Orí Ìkẹ́jọ

1 Jesu sì lọ sí orí òkè Ólífì. 2 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ópadà sí inú tẹ́mpìlì, ìjọ àwọn ènìyàn siwa pẹ̀lú; Ó si joko, Ó nkọ́ wọn. 3 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí mú obìnrin kan tí a mú nínú pansagà wá sọ́dọ̀ rè. Wọ́n sì ju obìnrin na sí àrin wọn. 4 Nígbàna ni wọ́n wí fun n pe, "Olùkóni, àwá mú obìnrin yi nínú panságà. 5 Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàse pé kí á sọ irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ ni òkúta pa, ǹjẹ́ kí ni ìwọ́ wí si? 6 Wọ́n sọ èyí kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kán ọ̀rọ rẹ̀, sùgbón Jesu tẹríba, ósi nfi ìka rẹ̀ kọ oun kan sílẹ̀. 7 Nígbàtí wón bi léèrè léraléra, ódìde ósì wí fún wọn pé, "Ẹnìkan nínú yin tí kò dẹ́sẹ̀, jẹ́ kí o kọ́kọ́ sọ ní òkúta." 8 Ósì tún bẹ̀rẹ̀ ó n kọwe lórí ilẹ̀. 9 Nígbàtí wọ́n gbọ́ èyí, wọ́n lọ ní ọ̀kọ̀ọkan, lati orí enití ó dàgbà jù. Ó sì ku Jesu àti obìnrin ti ajù sí arin náà. 10 Jesu dìde ó sì wí fun pe, "Arábìnrin, àwọn olùfisùn rẹ dà? kò a sí ẹnìkan tí ódá ọ lẹ́ bi? 11 Ó wípé, "kòsí ẹnìkan, Oluwa." Jesu dáhùn, bẹẹni, "Èmi náà kò da ọ lẹ́bi. Ma lọ, má dẹsẹ mọ́." 12 Ó sì tún wí fún wọn pé, "Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé; ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yio rìn nínú òkùnkùn, sùgbọ́n yio ni ìmọ́lẹ̀ ayé." 13 Àwọn Farisí sì wí fun pe, "Oun jẹ́ri sí ara rẹ, ẹ̀rí rẹ kìí se òtítọ́." 14 Jesu dáhùn Ó sì wí fún wọn pé, "Bí mo ti lẹ̀ njẹri fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mí íse. Mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò nlọ, sùgbọ́n, ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá tàbí ibi tí mò ńlọ. 15 Ẹ̀yin nse ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò se ìdájọ́ ẹnikéni 16 Sùgbon bí mo ti lẹ̀ se ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi nítorí èmi kò dáwà, mo wà pẹ̀lú bàbá tí ó rán mi. 17 Bẹ̀ẹ́ni, ówà nínú òfin yin pẹ̀lú pé, ẹ̀rí ní ẹnu ènìyàn méjì, òtító ni. 18 Èmi ni ẹni tí ó njẹri sí ara mi, baba tí ó rán mi pẹ̀lú jẹri nípa mí." 19 Wọ́n sì bìí pé, "Níbo ni bàbá rẹ wa?" Jesu dáhùn wípé, "Ẹ̀yin kò mọ̀ mí tàbí mọ baba mi, bí ẹ̀yin bá mòmí ẹyin ì bámọ baba mi pẹ̀lu." 20 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Ó sọ níbi ìsura bí ó tin kọ́ni nínú tẹmpili, ko si si ẹnikeni ti ofi ipá mu nítorí àkókò rẹ kò tìí to. 21 Nítorínâ, ótún wí fún wọn pé, "Èmi nlọ, ẹ̀yin ó wa mi, ẹ ó sì kú sinu ẹ̀sẹ̀ yin. Ibi tí èmí nlọ, ẹ̀yin kì yí o le wa." 22 Àwọn Ju wípé, "Yío ha pa ararẹ̀ bí? Nítorí tí ówí pé, 'Ibi tí èmí nlọ ẹ̀yin kole wa'?" 23 Jesu wí fún wọn pé, "Ẹ̀yín ti ìsàlẹ̀ wá, èmí sì ti òkè wá. Ẹ̀yín jẹ́ ti ayè yi, emi kii sise ti ayé yi. 24 Nítorínà ni mo se wí fun yin pe, ẹ̀yin ó kú ninu ẹ̀sẹ̀ yin. Àfi bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́ pé Èmi ni, ẹ̀yin ó kú sínú ẹ̀sẹ̀ yin." 25 Nítorínâ, wọ́n bii pe, "Tani ìwọ íse?" Jesu si wí fún wọn pé, "Oun tí mo ti wí fún yin tẹ́lẹ̀ lati àtètèkọ́ se. 26 Mo ní oun topọ lati wí àti lati dájọ́ nípa yin. Sùgbọ́n olotitọ ni ẹniti órán mi; àwọn oun tí mo gbọ́ láti ọ̀dọ rẹ̀ ni mo n sọ fun aráyé." 27 Wọn kó mọ̀ pé oun sọ fún wọn nípa Baba. 28 Jesu wípé, "Nígbàtí ẹbá gbé ọmọ ènìyàn sókè, nigba naa ni ẹ ó mọ̀ pé Èmi ni, àti pé kòsí ohunkóhun tí mo se fún ara mi. Bí Baba ti fi kọ́ mi, ni mo sọ nkan wọ̀nyí. 29 Ẹnití ó rán mi wà pẹ̀lú mi, kòsì fi mí sílẹ̀, nítorí mo n se oun tó dùn mọ nígbà gbogbo". 