Orí Kẹfà

1 Ará tí ẹ bá mú enìkan nínú àwọn ìrékọjá kan, kí ẹ̀yin tí ń ṣe ẹni ti ẹ̀mí kó ṣe ìmúpadàbọ̀sípò rẹ̀ nínú ẹ̀mí ìwàpẹ̀lẹ́. Ẹ máa ṣe àníyàn ara yín, kí ẹ má baà fa ara yín sínú ìdánwò. 2 Ẹ ma ru ẹrù ara yín, nípasẹ̀ èyí kí òfin Krístì di mímúṣẹ. 3 Nítorí tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òún ṣe pàtàkì nígbàtí kò já mọ́ nkankan, ó tan ara rẹ̀ jẹ. 4 Kí oníkálukú yẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ wò, èrèdí fún láti fọ́n-nu yóò sì wà nínú ara rẹ̀ nìkan láìsí nínú ẹlòmíràn. 5 Nítorí oníkálukú ni yíò gbé ẹrù ara rẹ̀. 6 Ẹ ni tí a kọ́ ní ọ̀rọ̀ náà gbọ́dọ̀ pín ohun rere gbogbo pèlú ẹni tí ó kọ́ọ. 7 Má ṣe jẹ́ kí á tàn yín jẹ, a kòleè gan Ọlórun, nítorí ohun tí ènìyàn bá gbìn ni yóò ká. 8 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fúrúgbìn sí inú ìwà ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nínú ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ náà ni yíò kó èrè ìparun. Ẹni tí ó bá fúrúgbìn sínú ti Èmí, ní inú Êmí ni yíò kórè ìyé ayérayé láti ọ̀dọ Ẹmí wá. 9 Ẹmá ṣe jẹ́ kí á sàárẹ̀ nínú ṣíṣe ohun rere, nítorí àkókó tí ó tọ́ ni a o kórè rẹ̀, tí a kò bá rẹ̀wẹ̀sì. 10 Bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwa ṣe ní àǹfàní, ẹjẹ́ ká máa ṣe rere sí gbogbo ènìyàn, pàápàá jùiọ àwọn tí ó jẹ́ ará ní ilé ìgbàgbọ́. 11 Ẹ wo ìwé ńlá tí mo kọ sí yiń pẹ̀lú ọwọ́ mi. 12 Àwọn tí ó fẹ́ láti tẹ́ yín lọ́rùn nínú ara wọ́n gbìnyànjú kí a bà le kọ yin ní ilà. Wọ́n se èyí láti má jẹ́ kí wọ́n jìyà fún àgbélèbú Krístì. 13 Nítorí kìí ṣe pé àwọn tí o kọlà tìkàálarà ń pa ófin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ kí á kọ yín ní ilà kí wọn ba lè máa ṣògo nínú ara yín. 14 Sùgbọ́n kí èmi ma ṣe fọ́n-nu, bíkòṣe nínú àgbélèbú ti Jésù Krístì Olúwa wa nìkan, nípasẹ̀ èyí tí ayé ti di kíkaǹ mọ́ igi fún mi, àti èmi sí ayé. 15 Nítorípé ìkọlà kò já mọ́ ǹkankan bẹ́ẹ̀ ni àìkọlà náà. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe kókó ni dídi ẹ̀dá titun. 16 Sí gbogbo àwọn ti ó ń gbé nípaṣẹ̀ ìlànà yìí, àláfíà àti àánu kí ó wà lórí wọn, àní lórí ísrélì ti Ọlọ́run. 17 Láti ìsísìnyí lọ kí ẹnikẹ́ni máṣe yomílẹ́nu, nítorípé èmí ru àpá Jésù ní ara mi. 18 Ore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín, ará. Àmín.