1 Lẹ́yìn àwọn nkàn wọ̀nyí, Jésù lọ sí òdì kejì Òkun Gálílì, èyí tí a tún ńpè ni Òkun Tìbéríà. 2 Àwọn ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ńwọ́ tọ̀ọ́ lẹ́yìn nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí wọ́n ríi pé ó ṣe lára àwọn aláìsàn. 3 Jésù sì gun orí òkè lọ Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. 4 (Ǹjẹ́ Àjọ Ìrékọjá, ọdún àwọn Júù, sì súnmọ́ tòòsí.) 5 Nígbàtí Jésù gb'ójú sókè Ó sì rí ogunlọ́gọ̀ àjọ àwọn ènìyàn ń wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Ó sì wí fún Fílípì pé, "Níbo ni á ó ti ra oúnjẹ tí yó tó fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti jẹ?" 6 Ṣùgbọ́n Jésù sọ èyí láti dán Fílípì wò nítorí tí Ó mọ ohun ti Òun yóò ṣe.) 7 Fílípì sí í dáa lóhùn pé, "Ìwọ̀n búrẹ́dì tí owó rẹ̀ tó igba dínárì kò le tó fún ẹnìkọ̀ọ̀kan kódà láti rí kékeré láti jẹ." 8 Áńdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, sọ fún un pé, 9 ọ̀dọ́mọkùnrin kan wà níbí ẹni tí ó ní búrẹ́dì tí a fi báálì ṣe àti ẹja méjì, ṣùgbọ́n níbo ni èyí a le dé láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn? 10 Jésù wípé, "Ẹ jẹ́kí àwọn ènìyàn kí ó jòkó." (Nísinsìnyí ọ̀pọ̀ koríko wà ní ibẹ̀.) Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà jókòó sílẹ̀, ìwọ̀n bí i ẹgbẹ̀rún márùn ún níye. 11 Nígbà náà ni Jésù mú ìṣù búrẹ́di ńà, àti lẹ́yìn tí ó dúpẹ́, o fi í fún gbogbo àwọn tí ó jókòó. Ó sì ṣe bẹ̀ ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ẹja ní ìwọ̀n tí olukúlùkù ènìyàn ń fẹ́. 12 Nígbàtí àwọn ènìyàn sì yó, Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé, "Ẹ ko gbogbo àwọn ẹ̀rún tí ó ṣẹ́kù, kí á má ba fi ohunkóhun ṣòfò." 13 Lẹ́yìn èyí wọ́n kó wọn jọ, àwọn àjẹkù ìṣù báálì márùn ún náà sì kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá. 14 Lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn rí àmì iṣẹ́ ìyanu tí Ó ṣe, wọn wípé, "Lóòtọ́ eléyìí ni Wòlíì náà tí yóò wá sínú ayé." 15 Nígbà tí Jésù mọ̀ wípé wọ́n fẹ́ fi tipá fi òun jọba, ó sá kúrò lọ́dọ̀ ọ wọn lọ sórí òkè láti dá wà ní òun nìkan. 16 Nígbàtí ó sì di alẹ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sí ibi òkun. 17 Wọ́n si wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì gba ojú omi òkun lọ sí Kápánáúmù. Ilẹ̀ sì ti ṣú ní àsìkò yìí, àti wípé Jésù kò sí ní ọ̀dọ̀ wọn. 18 Ìjì líle sì n fẹ́, àti wípé ojú òkun sí ǹ dàrú. 19 Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ti tù ọkọ̀ fún òpó ìwọ̀n sítédíà bí i mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jésù tí Ó nrìn lórí òkun, Ó sí n bọ̀ wá sí ìtòsí ibi ọkọ̀ ojú omi wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n Ó ṣọ fún wọn pé, "Èmi ni! Ẹ má ṣe bẹ̀rù." 21 Nígbà náà ni wọ́n finú fẹ́dọ̀ gbà á sínú ọkọ̀ wọn, àti wípé lójú ẹsẹ̀ ni ọkọ̀ wọn dé sí èbúté níbi tí wọn ń lọ. 22 Ní ọjọ́ kejì, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ti n dúró ni ìhà kejì òkun rí i wípé kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀ lẹ́yin ẹyọ̀kan ṣoṣo àti pé Jésù kò wọ inú u rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn nìkan ni wọ́n dá lọ. 23 Ṣùgbón àwọn ọkọ̀ ojú omi kan wá láti Tìbéríà sí ẹ̀bá ibití wọ́n ti jẹ àwọn ìsù búrẹ́dì lẹ́yìn ti Olúwa ti dúpẹ́. 