Orí Kẹ̀rin

1 Níbo ni ìjà ati èdè-àìyedè ti wá láàrin yín ? ṣé kìí se nípa èròńgbà búburú tí ẹ ní sí ara yín? 2 Ìwọ nífẹ̀ sìí, o kò sì ní. O pa o ṣì ń ṣe ojúkòkòrò, ọwọ́ rẹ kò sì bàá. Ìwọ jà, o sì ṣe aáwọ̀. Ìwọ kò ní nítorí tí ìwọ kò béèrè . 3 Iwọ bèèrè ìwọ kò rí gbà nítorítí ìwọ bèèrè lọ́nà àìtọ́, nítorí tí o fẹ́ lòò fún ìfẹ́kùfẹ́ ara rẹ. 4 Ẹ̀yin alágbèrè obìnrin! Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìbárẹ́pọ̀ mọ́ ayé jẹ́ ìṣọ̀tá sí Ọlọ́run bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ayé ti sọ ra rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run 5 Tàbí ìwọ rò wípé lásán ni ìwé mímọ́ wípé, "Ẹ̀mí tí ó dásí inú wa ń jowú ní gidigidi. 6 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fúnni ore-ọ̀fẹ́ síi, bẹ́ẹ̀ni ìwé mímọ́ wípé, "Ó lòdì sí agbéraga, ṣùgbọ́n O fi ore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀." 7 Nítorí nà jọ̀wọ́ ara rẹ fún Ọlọ́run, kí o sì kọjú ìjà sí èsù, yóó sí sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ. 8 Súmọ́ Ọlọ́run, Yóó sì súnmọ́ ọ. Wẹ ọwọ́ rẹ mọ́ ìwọ ẹlẹ́ṣẹ̀, kí o sì wẹ ọkàn rẹ mọ́ ìwọ oníyèmejì. 9 Banújẹ́, sọ̀fọ̀ kí o sì sọkún! Jẹ́kí ẹ̀rín rẹ di ìkorò àti ayọ̀ rẹ di ìbánújẹ́. 10 Rẹ ara rẹ sìlẹ ní iwájú Olúwa, yóó sí gbè ọ ga. 11 Ẹmá ṣe sọ̀rọ̀ lòdì sí ara yín, ẹ̀yin ará, ẹni tí ó sọ ọ̀rọ̀ lòdì sí arákùnrin rẹ̀ tàbí dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ti ó lòdì sí òfin. Bí o bá dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kìí se olùpa òfin mọ́, bí kò ṣe onídàjọ́. 12 Ẹnìkan ni Ó fi òfin fúnni àti adájọ́. Òun nìkan ni Ó lè gbani, tí Ó sì lè parun. Tani ìwọ, tí o ń dá aládúgbò rẹ lẹ́jọ́? 13 Gbọ́ nísisińyí, ìwọ to wípé "òní tàbí ọ̀la ni a ó lọ̀ sí inú ìgbòro yìí, láti lọ lo ọdún kan níbẹ̀, láti ṣòwò àti láti jèrè." 14 Tani ó mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọ́la, ǹjẹ́ ìwọ mọ iye ọjọ́ tí ó kù fun ọ nínú ayé bí? Nítorí pé ìwọ jẹ́ kùrukùru tí ó hàn fún ìgbà kan tí yó sì tún parẹ́. 15 Èyí ni kí o máa sọ, " tí Olúwa bá fẹ́, àwa yo wà láàyè a ó sì ṣè èyí, tàbí a ó ṣe t'ọ̀hún." 16 Ṣùgbọ́n nísísiǹyí, ìwọ ń yangàn ìgbéraga rẹ. Gbogbo àwọn ìwà ìgbéraga yìí ibi ni. 17 Nítorínà, fún gbogbo ẹni tí ó mọ rere láti ṣe ṣùgbọ́n tí kò ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.