1 Lẹ́yìn èyí ni àjọ̀dún àwon Júù kán wà, Jésù sì lọ sí Jèrúsalẹ́mú. 2 Lẹ́bá ẹnuọ̀nà àwọn àgùtàn ní Jèrúsalẹ́mù, adágún kan wà tó ńjẹ́ Bẹtẹ́sdà tó túmọ̀ sí ilẹ̀ àánú ní èdè Hébérù, tí ó ní àsomọ́ ilé márùn tó ní òrùlé. 3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n ṣàìsàn, fọ́jú, yarọ tàbí rọlápá-rọlẹ́sẹ̀ sùn sílẹ̀ níbẹ̀. 4 Nítorí ángẹ́lì Olúwa sọ̀kalẹ̀ ó sì rú omi sókè ní àwọn àkókò kan ẹnikẹ́ni tó bá si wọ inú rẹ̀ nígbàtí omi náà bá di rírú rí ìmúlaradá nínú àìsàn tó ń yọọ́ lénu. 5 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó ti sàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì. 6 Nígbàtí Jésù ríi tó nà sílẹ̀ níbẹ̀, tó sì dáa lójú pé ó ti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́, ó sọ fun wípé "Sé o fẹ́ ní ìlera?" 7 Ọkùnrin tó sàìsàn náà fèsì wípé, "Alàgbà, èmi kò ní ẹnìkan tó lè fi mí sínú adágún nígbàtí omi náà bá ti rúpọ̀ sókè. Tí mo bá dé, ẹlòmíraǹ yó ti sọ̀kalẹ̀ síwájú mi." 8 Jésù wí fún un pé, "Dìde sókè, gbé ìbùsùn rẹ, kí o sì rìn." 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ọkùnrin náà sì ní ìlera padà, ó sì gbé ibùsùn rẹ̀ ó sì rìn. Nísinsìyí ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. 10 Àwọn Júù sọ fún ẹni tó ní ìlera náà pé, "Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni àti pé kò sẹ́ni tó fún ọ láàyè láti gbé ẹní rẹ." 11 Ó fèsì pé, "Ẹni tó mú mi lárale sọ fún mi pé 'gbé ẹní rẹ kí o sì rìn.'" 12 Wọ́n bií léèrè pe "Tani ọkùnrin náà tó sọ fún ọ pé, 'gbe ẹní nílẹ̀ ko sì rìn?'" 13 Ọnàyówú tó gbà, ẹni tí ó gba ìlera náà kò mọ ẹni tí íse nítorí Jésù ti lọ kúro láìjẹ́ kó di mímọ̀, nítorí èrò púpò ló wà níbẹ̀. 14 Lẹ́hìn ìgbà náà, Jésù rí ọkùnrin tí ó wosàn nínú Témpìlì ó sì wí fún pé, "Wòó, o ti wá ní ìlera báyìí! máṣè dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tó burú kó má baà ṣẹlẹ̀ sí ọ." 15 Ọkùnrin náà bá tirẹ̀ lọ ó sì fi àbọ̀ fún àwọn Júù pé Jésù ni ẹnití ó mú òhun lárale. 16 Nísinsìnyí, nítorí ǹkan wọ̀nyí àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, nítorí Ó ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi. 17 Jésù fèsì padà sí wọn, "Bàbá mi ńṣiṣé lọwọlọwọ báyí, ati Èmi, pàápàá, mò ń ṣiṣé." 18 Nítorí èyí, àwọn Júù ńlépa gidigidi lati paá nitorí kó kúkú ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n Ó tún pe Ọlọ́run ní Baba rẹ̀, Ó sọ ara rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run. 19 Jésù dá wọn lóhùn, "Lóòtọ́, lóòtọ́, Ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun ti ara rẹ̀, àfi ohun to rí tí Babá ńṣe, nítorí ohunkóhun tí Babá bá nṣe, Ọmọ náà nṣe àwọn nkan wònyí pẹ̀lú. 20 Nítorí ti Bàbá fẹ́ràn Ọmọ Ó sì fi ohun gbogbo tí Ò ń ṣe hàn Án, àti pé Òhun yóò sì fi ọ̀pọ̀ ohun ńlá tó jù wọ̀nyí lọ hàn Án kí ẹnu kó le yà yín. 21 Nítorí bí Baba tí ń jí òkú dìdé tí ó sì ń fún wọn ní ìyè, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Ọmọ pẹ̀lú ń fi ìyè fún ẹnikẹ́ni tí O fẹ́. 