1 Lẹ́yìn oun kan wọ̀nyí Jesu n lọ káàkiri ní Galili, nítorí kò fẹ́ lọ sì Judia nítorí tí àwọn Ju n wa láti pa. 2 Nítorí Àjọ àgọ́ti àwọn Ju ti dé tán. 3 Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì wí fun pé, "Kúro ní ìhín kío sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ pẹ̀lú lerí àwọn isẹ́ tí iwọ nse. 4 Kò sí ẹni tí isé ohun kan ní ìkọ̀kọ̀ tí ó sì fẹ́ di mímọ̀ pẹ̀lú ní gbangba. Bí ìwọ́ bá ṣe nkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé. 5 Nítorí àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú kò gbàgbọ́. 6 Nígbànǎ ni Jesu wí fún wọn pé, "Àsìkò mi kò tí tó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní gbogbo àsìkò lọ́dọ̀. 7 Ayé kò le kórira yín, sùgbọ́n ó kórira mi nítorí mo jẹ̌rí pé ibi ni isẹ́ rẹ̀ íse. 8 Ẹ̀yin, ẹ gòkè lọ sí ibi ìpàgọ́ nâ, èmi kì yíò lọ nítorì àkókò mi kò tí tó." 9 Lẹ́yìn tì Ó sọ nkan wọ̀nyí, Ó dúró ní Galili. 10 Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ sí ibi àsè nâ, Òun pẹ̀lú gòkè lọ sí àsà nâ láìfi ara hàn nígbangba sùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀. 11 Awọn Ju n wa ní ibi àsè nâ, wọn sì n bèrè pé, "níbo lówà?" 12 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì nsọ ni pa Rẹ̀. Àwọn míràn wípé, "Ẹni rere ni," ẹ̀wẹ̀, àwọn míràn ní, "Rárá, ó n si ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà ni." 13 Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ kò sọ nípa Rẹ̀ ní gbangba nítorí ẹ̀rù àwọn Ju. 14 Nígbàtí àsè nâ fẹ́rẹ̀ parí tán, Jesu lọ sínú tempili, ósì bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀ni. 15 Ójẹ́ ìyàlẹnu fún àwọn Ju, wọ́n bèrè pé, "Báwo ni ọmọkùnrin yǐ ti ní ìmọ̀ tóbá yǐ láì se akẹ́kọ ilé ìwé kankan?" 16 Jesu dá wọn lóhùn ósì wípé, "Ẹ̀kọ́ mi kǐ se tèmi, bíkòse tẹni tó rán mi. 17 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti se ìfẹ́ rẹ̀, yíó mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ rè, bóyá ówá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni tàbí mò n sọ nípa ti ara mí ni. 18 Ẹni tí ó sọ ti ara rẹ̀ n wa ògo ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó n wá ògo ẹni tó ran, olótítọ́ ni ẹni nǎ, kòsì sí àìsòdodo nínú rẹ̀. 19 Mose kò a fún yín ní òfin? Bệ ọ̀kan nínú yín kòpa òfin mọ́. Èése tí ẹ fi n wá láti pamí?" 20 Ìjọ ènìyàn sì wípé, "Ẹlẹ́mǐ èsù ni ìwọ ìse, ta ló n fẹ́ láti pa ọ́?" 21 Jesu dáhùn ósì wípé, "Mo se isẹ́ kan, ẹnú sì ya gbogbo yín. 22 Mose fi ìkọlà fun yín, (kì íse nìti Mose bíkòse ti àwọn bàbá) ẹ̀yin sìn kọ okùnrin ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 23 Bí abá kọ okùnrin nílà ní ọjọ́ ìsinmi kí òfin Mose le dúró sinsin, ěse tí ẹ̀yin fi n bínú nígbàtí mo múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 24 Ẹmá se dáni lẹ́jọ́ nípa ti òde ara, ese ìdájọ́ òdodo." 25 Ọ̀pọ̀ nínú wọn láti Jerusalemu wípé, "Ẹni tí wọ́n wá láti pa kọ́ni èyí? 26 Wǒ, ó n sọ̀rọ̀ ní gbangba wọn kòsì sọ oun kankan si. Àwọn olórí amọ̀ pé èyí ni Kristi nâ bí? 27 Bẹ́ẹ̀ àwá mọ ibi tí ọkùnrin yi tiwá. Ṣùgbọ́n bí Kristi bá dé, kòsí ẹnikẹ́ni tó mọ ibi tó ti wá." 28 Jesu nké rara nínú tempili, Ó n kọ́ni ósì n wípé, "Ẹ̀yín mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ẹmọ ibi tí mo ti wá. Ẹ̀mi kòwá fún ara mi, olódodo ni ẹni tó rán mi, ẹ̀yin kòsì mọ́. 