Orí Kẹẹ̀sán

1 Bí Jésù tí ń rékojá lọ, Ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí. 2 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wípé, "Olùkọ́ni, tani ó ṣẹ̀, ọkùnrin yí ni tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?" 3 Jésù dáhùn wípé, "kíìṣe nítorí ọkùnrin yí dẹ́ṣẹ̀ àbí àwọn òbí i rẹ̀, sùgbọ́n kí á le fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn nínú rẹ̀. 4 A gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi nígbà tííṣe ọ̀sán. Alẹ́ nbọ̀ wá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò ní leè siṣẹ́ mọ́. 5 Nígbà tí mo wà láyé, Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. 6 Nígbà tí Jésù ti sọ àwọn nkàn wọ̀nyí, ó tutọ́ sílẹ̀, ó fi itọ́ se amọ̀, ó sì rẹ́ẹ mọ́ ọ lójú. 7 Ó sọ fún un wípé, "Lọ, wẹ̀ nínú adágún Sílóámù (Tí a túmọ̀sí: rán-lọ)." Báyìí ni ọkùnrin náà sì lọ, ó wẹ̀, ó padà wá ó ríran. 8 Nígbà náà ni àwọn aládùúgbò ọkùnrin náà àti àwọn tí ó ríi tẹ́lẹ̀ pé ó n ṣagbe tẹ́lẹ̀ ń wípé, kì í ṣe ọkùnrin tí ó má ń jókòó ṣagbe nì yí? 9 Àwọn kan wípé "óun ni." Àwọn ẹlòmíràn wípé, "Bẹ́ẹ̀kọ́, ó jọ ọ́ ni." Ṣùgbọ́n òun wípé, "èmi ni." 10 Wọ́n wí fún unpé, "Báwo ni ojú rẹ ṣẹ là? 11 Ó sì dáhùn wí pé, "Ọkùnrin náà tí à n pè ní Jésù ṣe amọ̀ ó fi rẹ́ mi lójú ó wí fún mi pé, 'Lọ sí Sílóámù kí o sì wẹ́.' Èmí sì lọ mo sì wẹ̀, mo sì ríran. 12 Wọ́n sì wí fun pé, "Òun dà?" Ó dáhùn pé, "Èmi kò mọ̀." 13 Wọ́n mú ọkùnrin náà tí ó fọ́jú tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn Farisí. 14 Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi nígbàtí Jésù ṣe amọ̀ náà tí ó sì là á lójú. 15 Nígbà náà ni àwọn Farisí tún bi í léèrè pé báwo ni ó ṣe ríran. Ó sì wí fuń wọn pé, "Ó fi amọ̀ sí mi lójú, mo fọ̀ ọ́, èmi sì ti ríran nísisìyí. 16 Àwọn kan nínú àwọn Farisí náà wípé, "Ọkùnrin yí kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nítorí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Àwọn míràn wípé, "Báwo ni ọkuǹrin ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣe le ṣe irú iṣẹ́ àmì yí?" Bẹ́ẹ̀ni ìyapa wà láàrin wọn. 17 Nítorí náà wọn tún bi ọkùnrin tí a là lójú náà léèré pé, "Kínnin ìwọ yóò sọ nípa rẹ̀, nítorí ó là ọ́ lójú?" Òun wípé "Wòólì ni." 18 Bákan náà àwọn Júù kò gbà á gbọ́ pé òun ni afọ́jú tí ó ti ríran títì wọn fi pe àwọn òbí ọkuǹrin tí a là lójú. 19 Wọ́n bèèrè lọ́wọ́ àwọn òbí náà, "Ṣé ọmọ yín tí ẹ wípé ẹ bí ní afọ́jú nì yí? Báwo ni ó ṣe ríran nísisìyí?" 20 Nítorínà, àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wípé, "Àwa mọ̀ wípé ọmọ wa ni èyí tí a bí ní afọ́jú. 21 Sùgbọ́n bí ó ti ṣe ríran nísisìyí àwa kò mọ̀, tàbí ẹni tí ó là á lójú, àwa kó mọ́. Ẹ bií léèrè, àgbàlagbà ni, òun leè sọ fún ara rẹ̀." 