Orí Kèta

1 Ẹyín òmùgọ̀ ará Galátía! Ta lò fi èdì dì yín? Lójú u yín ni a se fi Jésù Kristì hàn gedegbe bíi ẹni tí a kàn mo àgbélèbú. 2 Ẹ̀yi nìkan ni mo fẹ́ kọ́ lára yín: Ǹjẹ́ ẹ̀yin gba Ẹ̀mí Mimó nípa iṣẹ́ òfin tábì nípa oun tì ẹ gbọ́? 3 Sé báyǐ ni ẹ se gọ̀ tó? Nìgbátì ẹ bẹ̀rẹ̀ nípa Ẹ̀mí Mimó, ǹjẹ́ ẹ̀yín o parí nínú ará? 4 Ǹjẹ́ ẹyín ti jìyà oun pupọ̀ fún asán- bí ó ti lè se fún asán bi? 5 Ǹjẹ́ ẹnití ó fi Ẹ̀mí fún yín tí ó si ń ṣiṣẹ́ ìyanu láarín yín ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ òfin tàbí nípa ìgbọràn ìgbàgbọ́? 6 Gẹ́gẹ́ bí Ábráhámù "ti gba Ọlọ́run gbọ tí a sì kàá sí fun bí òdodo," 7 ní ọ̀nọ̀ kannáà, ẹ jẹ́kí ó yé e yín, pé àwọn tí wọ́n ní irú ìgbàgbọ́ báyǐ ni ọmọ Ábráhámù. 8 Gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti rí i tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yíò dá àwọn Kèfèrí láre nípa ìgbàgbọ́, wàású ìhìnrere sájú fún Ábráhámù wípé, "Nínú rẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yí ó di alábùkún fún. 9 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀, ni gbogbo onígbàgbọ́ yíò di alábùkúnfún pẹ̀lú Ábráhámù, ẹni ìgbàgbọ́. 10 Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lẹ́ isẹ́ ti òfin ni ó wà lábẹ́ ègún; a sì ti kọ́ pé, "Ìfibu ni ẹnikẹ́ni tí kò pa ohun gbogbo ti a kọ sí inú ìwé òfin mọ́, tí kò sì se é. 11 Ò sì ti di mí mọ̀ pé a ko dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípá òfin, nítorí àwọn olódodo yíò gbe nípa ìgbàgbọ́. 12 Ṣùgbọ́n òfin kíì ṣe ti ìgbàgbọ́, bíkòse pé, Ẹnití ó ń se iṣẹ́ òfin gbọ́dọ̀ gbé nípasẹ̀ rẹ̀. 13 Krístì rà wá padà lọ́wọ́ ègún òfin nípa dídí ègún fún wa - nítorí tì a tí kọ pé, Ìfíbu ni fún ẹni tí a fi kọ́ sóri igi 14 ki ìbùkún Abrahamù jẹ́ tí awọ́n keferi nínu Kristi Jesu, atí kí a le gba ilé Ẹ̀mí Mimọ́ nípa ìgbàgbọ́. 15 Ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́kí n sọ́rọ́ bí ènìyàn. Nínú májẹ̀mú ènìyàn, kò sí ẹni tí ó le sọ́ di asán tabí fi kún n nígbàtí a bá tí fi ìdí rẹ̀ mú lẹ̀. 16 A sì sọ àwọn ìlérí wọ̀nyí fún Àbràhàmú àti irú ọmọ rẹ̀. Kò wípé, "fún àwọọn irú ọmọ" bí ẹnipé ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbón sí ọ̀kan soso, "àti fún irú ọmọ rẹ," èyítí ṣe Krístì. 17 Ìtumò ọ̀rọ̀ mi nì yí: Òfin, tí ó dé lẹ́yín ọgbọ̀n-le-nírinwó ọdún, kò pá májẹ̀mú tí Ọlọ́run tí dá tẹlẹ̀ sí apá kan. 18 Nítorí tí ijogún bá wá nípa ti òfin, kò wá nípa ti ìlérí mọ́. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fifún Ábráhámù nípa ìlérí. 19 Ǹjẹ́ kí ni ìdí òfin? A fi kún n nítorí ìrékọjá, títí irú ọmọ Ábráhámù yíò fi wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí a ti se ìlérí. A si ti ipasẹ àwọn ángẹ́lì ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá. 20 Ǹjẹ́ alarina ju ẹnìkan lọ, ṣùgbọ́n ọ̀kan ní Ọlọ́run. 21 Ǹjẹ́ òfin ta ko ìlérí Ọlọ́run bí? K'á má rí i: Nítorí tí a bá tí fún wa ní òfin tí o le mú ìyè wa, nígbànáà ní òdodo yí o tí ípasẹ̀ òfin wá. 22 Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ tí a fí gbogbo ǹkan sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí láti mú ìlérí àti gbà wá là nípasè ìgbàgbọ́ ṣe nínu àwọn tó gbàgbọ́. 23 Sùgbọ́n ki ìgbàgbọ́ to de, a dì wá ní ígbékún lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ títí dé ìgbàgbọ́ tí n bọ̀ wa fihàn. 24 Nípasẹ̀ náà ni òfin fi di alágbàtọ́ wa títí Krístì fi dé, kí á lè dáwa láre nípa ìgbàgbọ́. 25 Ṣùgbọ́n nísisìnyí tí ìgbàgbọ́ tí de, a kò sí lábẹ́ alágbàtọ́ kankan. 26 Nítorí ọmọ Ọlọ́run ni wá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínu Krístì Jésù 27 Nítorí iye ẹ̀yin tí a ti baptísì sínú u Krístì, tí gba Krístì. 28 Kò sí Júù tàbí Éllénì, kò sí ẹrú tàbí òmìnira, kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, nítorí ọ̀kan lẹ jẹ nínú u Krístì Jésù. 29 Ti ẹ̀yin bá jẹ́ ti Krístì, ẹ jẹ́ irú ọmọ Ábráhámù àti ajogún gẹ́gẹ́ bí ìlérí.