Orí Kẹẹ̀rin

1 Ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ fi ohun tí ó tọ́ fún àwọn ẹrú yín, kí ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin náà ní ọ̀gá kan ní ọ̀run. 2 Ẹ tẹ̀síwájú ní dídúróṣinṣin nínú àdúrà gbígbà. Ẹ wà ní ìtají nínú ìdúpé. 3 Ẹ parapọ̀ gbàdúrà fún àwa náà pèlú, pé kí Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀rọ̀ fún wa, kí á le sọ àṣírí òtítọ́ ti Krístì. Nítorí èyí ni a fi ẹ̀wọ̀n dè mí. 4 Ẹ gbàdúrà kí n le jẹ́ kí ó já geere, gẹ́gẹ́ bí ó tí yẹ kí n sọọ́ jáde. 5 Ẹ máa fi ọgbọ́n bá àwọn tí ó wà l'óde rin, àti pé kí ẹ máa ra ìgbà padà. 6 Ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ yín dàpọ̀ pèlú oore-ọ̀fẹ́ nígbàgbogbo. Ẹ jẹ́ kí á fi iyọ̀ dùn wọ̀n-án, kí èyin kí ó lè mọ̀ bí ó ti yẹ kí ẹ fún olúkúlùkù ènìyàn ní èsì. 7 Lórí àwọn nǹkan tí ó nííṣe pẹ̀lú mi, Tíkíkù yóò sọ wọ́n di mimọ̀ fún yín. Arákùnrin olùfẹ́ ni ó jẹ́, olótìtọ́ọ́ ìránṣẹ́ àti akẹgbẹ́ nínú Olúwa. 8 Nítorí ìdí yìí ni mo ṣe rán-an sí yín, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ ohun tí ó ń sẹlẹ̀ sí wa, àti pé kí òun ba le mú yín lọ́kàn le. 9 Mo rán-an pẹ̀lú Onésímù, arákùrin olùfẹ́ àti olótìtọ́ọ́, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára yín. Wọn yóò sọ ohun gbogbo tí ó ń sẹlẹ̀ níbìyí fún yín. 10 Árístákù, òùndè ẹlẹgbẹ́ mí ń kí yín, bákannáà sì ní Máàkù, ọmọ arábìnrin Bánábà (nípasẹ̀ ẹnití ẹ̀yin ti gba àṣẹ; nígbàtí ó bá dé ọ̀dọ yín, kí ẹ tẹ́'wọ́ gbàá), 11 àti pẹ̀lu Jésù tí a ń pè ní Jústù. Àwọn wọ̀nyí nìkan tí ó jẹ́ oníkọlà ni ó ṣe alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi fún ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ti jẹ́ ìtùnú fún mi. 12 Ẹ́pafra ń kí yín. Ọ̀kan lára yín ní Í ṣe àti ìránṣẹ́ Krístì Jésù. Gbogbo ìgbà ni ó ń sakitiyan lórí yín nínú àdúrà kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé àti nínú ìdánilójú ìfẹ́ Ọlọ́run. 13 Nítorí mo j'ẹ́rìí rẹ̀, pé ó ń ṣiṣẹ́ takuntakun fún yín, fún àwọn tí ó wà ní Laodíkéà àti àwọn tó wà ní Híerápólísí. 14 Lúúkù olùfẹ́ oníṣègùn ati Dẹ́mà ń kí yín. 15 Ẹ kí àwọn ará tó wà ní Laodíkéà, àti Nímfà, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀. 16 Nígbàtí a bá ti ka lẹ́tà yìí ní ààrin yín, ẹ jẹ́ kí ó di kíkà pẹ̀lú nínú ìjọ àwọn ará Laodíkéà, ẹ sì ri wípé a tún ka lẹ́tà tó wá láti Laodíkéà. 17 Ẹ sọ fún Ákípù, "Mójútó iṣẹ́ ìyìnrere tí o ti gbà nínú Olúwa, kí ìwọ kí ó lè muṣẹ." 18 Ìkínni yìí wá láti ọwọ́ èmi tìkálárami — Pọ́ọ̀lù. Ẹ rántí ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.