22 Àwọn òbí rẹ̀ ṣọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí wọn bẹ̀rù àwọn Júù. Àti wípè àwọn Júù ti gbìmọ̀ pọ̀ pé bí ẹnìkan bá le jẹ́wọ́ rẹ ẹ̀ pé òun ni Kírísítì náà, a ó jù ú síta kúrò nínú Sínágọ́gù náà. 23 Nítorí èyí ni àwọn òbí rẹ̀ ṣe sọ pé "Àgbàlagbà ni, ẹ bi í." 24 Fún ìgbà kejì wọ́n pe ọkùnrin náà tí ó ti fọ́jú rí wọ́n wí fun pé, "Fi ògo fún Ọlọ́run. A mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yí." 25 Nígbà náà ni ọkùnrin yí dáhùn wípé, "Èmi kò mọ̀ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni. Ohun kan ni mo mọ̀: Mo fọ́jú tẹ́lẹ̀, sùgbọ́n báyìí mo ríran." 26 Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, "Kí ló ṣe sí ọ? Báwo ni ó ṣe la ojú rẹ?" 27 Ó dá wọn lóhùn wípé, èmí ti sọ fún un yín tẹ́lè, ẹ̀yin kò fẹ́ gbọ́ ! Kíló dé tí ẹ̀yin tún fẹ́ tun gbọ́? Ẹ̀yin kò ṣáà fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Njẹ́ ẹ fẹ́? 28 Wọn tàbùkù rẹ̀ wọn wípé, "Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀ sùgbọ́n ọmọ ẹyìn Móóṣè ni àwa jẹ́. 29 Àwá mọ̀ pé Ọlọ́run bá Móóṣè sọ̀rọ̀, sùgbọ́n àwa kò mọ ibi tí eléyìí ti wá. 28 Wọn tàbùkù rẹ̀ wọn wípé, "Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìnin rẹ̀ sùgbọ́n ọmọ ẹyìn Móóṣè ni àwa jẹ́. 29 Àwá mọ̀ pé Ọlọ́run bá Móóṣè sọ̀rọ̀, sùgbọ́n àwa kò mọ ibi tí eléyìí ti wá. 30 Ọkùnrin náà sì dáhùn ó wí fún wọn pé "Ohun ìyanu ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó ti wá, àti síbẹ̀ òun là mí lójú 31 Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kìí gbọ́ ti ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùfọkànsìn àti ẹni tí ó n ṣe ìfẹ́ rẹ̀, òun a má à gbọ́ tirẹ̀. 32 Láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀ a ò tíì gbọ rí pé ẹnìkan la ojú ẹni tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá. 33 Bí ọkùnrin yìí ´ kò bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá kò le ṣe ohùǹ kan. 34 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé "Nínú ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá ni a bí ọ, ìwọ́ a ń kọ́ wa bí? Nígbà náà ni wọ́n tì í síta. 35 Jésù gbọ́ pé wọn ti ti ọkuǹrin yí jáde kúrò nínú Sínágọ́gù. Ó rí i ó sì wípé "Ṣé ìwọ gbàgbọ́ nínú ọmọ ènìyàn bí"? 36 Òun si dáhùn wípé, taani íṣe, Olúwa, kí èmi le gbàgbọ́ nínúu rẹ̀?" 37 Jésù wí fún un, ìwọ ti ríi àti pé òun ni ẹni tí ó n bá ọ sọ̀rọ yí." 38 Ọkùnrin náà wípé, "Olúwa, mo gbàgbọ́" ó sì wólẹ̀ sín. 39 Jésù wípé "Nítorí ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí kí àwọn tí kò ríran le è ríran àti àwọn tí ó ríran le è di afọ́jú." 40 Nínú àwọn Farisí tí ó wà pẹ̀lúu rẹ̀ gbọ́ ǹ kan wọ̀nyí wọ́n sì bií wípé àwa pẹ̀lú fọ́jú bí?" 41 Jésùsọ fún wọn pé, "Bí ẹ̀yin bá jẹ́ afọ́jú, ẹ̀yin kò bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀, sùgbọ́n nísisìyí ẹ̀yin wípé 'Àwa ríran,' nítorí náà ẹ̀ṣẹ̀ ẹ yín wà síbẹ̀.