30 Bi Jesu ti n wi nkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ si gbàgbọ́ nínú rẹ. 31 Jesu sì wí fún àwọn Ju tí o gbàgbọ́ nínú rẹ, "Bí ẹ̀yin bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, nígbà na ni ẹ̀yín jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mì ní tootọ; 32 ẹ̀yin ósì mọ òtítọ́, òtítọ́ yio sì sọ yín di òmìnira." 33 Wọ́n da lóhùn wípé, " Irú ọmọ Abrahamu ni àwá nse, ako si se ẹrú fún ẹnikẹ́ni ri; iwo o ha ti wípé, 'Ẹyin o di òmìnira'?" 34 Jesu dá wọn lóhùn pé, "Lotitọ, lotitọ ni mo wí, ẹni tí ó dẹ́sẹ̀, ẹrú ẹ̀sẹ̀ ni. 35 Ẹrú kìí wà nínú ilé títí lai; sùgbọ́n ọmọ amá wa títí lai. 36 Nítorínà, bí ọmọ bá sọ yín di òmìnira, èyin o di òmìnira ni tootọ. 37 Mo mọ̀ pé irú ọmọ Abrahamu ni ẹyin ise; ẹ n wa lati pamí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò ráyè nínú yin. 38 Mo sọ oun ti mo ti rí pẹ̀lu baba mi, ẹ̀yin pẹlu si ńse oun ti ẹ gbọ lati ọdọ baba yin." 39 Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fun pé, "Abrahamu ni bàba wa." Jesu wí fún wọn pé, "Bi ẹyin bájẹ́ ọmọ Abrahamu, ẹyin ìbá se isẹ́ Abrahamu. 40 Sùgbọ́n ẹ̀yin nwá lati pa mí, okùnrin tí osọ gbogbo otitọ ti mo gbọ́ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun fun yin. Abrahamu kò se èyí 41 Îse baba yin ni ẹyin nse." Wón wí fun pe, "Akò bí wa nípa àgbèrè; àwá ní baba kan: Ọlọrun." 42 Jesu wí fún wọn pé, "Bí Ọlọrun bá jẹ́ baba yín, ẹ̀yin ó fẹ́ràn mi, nítorí mo ti ọ̀dọ baba wa mo sì wà ní ihin yii; nítorí nkò wa fún ara mi, sùgbọ́n ó rán mi. 43 Kíló dé ti ọ̀rọ̀ mi kò fi ye yin? Nítorí pé ẹ̀yin kole gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 44 Ti baba yín ni ẹ̀yin ise, èsù, ẹ̀yín sì fẹ́ se ìfẹ́ baba yin. Apànìyàn ni lati àtètèkọ́se, kòsì dúró nínú òtítọ́ nítorí òtítọ́ kòsí nínú rẹ. Bí óbá sì pa irọ́, o n sọ̀rọ̀ ninu ìwa rẹ̀. nítorí òpùrọ́ ni baba onìrọ́ sì ni pẹ̀lú. 45 Sùgbón, nítorí tí mo sọ òtítọ́, ẹ̀yin ko gba mi gbọ. 46 Èwo nínú yín ni ódá mi lẹ́bi ẹ̀sẹ̀? Bí mo bá sọ òtítọ́, èése ti ẹkò fi gbà mí gbọ́? 47 Ẹni tí ó jẹ́ tí Ọlọrun í gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́; ẹ̀yin ko gbàgbọ́ nítorí ti ẹkì íse ti Ọlọrun." 48 Àwọn Ju dáhùn wọ́n sì wí fun pe, "Àwa kò ha ti wípé ara samaritan ni iwọ àti pé ìwọ́ ní ẹ̀mí èsù?" 49 Jesu dáhùn wípé, Èmi kò ní ẹ̀mí èsù, sùgbón, mo bu ọlá fún baba mi, ẹ̀yin ko si bu ọlá fún mi. 50 Èmi kò wá ògo ti ara mi; ẹnìkan ń wá tí ó si n se ìdájọ. 51 Lotitọ, lotitọ ni mo wí fun yin, bí ẹnikẹ́ni bá pa òrọ̀ mi mó, kì yio rí ikú." 52 Àwon Ju si wi fun pe, "Ní ìsin yi amọ̀ pé ìwọ ni ẹ̀mí èsù. Abrahamu àti àwọn woli kú; sùgbọ́n, ìwọ́ wípé, 'Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, òun kì yio tọ́ ikú wò; 53 Ìwọ kò tóbi ju Abrahamu baba wa tí ó kú lọ, àbí bẹ̀ a kọ? Àwon woli pẹ̀lú kú. Kí ni ò n fi ara à rẹ pè?" 54 Jesu dáhùn wípé, "Bí mo bá yin ara mi, ògo mi kò jẹ́ oun kan; sùgbọ́n baba mi ni ẹnití óun yìn mí lógo, ẹnití ẹ̀yín wí nípa rẹ̀ pé, Ọlọrun yín ni. 55 Ẹ̀yin kò ti mọ́, sùgbọ́n èmí mọ òhun. Bí èmí bá wípé, 'Èmi kò mọ́; èmí o dà bi yín, òpùrọ́. Sùgbọ́n èmí mọ́, mo sì pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́ . 56 Baba yín Abrahamu yọ̀ lati rí ọjọ́ mi; ó rìí, inú rẹ sì dùn." 57 Àwọn Ju sì wí fun pé, "O kò tí ìpé ọmọ aadọta, ìwọ́ sì ti rí Abrahamu?" 58 Jesu wí fún won pé, "Lotitọ, lotitọ, ni mo wí fún yin, kí Abrahamu tó wà, EMI ti wà." 59 Nígbà na ni, wọ́n mú òkúta nílẹ̀ láti sọ̀ọ́lu, sùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́ ósì jade kúrò nínú tẹ́mpìlì.