Orí Kẹ̀ta

1 Kìí ṣe ènìyàn púpọ̀ ni ó le di olùkọ́ni, ẹ̀yin ará mi. Àwá mọ̀ pé a ó gbà ìdàjọ́ tí ó tún le síi. 2 Nítorí tí gbogbo wa ń dẹ́sẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Tí ẹnikẹ́ni kò bá dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀, òun ni ẹnití ó ti dàgbà lẹ́kùnrẹ́rẹ́, ó sì le kó gbogbo ara rẹ̀ ní ìjánu. 3 Níbáyìí, bí a ba fi ìjánu sí ẹnu ẹṣin fún wọn láti gbọ́ tiwa, a sì tún le darí gbogbo ara wọn. 4 Kíyèsi àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bó tí lẹ jẹ̀ wípé wọ́n tóbi ìjì líle si tún n darí wọn, ìtọkọ̀ kékeré ni awakọ̀ ojú omi náà fí ń darí rẹ̀ síbi tí ó fẹ́. 5 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n jẹ́ kéré nínú ẹ̀yà ara, síbẹ̀, ó ma n lérí àwọn ohun ńlá . Sì kíyèsi bí iná kékeré ṣe ń jó igbó-ńlá, 6 Ahọ́n jẹ́ iná pẹ̀lú, ayé ẹ̀ṣẹ́ tí ó wa láàrin àwọn ẹ̀yá ara wa. A má a fi àbàwọ́n sí gbogbo ara, yóò sì fi iná sí ipa ìyè. Òun tìkalára rẹ̀ á di jíjó nínú ọ̀run àpààdì. 7 Bí ọmọ ènìyàn ṣé ń darí ẹranko búburú, ẹyẹ , afaayàfàà, àti ẹranko inú òkun. 8 Ṣùgbọ́n fún ahọ́n, kòsí ènìyàn kan tí ó le kápá rẹ̀. Nítorí tí ahọ́n jẹ́ oun búburú ti a kò le kápá rẹ̀, ó kún fún oró tí ń pa ni. 9 Ahọ́n kan náà tí a fí ń yin Olúwa àti Bàbá, òun pẹ̀lú ni a fí ń sépè fún ọmọ ènìyàn, ẹnití Ọlọ́run dá ní àwòrán ara Rẹ̀. 10 Ìbùkún àti èpè ń jáde láti ẹnu kan náà. Ẹ̀yin ará mi, àwọn nǹkan wọ̀nyí kò yẹ bẹ́ẹ̀. 11 Ǹjẹ́ ísùn kan a le sun omi dídùn àti kíkorò bí? 12 Ǹjẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ a máa so ólífì bí, ẹ̀yin ará mi? Tàbí èso àjàrà, lórí ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ni omi iyọ̀ kò le sun omi dídùn. 13 Tani ó gbọ́n tí ó sí nì oye nínu yín ? Jẹ́kí ẹni náà fi ìgbe ayé rere hàn nípasẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ nínú ọgbọ́n. 14 Sùgbọ́n bí o bá ní owú kíkorò àti ìlara nínú ọkàn rẹ, má se yangàn má sì se parọ́ ni ìlòdì sí òtítọ́. 15 Èyí kìí ṣe ọgbọ́n láti òkè wá. Dípò bẹ́ẹ̀, èyí tí ṣe ti ayé ni, ti ara àti ti ẹ̀mí àìmọ́ . 16 Níbití owú àti ìlara gbé wà níbẹ̀ ni dàrúdàpọ̀ àti gbogbo ìwà búburú wà. 17 Ṣùgbọ́n, ṣaájú ohun gbogbo, ọgbọ́n àti òkè wá jẹ́ mímọ́, àlàáfíà, ó ní ìwàpẹ̀lẹ́, ó mọ ẹ̀tọ́, o kúnfún àánú àti síso èso dáradára, aláíṣàarẹ àti òdodo 18 Èso òdodo sì di gbígbìn nínú àlááfìà láàrin àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sètò àlááfìà.