Orí Kaàrún

1 Ní ti òmìnira, Krístì ti sọ wá di òmìnira. Nítorínà, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ má sì ṣe wà ní abẹ́ ìsàkóso àjàgà ti ìkónilérú. 2 Ẹ wòó, èmi, Pọ́ọ̀lù, sọ fún yín pé tí èyin bá fi ara yín sílẹ̀ fún ìkọlà, Krístì, kì yó ní èrè kankan fún yín. 3 Lẹ́ẹ̀kan sí, mo ṣe ìjẹ́rí pé gbogbo ènìyàn tí ó bá fi ara rẹ síiẹ̀ fún íkọlà ó pọn dandan fún-un láti se ìgbọràn sí gbogbo òfin . 4 A gée yín kúrò lára Krístì, ẹ̀yin tí ẹ ó gba ìdáláre nípasè òfin; ẹyin kò ní ìrírí ore-ọ̀fẹ́ mọ́. 5 Nítorí nípasẹ̀ ti Ẹ̀mí, nípa ìgbàgbọ́, ni a ń fi inúdídùn dúró de ìrètí òdodo tí ó dájú. 6 Nínú Jesù Krístì ìkọlà tàbí àìkọlà kò ní ìtumọ̀ kankan, bíkòse ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ ti ìfẹ́. 7 Ẹ ti ń sáré dáradára. Tani ó dá yín dúró láti má se ìgbọràn sí òtítọ́? 8 Ìyínilọ́kàn padà yí kò ti ọ̀dọ ẹni tí ó pè yín wá! 9 Ìwúkàrà kékeré amá a mú gbogbo ìyèfun wú. 10 Mo ní ìgboyà nínú Olúwa wípé ẹ̀yin kì yóò rí irú èyí mọ́. Ẹni tí ó ń dà yín láàmú ni yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹni yóò wù tí ìbáà jẹ́. 11 Ẹ̀yin ará, tí èmi bá sì ń polongo ìkọlà, kílódé tí èmi ṣì n rí ìpọ́nlójú? Fún ìdí èyí òkúta ìdìgbòlù ibi àgbélèbú ti sí kúrò. 12 Ní ti àwọn tí ó ń dàyínláàmù, ó wù mì kí wọ́n tẹ ara wọn lọ́dà! 13 Nítorí ti a pè yín sí òmìnira, ará. Sùgbọ́n ẹ má se lo òmìnira yín gẹ́gẹ́ bíi ànfàní fún ìgbeayé ẹ̀ṣẹ̀; sùgbọ́n, nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹ ran ara yín lọ́wọ́. 14 Nítorí tí gbogbo òfin di mímúṣẹ nínú àṣẹ ẹyọọkan; nínú'' ìwọ gbọ́dọ̀ fẹ́raǹ ẹnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bi ara rẹ.'' 15 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yín bá ń bu ara yín sán ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run. 16 Ṣùgbọ́n èmi wípé, ẹ rìn nípa tí ẹ̀mí, ẹ̀yin kò sì ní ṣe ìfẹ́ inú ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ 17 Nítorí ìfẹ́ ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí tí ẹ̀mí àti ẹ̀mí sí ti ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí tí àwọn méjéèjì wà ní ìjàkadì pèlú ara wọn, kí ẹ̀yin kí ó má baà ṣe àwọn ohun ti ó ń wù yín láti ṣe. 18 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá wà lábẹ́ ìdarí Ẹ̀mí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin. 19 Ǹ jẹ́ nísisìyí iṣẹ́ ti ara fi ara hàn: bi ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kùfẹ́, 20 ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìṣọ̀tẹ̀, ìjà, ìlara, ìbínú, owú, ìkùnsínú, ìyapa, 21 owú jíjẹ, ìmutí para, ìréde òru, àti ǹkan bí àwọn wọ̀nyí. Mo kìlọ̀ fún yín bí mo ṣe kìlọ̀ fún yin ṣaájú wípé, àwọn tí o ńṣe ǹkan wọ̀nyìí kò ní wọ ìjọba Ọlọ́run. 22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlààfíà, sùúrù àánú, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra ẹni níìjánu; òfin kan kò lòdì sí irú ǹkan wọ̀nyíí. 24 Àwọn tí ó jẹ́ ti Jésù Krístì ti kan ara ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú agbára àti ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀. 25 Tí a bá ń gbé nípa ti ẹ̀mí, ẹ jẹ́ ká máa rìn nípa ti ẹ̀mí náà. 26 Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbéraga, nípa mímú ara wa bínú, ṣíṣe ìlara ara wa.