24 Nígbà tí wọn ri wípé yálà Jésù tàbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ kòsí níbẹ̀, áwọn tìkarawọn wọnú ọkọ̀ ojú omi wọn lati lọ si Kápánáúmù wọ́n ń wá Jésù. 25 Lẹ́yìn tí wọ́n sì ri ni ìhà kejì òkun, wọ́n wí fun pé, "Ráàbì, nígbàwo ni O de síbí?" 26 Jésù si dá wọn lóhùn, ó wípé, "Lóòtọ́ọ́, lóòtọ́ọ́, ẹ̀yin ń wá mi kì íṣe nítorí àwọn àmì iṣẹ́ ìyanu bíkòse nítorí àwọn ìsù búrẹ́dì tí ẹ jẹ tí ẹ sì yó. 27 Mo rọ̀ yín kí ẹ má ṣe wa oúnjẹ èyí tí o le parun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ẹ ṣisẹ́ fún oúnjẹ ìyè àínípẹ̀kun ti yóó wà títí láí èyítí Ọmọ Ènìyàn yóó fun yín, nítorí tí Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì Rẹ̀ sóríí Rẹ̀." 28 Lẹ́yìn èyí ni wọ́n wí fún un pé, "Kín ni kí àwa ó ṣe lati siṣẹ́ Ọlọ́run?" 29 Jésù dáwọn lóhùn o si wí fún wọn pé, "Èyí ni iṣẹ́ Ọlọ́run: ẹ gba ẹnì kan náà tí Ó ti rań wá sí ayé gbọ́." 30 Nígbà náà ni wọ́n wí fun pé, "Kín ni àmì tí ìwọ yóò ṣe, èyítí àwa yóò rì í tí a ó sí gbàgbọ́? 31 Àwọn bàba wa jẹ mánà ní aginjù, gẹ́gẹ́bi a ti i kọ́ ọ́ pé, 'Ó fún wọn ní búrẹ́dì láti ọ̀run wá láti jẹ." 32 Nígbà náà ni Jésù dáwọn lóhùn ó sì wípé, "Lóòtọ́ọ́, lóòtọ́ọ́, kì í ṣe Mòósè ni ó fún yín ní búrẹ́dì tí ó ti ọ̀run wa bíkòṣe Bàba mi ni ó fún yín ni búrẹ́dì tòótọ́ lati ọ̀run. 33 Nítori búrẹ́dì Ọlọ́run ni èyí ti ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá àti èyí tí o nfún ayé ni ìyè." 34 Wọn sì sọ fún un pé, Alàgbà, fún wa ní búrẹ́dì yì í ní gbogbo ìgbà." 35 Jésù sọ fún wọn pé, "Èmi ni oúnjẹ ìyè; ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yòó pá láílái, àti wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ òrúgbẹ kì yóò gbẹ́ láíláí. 36 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé nítòótọ́ ẹ̀yin ti rí mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 37 Gbogbo áwọn ẹnití Bàbá fi fún mi ni yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti wípé ẹnikẹ́ni tó bá tọ̀ mí wá dájúdájú èmi kì yoò ta á nù. 38 Nítorí tí èmi wá lati ọ̀run, kì í ṣe láti se ìfẹ́ tì kara aláraami, ṣùgbọ́n lati ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi. 39 Èyí sì ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, pé kí èmi kí ó má ṣe pàdánù gbogbo àwọn tí ó fi fún mi, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó lè gbé wọn dìde ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́. 40 Nítorí èyi ni ìfẹ́ Bàbá mi, pé kí gbogbo ẹni tí ó bá ti rí Ọmọ ati wípe o ní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ ni yóò ni iyè àìnípẹ̀kun àti wípé èmi yóò gbé e dìde ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́. 41 Lẹ́yìn èyí àwọn Júù bẹ̀rẹ sí kùn sí i nítorí pe o ṣo wípé, "Èmi ni búrẹ́di tí ó ṣòkalẹ̀ láti ọ̀run wa." 42 Wọ́n sì wípé, "Eléyìí ki a ṣe Jésù ọmọ Jóṣẹ́fù bí, ẹni ti àwa mọ bàbá àti ìyá Rẹ̀? Níṣinṣìnyí báwo ló ṣe ń ṣọ wípé, "Èmi ṣọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run wá." 43 Jésù si dá wọn lóhùn ó wípé, "Ẹ yé má a kùn láàrin ara yín. 44 Ẹnikẹ́ni kò le wá ṣọ́dọ̀ mi bíkòse wípé Bàbá mi tí o ránmi fà á wá sí ọ̀dọ̀ mi, àti pe èmi tìkalára mi yóo gbe dìde níkẹyìn ọjọ́. 