22 Nítorí Baba kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n O ti fi gbogbo ìdájọ́ fún Ọmọ náà 23 torí kí ẹníkọkan le fi ọlá fún Ọmọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń fọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá fọlá fún Ọmọ kò fọlá fún Baba tó rán Ọmọ. 24 Lóòtọ́, lóòtọ́, ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi tí ó sì gbàgbọ́ nínú ẹni tí ó ránmi ó ní iyè tí kò lópin àti pé kò ní gba ìdálẹ́bi, ṣùgbón ó ti rékọjá kúrò nínú ikú sí ìyè. 25 Lóòtọ́, lóòtọ́, mo sọ fún yín àkókò náà ńbọ, nísinsìnyí ni, nígbàtí àwọn òkú yó gbọ́ ohún Ọmọ Ọlọ́run, àwọn tí ó sì gbọ́ yóò sì wà láàyè. 26 Nítorí gẹ́gẹ́ bí Baba ṣe ní iyè nínú ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì ti fi fún Ọmọ nítorí pé O ní iyè nínú ara rẹ̀, 27 àti pé Baba ti fi àṣẹ fún Ọmọ láti ṣe ìdájọ́ nítorípe òun sì ni Ọmọ Ènìyàn. 28 Máṣe jẹ́ kí èyí yà ọ lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nínú èyí tí ẹnìkọ̀kan tí ó wà nínú àwọn ibojì yóò gbọ́ ohùn Rè 29 wọn yóò sì jáde: àwọn tó ti ṣe rere sí àjíǹde ti ìyè, ati àwọn tí ó ti se buburú sí àjíǹde ti ìdájọ́ 30 Èmi kò lè ṣe ohunkóhun láti ọwọ́ ara mi. Bí mo ti gbọ́, mo dájọ́, ìdajọ́ mí sì jẹ́ òdodo nítorí pé emi ko wá ìfẹ́ araà mi ṣùgbọ́n ti ìfẹ́ẹ Ẹnitó ran mi. 31 Tí emi yó bá jẹ́rí nípa ara mi, ìjẹ́ríì mi kò ní jẹ́ òtító. 32 Ẹlòmíràn wà tó njẹ́rí mi, mo sì mọ pé ìjẹ́rí tó njẹ́ nipaà mi jẹ́ òótọ́. 33 Ẹ ti ránṣẹ́ sí Jọ̀hánú, òun sì ti jẹ́ri òdodo. 34 Ṣugbọ́n ìjẹ́rí tí mo rí gbà kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn. Mo sọ àwọn nkan wọ̀nyí pé kí ẹ báà le yè. 35 Jọhánù dàbíi fìtílà tó ńjó tó sì ńdán, ẹ̀yín sì ti múra láti yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 36 Síbẹ̀ ìjẹ́rí tí emí ní ju ti Jọ̀hánù lọ, nítorí àwọn iṣẹ́ tí Babá fi fún mi láti parí, àwọn iṣé náà tí mo ṣe, jẹ́rí nípaà mi wípé Babá ti rán mi. 37 Bàbá tí ó rán mi oun pàápàá jérí nípaà mi. Ẹ kò tilẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ tàbí rí ìrísí rẹ̀ nígbàkan. 38 Ẹ kò tilẹ̀ ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ṣẹ́kù nínú yín, nítorí ẹ kò ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí o ti rán. 39 Ẹ̀yín ńwá inú àwọn ìwé mìmọ́ nítori ẹ rò pé nínú wọn lẹní ìyè àìlópin, àti pé àwọn ìwé mímọ yí jẹ́rí nípaà mi, 40 àti pé ẹ̀yin kò ṣetán láti tọ̀ mí wá torí pé kí ẹ le ní ìyè. 41 Èmi kò gba ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn 42 ṣugbọ́n mo mọ̀ pé ẹyin kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ara yín. 43 Mo ti wá ní orúkọ Babáà mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí. Bí elòmíràn bá wá ní orúko ara rẹ̀, ẹ̀yin yó gbàá. 44 Báwo lẹ ó se gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ìyìn lọ́dọ̀ọ ara yín ṣugbón ẹ kò wá ìyìn tó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan ṣoṣo. 45 Máṣe rò wípé emi pàápàá yóò fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú Bàba. Ẹni tí ó ń fẹ̀sùn kàn yín ni Mosè, nínú ẹnití ẹ fi ìrètí yín sí. 46 "Bí ẹ bá gba Mósè gbọ́, ẹ ó gbà mí gbọ́, nítorí ó kọ nípaà mi. 47 Bí ẹ kò bá gba àwon ìwé rẹ̀ gbọ́, báwo ni ẹ ó ṣe gbà ọ̀rò mi gbọ́?."