hìn yóò síwájú.