Orí Kejì

1 Nítorí èmí fẹ́ kí ẹ̀yin mọ ìjàkadì tí mo ní fún yín, fún àwọn tó wà ní Laodíkìa, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọn kò tíì rí mi lójúkojú. 2 Mo tiraka kí á ba lè mú wọn lọ́kàn le nípa mímú wọn parapọ̀ nínú ìfẹ́ àti sínú gbogbo ọrọ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye Rẹ̀ tó dájú, sínú ìmọ̀ àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, àní Krístì. 3 Nínú ẹnití a fi gbobgo ìsúra ọgbọn àti ìmọ̀ pamọ́ sí. 4 Mo sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. 5 Bótilẹ̀jẹ́'pé èmi ko sí pẹ̀lú yín lójúkojú, síbẹ̀, mo wa pẹ̀lú yín nínú ẹ̀mí. Mo yọ̀ láti mọ ètò dáradára yín àti ìdúróṣinṣin yín nínú Krístì. 6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Krístì ní Olúwa, ẹ rìn nínú Rẹ̀. 7 Ẹ fi gbòngbo múlẹ̀ nínú Rẹ̀, kí á gbé yín ró lóríí Rẹ̀, kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, ki ẹ sì pọ̀ si nínú ìdúpẹ́. 8 Ẹ f'iyèsi kí ẹnikẹ́ni má fi ọ̀rọ̀ àròsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tó dá lórí àṣà ènìyàn mú yín ní ìgbèkùn, eléyìí tí ó ní ìdàpọ̀ àwọn ẹ̀mí ìpìlẹ̀ ayé yìí ṣùgbọ́n tí kò bá ìlàna Krístì mu. 9 Nítorí nínú Rẹ̀ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run ń gbé nínú ara. 10 A sì ti sọ yín di kíkún nínú Rẹ̀, ẹnití ó jẹ̀ orí lórí gbogbo ipá àti agbára. 11 Nínú Rẹ̀ ni a sì kọ ẹ̀yin náà n'ílà pẹ̀lú, ìkọlà tí a kò ti ọwọ́ ènìyàn ṣe níti mímú ẹran ara kúrò, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìkọlà Krístì. 12 A ti sin yín pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìrìbọmi, àti nínú Rẹ̀ ni a jí yín dìde nípa ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, enití ó jí Krístì dìde nínú òkú. 13 Nígbàtí ẹ̀yín jẹ́ òkú nínú àwon ẹ̀ṣẹ yín àti nínú àìkọlà ẹran ara yín, Ó sọ yín di ààyé pẹ̀lú Rẹ̀ bẹ́ẹ̀ni ó dárí àwọn ẹ̀ṣẹ yín jìnyín. 14 Ó fagilé àkọsílẹ̀ gbogbo gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dúró lòdì sí wa pẹ̀lú àwọn ìlàna rẹ̀. Ó mú kúrò nípa kíkà-án mọ́ àgbélèbú. 15 Ó gba ipá lọ́wọ́ àwọn agbára àti aláṣẹ, bẹ́ẹ̀ni ó dójútì wón ní gbangba, bí ó ti ṣe ṣẹ́gun wọ́n lórí àgbélèbú. 16 Nítorínà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dá yín l'ẹ́jọ́ lórí àwọn ohun tí ẹ̀ ń jẹ tàbí àwọn ohun tí ẹ̀ ń mu, tàbí ní ti ọjọ́ ayẹyẹ kan tàbí ti oṣù tuntun, tàbí ní ti àwọn ọjọ́ ìsinmi. 17 Àwọn wọ̀nyí ni àwòjíji àwọn ohun tí ó ń bọ̀'wá, ṣùgbọ́n Krístì ni ara. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ń fẹ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àbí ìsìn àwọn ángẹ́lì ṣe ìdájọ́ yín kúrò nínú ère yín. Irúfẹ́ ènìyàn báyìí a máa wọnú àwọn ohun tí ó rí àti pé a sì máa gbéraga nípa èro ẹran ara rẹ̀. 19 Òun kò sì di orí nnì mú ṣinṣin. Láti ara orí ni gbogbo ẹ̀ya ara pẹ̀lú àwọn oríkèríkèé atí iṣan ti ń gba ìpèsè tí wọ́n sì so papọọ̀; ó ń dàgbà pẹ̀lú ìdàgbà tí Ọlọ́run fi fún. 20 Bí ẹ̀yín bá ti kú pẹ̀lú Krístì sí àwọn ẹ̀mí ìpìlẹ̀ ayé, kílóde tí ẹ̀yin ń gbé bí ẹnití a fi ipá mú láti gbọ́ ti ayé: 21 "Máṣe gbámú, tàbí tọ́wò, tàbí fọwọ́kàn"? 22 Gbogbo ìwọ̀nyí ni yó parun pẹ̀lú ìlo wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ àwọn ènìyàn. 23 Àwọn ìlànà yìí ni ọgbọ́n àdábọwọ́ ẹ̀sìn àti ìrẹ̀lẹ̀ àti ìpọ́nra-ẹni-lójú. Ṣùgbọ́n wọn kò ní èrè láti dín ìfẹ́kùfẹ́ ara kù.