Orí Kẹẹ̀ta

1 Bí ó bá jẹ́ wípé Ọlọ́run ti jí yín pẹ̀lú Krístì, ẹ sàfẹẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbití Krístì gbé jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 2 Ẹ ronú nípa àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, kìí ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. 3 Nítorítí ẹ ti kú, a sì ti fi ẹ̀mí yín pamọ́ pẹ̀lú Krístì nínú Ọlọ́run. 4 Nígbàtí Krístì bá fi ara hàn, ẹnití Í ṣe ìyè yín, nígbànáà ni ẹ̀yin náà yó farahàn pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ògo. 5 Nísinsìnyí, ẹ pa àwọn ẹ̀yà ara yín tí ó wà ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìgbónára, ìfẹ́kùfẹẹ́ àti wọ̀bìà tí ṣe ìbọ̀rìṣà. 6 Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀ sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. 7 Nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ẹ̀yin náà ti rìn nígbàkan rí ní àkókò tí ẹ gbé nínú wọn. 8 Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ gbudọ̀ pa àwọn nǹkan wọ̀nyí tì - ìrunú, ìbínú, èròǹgbà ibi, èébú, àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ẹnu yín. 9 Ẹ má ṣe parọ́ fún ara yín, nígbàtí ó jẹ́ wípé ẹ̀yín ti bọ́ ọkùnrin àtijọ́ nnì sílẹ̀ àti àwọn ìṣe rẹ̀, 10 ẹ̀yín sì ti gbé ọkùnrin titun nnì wọ̀, ẹnití à ń ṣe ní ọ̀tun ní ìmọ̀ gẹ́gẹ́bí àwòrán enití ó dáa. 11 Ní ibíyìí ni kò ti sí'pé eléyìí ni Gíríkì tàbí Júù, ẹnití ó kọlà àti ẹnití kò kọlà, aláìgbédè, ara Skítìa, ẹrú, olómìnira, ṣùgbọ́n Krístì ni ohun gbogbo, Ó sì wà nínú ohun gbogbo. 12 Nítorínà, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí Ọlọ́run ti yàn, ẹni mímọ́ àti àyànfẹ́, ẹ gbé ọkàn àánú wọ̀, ìṣore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13 Kí ẹ máa faradàá fún ara yín. Ẹ máa yọ́nú si ara yín. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀sùn sí ẹlòmíràn, ẹ máa dáríjìn ní ọ̀nà kannáà tí Olúwa ti dáríjìn yìn-ín. 14 Borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ ní ìfẹ́, eléyìí tí ṣe àmùrè ìwà pípé. 15 Ẹ jẹ́ kí àlááfíà Krístì jọba ní ọkàn yín. Nítorí ti àlááfíà yìí ni a ṣe pè yín sínú ara kan. Àti pé ẹ máa kún fún ìdúpẹ́. 16 Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Krístì máa gbé inú yín lọ́pọ̀lọpọ̀. Ẹ máa kọ́ni pẹ̀lú ọgbọ́n gbogbo bẹ́èni kí ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú pẹ̀lú àwọn Sáàmù àti àwọn orin ìyìn àti àwọn orin ẹ̀mí. Ẹ kọrin pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọpẹ́ nínú ọkàn yín sí Ọlọ́run. 17 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, nínú ọ̀rọ̀ sísọ tàbí nínú ìṣe, ẹ ṣe gbogbo rẹ̀ ní orúkọ Jésù Olúwa. Kí ẹ sì ma fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ Rẹ̀. 18 Ẹ̀yin ìyàwó, ẹ tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ nínú Olúwa. 19 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn ìyàwó yín, kí ẹ má sì ṣe korò sí wọn. 20 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo, nítorí èyí ni ó dára nínú Olúwa. 21 Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọ́n má baà rẹ̀wẹ̀sì. 22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn olówó yín níti ara lẹ́nu nínú ohun gbógbó, kìí ṣe pẹ̀lú ojú-aye, bí awọn tí ń fẹ́ láti tẹ́ àwọn ènìyàn l'ọ́rùn, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tí ó tọ́. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run. 23 Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣé, ẹ ṣiṣẹ́ láti inú ọkàn gẹ́gẹ́ bíi fún Olúwa tí kìí sìí ṣe fún àwọn ènìyàn. 24 Ẹ̀yín mọ pé ẹ ó gba èrè ogún ìbí láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Krístì Olúwa ni ẹ̀yin ń sìn. 25 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo yóò gba èrè fún àìṣòdodo tí ó ṣe, àti pé kò sí ojúṣàájú.