29 Èmí mọ̀ nítorí ọ̀dọ rẹ̀ ni mo ti wá, àti pé óun lórán mi." 30 Wọ́n gbìyànjú láti mú, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò le fọwọ́ kǎn nítorí àkókò rẹ̀ kòtí tó. 31 Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ nâ gbà gbọ́, wọ́n sì wípé, "Bí Kristi bádé òun óha ṣe àwọn isẹ́ àmì ju èyí tí arákùnrin yǐ ṣe lọ?" 32 Àwọn farisi gbọ́ wújẹ́wújẹ́ àwọn èrò nípa Jesu, àwọn olórí àlúfà àti àwọn farisi sì ránsẹ́ láti fi ipá mu. 33 Nígbànâ ni Jesu wípé, "Èmí wà pẹ̀lú yín fún ìwọn ìgbà díẹ̀, lẹ́hìn èyí ni, èmi ó padà sọ́dọ̀ ẹni tórán mi. 34 Ẹ̀yin yíò wá mi, ṣùgbọ́n ẹkò ní rí mi: ibi tí èmí nlọ, ẹkì yíò le wá bẹ̀." 35 Àwọn Ju sì wí lárìn arawọn pè, "Níbo laràkùnrin yí nlọ tí àwa kòní ri? Òún ó ha lọ sârin àwọn Helleni tí ó fọ́nká kí ó sì ma kọ́ àwọn Helleni bí? 36 Ọ̀rọ̀ kín ni ó sọ yìí, 'Ẹ̀yin ó wá mi, ẹkì yíò sì rí mi; ibi tí émì nlọ, ẹkí yíò le wá bẹ̀'?" 37 Ní ìparí ọjọ́ nlá àsè nâ, Jesu dúró ósì ké ní ohùn rara wípé, "Òùngbẹ a n gbẹ ẹnikẹ́ni bí, ẹjẹ́ kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó sì mu omi. 38 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́ nínú mi, gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, odò omi yíò sàn jáde láti inú rẹ̀ wá." 39 Ṣùgbọ́n Ó sọ èyí nípa ẹ̀mí, tí àwọn tó gbàgbọ́ nínú rẹ̀ yíò rí gbá, nítorí akò tí fi ẹ̀mí nâ fún ni, nítorí akò tí yin Jesu lógo. 40 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èrò nâ, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yí, wípe´, "Lótǐtọ́, Woli nâ ni èyí." 41 Àwọn míràn wípé, "Èyí ni Kristi naâ." Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ tún wípé, "Kristi a ti Galili wá? 42 Ìwé mímọ́ kò ha ti wípé, láti inú irú ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtlehemu, ìlú Dafidi ni Kristi yíò ti sẹ wá?" 43 Ìyapa sì dìde lârin àwọn èrò nítorí Rẹ̀. 44 Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò bá ti fi ipá mu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án. 45 Nítorínà, àwọn onsẹ́ padà tọ àwọn àlúfà àti pharisi wá, wọ́n sì wífún wọn pé, "Èése tí ẹfi le mú wa?" 46 Àwọn onísẹ́ nâ dáhùn pé , "Kò tí sí irú fẹ́ ẹ́ni tí ó sọ̀rọ̀ bí èyí rí." 47 Fún ìdí èyí, àwọn pharisi dá wọn lóhùn, "Ó ha ti tan ẹ̀yin nâ bí? 48 Ẹnikẹ́ni nínú àwọn olórí ha gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àbí ọ̀kan nínú àwọn pharisi? 49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn tí kò mọ òfin, di ẹni ìfibú." 50 Nicodemu (Ọ̀kan nínú àwọn pharisi, tí ó ti kọ wá sọ́dọ̀ rẹ) wí fún wọn pé, 51 wa dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ láì tí gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ tí kí ó tó mọ oun tí ó se bí? 52 Wọ́n da lóhùn pé, "Ìwọ́ nâ ha ti Galili wá bí? Wádìí, kí o sì ri, nítorí wòlí kan kò dìde ní Galili." 53 Nígbànâ ni olúkùlùkù sì gba ilé rẹ̀ lọ.