Ori´ Kàrún

1 Wá nísísiǹyí, ìwo tí o ní ọrọ̀, sọkún kí o sì kígbe nítorí tí àjálù ń bọ̀ lórí rẹ. 2 Nítorí tí gbogbo ọrọ̀ yín ti díbàjẹ́. Ìdun sí tì jẹ aṣọ rẹ. 3 Wúrà àti fàdákà yín ti dógùń. Dídògún wọn yóò sì jẹ́ ẹ̀rí lòdì sì ọ. Yóò sì jó ẹran ara rẹ bi iná. Ẹ ti fi ọrọ̀ yín pamọ́ di ọjọ́ ìkẹyìn nígbàtí Olúwa yóò se ìdájo yín. 4 Wòó, òógùn àwọn òṣìṣẹ́ ń kéé, o kọ̀ láti fún wọn ní ẹ̀tọ wọn fún iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe lóri oko rẹ, igbe àwọn olùkórè yí sí gòkè tọọ Olúwa ọ̀gá ògo lọ. 5 O ti gbé ìgbe ayé ọrọ̀, o sì ti wu ìwà ìwàjẹ́. O ti jẹ àjẹ sanra ọkàn fún ọjọ́ ìparun. 6 Ìwọ ti dá olódodo lẹ́bi. Ẹni tí ò ta kò ọ́. 7 Nítorínà ẹ ní sùúrù, ẹ̀yin ará, fún bíbọ̀ Olùwa. Wòó, àgbẹ̀ a máa mú súùrú de ìkórè oko. Ó ń farabalẹ̀ ní sùúrù títí tí òjò àkọ́kọ́ àti ìkehìn yó fi rọ̀ sórí oko. 8 Ìwọ, tìká láraàrẹ, ní sùúrù, mú ọkàn rẹ dúró ṣinṣin, ní torítí bíbọ̀ Olùwa súnmọ́. 9 Má ṣe ṣàròyé, ẹ̀yin ará, sí arayín, kí á má baà dá ọ lẹ́jọ́. Wòó, Olùjẹ́jọ́ ń dúró lẹ́nu ọ̀nà. 10 Fi èyí se apẹ̀rẹ, ẹ̀yin ará, nínú ìjìyà àti sùúrù àwọn wòólì, àwọn tó ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa. 11 Wòó, alábùkúnfún ni àwọn tó ní ìfaradà. O ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, bẹ́ẹ̀ni o mọ ète Olúwa, bó ṣe kún fún àánú àti ojú rere. 12 Borí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe búra, yálà pẹ̀lú ọ̀run tàbí ayé, tàbí nípa ìmùlẹ̀kímùlẹ̀. Ṣùgbọ́n jẹ́kí "bẹ́ẹ̀ni" kí ó rẹ́ jẹ́ "bẹ́ẹ̀ni" àti "bẹ́ẹ̀kọ́" jẹ́ "bẹ́ẹ̀kọ́", kí Olúwa má báà da ọ lẹ́jọ́. 13 Ǹjẹ́ ọ̀kan nínu yín ń la ìnira kọjá? Jẹ́ kí ẹni náà gbàdúrà. Ǹjẹ́ ọ̀kan ń dunnú bí? Jẹ́ kí ó kọrin ìyìn. 14 Ǹjẹ́ ọ̀kan nínu yín nṣe àárẹ̀ bí? Jẹ́ kí ó késí àwọn alàgbà ìjọ, kí wọ́n kí ó gbàdúrà fun. Kí wọ́n fi àmì òróró yàn án lórúkọ Olúwa. 15 Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò wo aláàrẹ́ sàn, Olúwa ó sì gbe dìde. Tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run ó foríjìń ín. 16 Nítorí náà, ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ẹnìkọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì gbàdúrà pẹ̀lú ara yín, kí a lè mu yín láradá. Àdúrà olódodo má ń ṣiṣẹ́ agbára. 17 Ènìyàn ẹlẹ́ran-ara ni Èlíjà jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi àwa. Ó gbàdúrà gidigidi kí òjò má rọ̀, òjò kò sì rọ̀ fún ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà. 18 Lẹẹ̀kan si, Èlíjà síì gbàdúrà. Ọ̀run síì rọ òjò, ilẹ̀ síì so èso. 19 Ẹ̀yin ará, tí ẹnikẹ́ni nínu yín bá sáko jìnà sí òtítọ́, ti ẹ́lomíràn sí mu padà, 20 Kí ẹni náà mọ̀pé ẹni tí ó yí ẹlẹ́ṣẹ̀ padà sí ọ̀nà òtítọ́ ti gbàálà lọ́wọ́ ìparun, Olúwa yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sẹ̀ rẹ mọ́lè.