45 A ṣá ti kọọ́sílẹ̀ nínú ìwé àwọn wòólì pe, "Gbogbo ènìyàn ni a ó kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run." Gbogbo ẹni tí ó ti gbọ́ ati pe o ti kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ Bàbá ni ó ń wá ṣọ́dọ̀ mi. 46 Nìtorí pé ẹnikẹ́ni kò rí Bàbá rí, lẹ́yìn Ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa - òun sì ti rí Baba. 47 Lóòtọ́ọ́, lóòtọ́ọ́, ẹnikẹ́ni tíó bá gbàgbọ́ ní iyé àìnípẹ́kun. 48 Èmi ni búrẹ́dì ìyè. 49 Àwọn baba yín jẹ mánà ní aginjù, àti wípé wọ́n kú. 50 Èyí ni búrẹ́dì náà tí ó ṣọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pé ènìyàn le è jẹ nínú Rẹ̀ kì ó má kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ìyè tí ó ṣọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Bí ẹnikẹ́ni bá síì jẹ nínú oúnjẹ yi, òun yóo yè títí láí. Nítorí oúnjẹ ti èmi O fi fún ayé ni ìyè ni ẹran ara mì." 52 Eleyì í ṣì mú inú bí àwọn Júù tó bẹ̀ gẹ́ tí n wọn bára wọn jiyàn, wípé, "Báwo ni arákùnrin yóo ṣe fún wa ní ẹran ara rẹ̀ láti jẹ?" 53 Lẹ́yìn èyí ni Jésù ṣọ fún wọn pé, "Lóòtọ́, lóòtọ́, tí kò bá se wípé ẹ̀yin jẹ nínú ara Ọmọ Ènìyàn àti wípé ẹ mu nínú ẹ̀jè Rẹ̀, ẹ̀yin kò le ní ìyè nínú ẹ̀yin tìkalára yín. 54 Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ nínú ara mi àti mu nínú ẹ̀jẹ̀ mi yóò ní iyè àìnípẹ̀kun, àti wípe èmi yóò jí i dìde níkẹyìn ọjọ́. 55 Nítorí tí ara mi jẹ́ oúnjẹ nítòọ́tọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi jẹ́ ohun mímu nítòọ́tọ́. 56 Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ nínú ara mi àti mu nínú ẹ̀jẹ̀ mi yóò wà nínú mi, àti èmi nínú rẹ́. 57 Gẹ́gẹ́ bi Baba mi ti ó wá láàyè ti rán mi, àti wípé bí èmi ti wa láàyè nítorí Baba, nítorí náà ẹni tí o bá jẹ mí yóó yè nítorí tèmi. 58 Èyí ni búrẹ́dì ti o ṣọ̀kalẹ̀ lati ọ̀run wa, kì í ṣe bi èyítí àwọn baba yín jẹ tí wọn sì kú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ búrẹ́dì yìí yóò wà títí láí." 59 Ṣùgbọ́n Jésù ṣọ àwọn ǹ kan wọ̀nyí nínu Sínágọ́gù nígbátì ó ńkọ́ wọn ni Kápánáúmù. 60 Lẹ́yìn èyí ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí o gbọ́ èyí wípé, "Ẹ̀kọ́ èyí l'ágbára; tani ó le e gbà á? 61 Jésù, nítorí òun tìkararẹ̀ mọ̀ nínú rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ́yìn rẹ̀ ńkùn nítorí èyí, ó ṣọ fún wọn pe, "Ǹjẹ́ èyí a bi yín nínú bí? 62 Ǹjẹ́ nígbàtí ẹ̀yin bá rí Ọmọ Ènìyàn tí o ngòkè padà lọ síbi tí ó wá tẹ́lẹ̀? 63 Ẹ̀mí ni o ńfúnni ní ìyè; ara kò ní èrè kankan. Àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ń sọ fún yin ẹ̀mí ni wọ̀n, àti ìyè sì ni wọn pẹ̀lú. 64 Síbẹ̀ àwọn kan ń bẹ nínú yín tí wọn kò gbàgbọ́." Nítorí Jésù mọ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ gbogbo áwọn tí kò gbàgbọ́ àti ẹni náà tí yóò dàá. 65 Ó wípé, "Nítorí èyí ni mo fi sọ fún yín pe ẹnikẹ́ni kò le wá sí ọ̀dọ̀ mi bíkòbáṣe wípé a fi fún wa lati ọ̀dọ̀ Baba." 66 Nítorí èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ padà ṣẹ́yìn wọn kò sì rìn pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. 67 Lẹ́yín èyí Jésù sì bi àwọn méjèèjìlá náà pé, "Ǹ jẹ́ ẹ̀yin náà fẹ́ lọ ọ bí?" 68 Símónì Pétérù sì dá a lóhùn pe, "Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa o lọ?" Nítorí ìwọ ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun, 69 àti wípé àwa ti gbàgbọ́ a ṣì ti mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run." 70 Jésù bi wọn pé, "Ṣé èmi kọ́ ni mo yàn ni, ẹ̀yin méjìlá, àti wípé ọ̀kan nínú yin jẹ́ èsù? 71 Níṣinsìnyí o nṣọ nípa Júdásì ọmọ Símónì Ìsìkáríótù, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ẹni tí yòó ṣẹ́ Jésù.