Orí Kejì

1 Ẹ̀yin ará mi, ẹ máṣe ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì, Olúwa ògo, pẹ̀lú ojúsàájú sí àwọn kan. 2 Kí á wípé ẹnìkan bá wọ inú àpéjọ yín tí ó wọ òrùka wúrà àti àwọn aṣọ tí ó dára, tí òtòṣì ọkùnrin náà sì wọlé nínú aṣọ eléèríí. 3 Tí ẹ bá sì wo aláṣọ dáradára nnì, tí ẹ sì wípé, "Jọ̀wọ́, jókòó ní ibi dáradára yìí," tí ẹ sì sọ fún òtòṣì ọkùnrin wipe, "Ìwọ dúró sí ọ̀hún," tàbí "jókòó ní ibi ẹsẹ̀ mi," 4 ẹ̀yin kò a ti ṣe ìdájọ́ láàárín ara yín bí? Ẹ̀yin kò a ti di onídàájọ́ pẹ̀lú èrò ibi bí? 5 Ẹ tẹ́tí gbọ́, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, Ǹjẹ Ọlọ́run kò ti yan àwọn òtòsì nínú ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́ àti láti jẹ́ ajogún ìjọba tí ó ti se ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́? 6 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti tàbùkù aláìní! Kìí há se àwọn ọlọ́rọ̀ ni ń dààmú yín? Ṣé kìí ṣe àwọn sì ní ń fà yín lọ sí ilé ẹjọ́ bí? 7 Ṣé àwọn kọ́ ni ó ń tàbùkù orúkọ rere tí ẹ jẹ́ tirẹ̀ bí? 8 Ṣùgbọ́n tí ẹyin bá pa òfin ti ọba mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, "ẹ̀yin yíò fẹ́ràn ẹnìkejì yín gẹ́gẹ́ bí ara yín", ẹ̀yin se rere. 9 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá se ojúsàájú fún àwọn ènìyàn kan, ẹ̀yin ń dá ẹ̀ṣẹ̀, òfin sì dá yin lẹ́jó gẹ́gé bí àwọn arúfin. 10 Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì kùnà nínú ọ̀kan péré, ó ti jẹ̀bi rírú gbogbo òfin. 11 Nítorí ẹni tí ó wípé, "má se se àgbèrè", Òhun náà ni Ó wípé, "má se pa ènìyàn". Tí ìwọ kò bá se àgbèrè, sùgbọ́n tí o pa ènìyàn, ìwọ ti di arúfin. 12 Fún ìdí èyí, ẹ máa sọ̀rọ̀ kí ẹ sì máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a o dá lẹ́jọ́ nípa òfin òmìnira. 13 Nítorí ìdájọ́ wá láìsí àánú fún àwọn tí kò fi àánú hàn. Àánú ń sògo lórí ìdaájọ́. 14 Rere wo ni ó jẹ́, ẹ̀yin ará mi, tí ẹnìkan bá ní òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní iṣẹ́? Ṣé ìgbàgbọ́ rẹ̀ le gbàálà bí? 15 Bí arákùnrin tàbí arábìrin kan bá wọ asọ tí kò dára àti tí kò sì ní óunjẹ fún ọjọ́ naa. 16 Bí ẹnìkan nínú yin bá wí fún wọn pé, "máa lọ ní àlàáfíà, kí o yó, kí òtútù má sì mú ọ". Bí o kò sì fún wọ́n ní ohun tí wọ́n nílò fún ara wọn, irú isẹ rere wo nì èyí? 17 Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ nínú ara rẹ̀, tí kò ni iṣẹ́, di òkú. 18 Síbẹ̀, ẹlòmíràn lee sọ wípé, "ìwọ ní ìgbàgbọ́ tí èmi sí ní iṣẹ́". Fi ìgbàgbọ́ rẹ tí kò ní àwọn iṣẹ́ hàn, èmi yóó si fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nipa àwọn iṣẹ́ mi. 19 Ìwọ gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run kan ni ó wà; ìwọ se dáradára. Àwọn ẹ̀mí òkùnkùn naa gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ń wá rìrì. 20 Ṣé ìwọ fẹ́ mọ̀, aláìlóye ènìyàn, wípé ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ kò wúlò? Àwọn ẹ̀dà àtijọ́ mìíràn wípé: aláìlóye ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ fẹ́ mò bí ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ ṣe jẹ́ òkú? 21 Ǹ jẹ́ a kò dá Ábráhámù bàbá wa láre nípa isẹ́ nígbàtí ó yọ̀ǹda Ísákì ọmọ rẹ̀ lórí pẹpẹ fún ìrúbọ. 22 Ẹ rí wípé ìgbàgbọ́ bá iṣẹ́ ẹ rẹ̀ ṣisẹ́, àti nípa iṣẹ́, ìgbàgbọ́ rẹ̀ dàgbà tán, 23 Ìwé mímọ́ ṣẹ tí o ṣọ wípé, " Ábráhámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kàá sí òdodo fún un", wọ́n sì ń pe ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 24 Ẹ rí wípé nípa iṣẹ́ ni ènìyàn ń gba ìdáláre, kìí se nípa ìgbàgbọ́ nikan. 25 Bákan náà, ǹ jẹ́ Ráhábù aṣẹ́wó kò ha rí ìdáláre gbà nípa iṣẹ́, nígbàtí ó gba àwọn òjíṣẹ́ ní àlejò tí ó sì sín wọ́n gba ọ̀nà míràn? 26 Gẹ́gẹ́ bí ara tí kò ní ẹ̀mí ṣe jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.