1 Nígbàtí Jésù ti mọ̀ pé àwọn Farisí ti gbọ́ pé òun ńṣe ìtẹ̀bọmi ọ̀pọ̀lọpọ ọmọ ẹ̀yìn tí ó ju ti Jòhánù lọ 2 Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé Jésù funrarẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ni ó ńti àwọn ènìyàn bọmi 3 O kúrò ní Jùdíà, ó sì padà sí Gálílì. 4 Ó ṣe dandan fun láti gba Samáríà kọjá. 5 Nítorínáà ó wá sí ìlú kan ní Samáríà, tì à ńpè ní Sííkà, lẹ́bàá ilẹ̀ tí Jákọ́bù fi fún Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀. 6 Kànga Jákọ́bù wà níbẹ̀, ó rẹ Jésù fún ìrìn àjò tí ó ti rìn, O jókòó lẹ́gbẹ̀ ẹ kànga níwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́. 7 Obìnrin aráa Samáríà si dé láti pọn omi, Jésù sọ fún un pé, " Fún mi ní omi mu!" 8 Nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti ra oúnnjẹ. 9 Obìnrin náà sọ fún un wípé, ó yà mí lẹ́nu tí ìwọ Júù lè máa bèrè omi mímu lọ́wọ́ èmi aráa Samáríà. 10 Jésù dáa lóhùn, ó sì sọ fún un wípé, tí ìwọ bá mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó ńbá ọ sọ̀rọ̀, wípé fún mi ní oun mímu, ìwọ kì báa béèrè lọ́wọ́ọ̀ mi oun mímu, èmi ìbá fún ọ ní omi ìyè. 11 Obìnrin náà sọ fún un wípé, Ọ̀gbẹ́ni, ìwọ kò ní ìfami tí ìwọ ó fi fa omi 12 Ìwọ́ a ga ju bàbá wa Jákọ́bù, lọ bí? tí ó fún wa ní kànga yí, tí òun fúnra rẹ̀ mu nínu rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀. 13 Jésù dáa lóhùn, ó sì wí fún un pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá mú nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò gbẹ́ẹ́. 14 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi yóò fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ́ẹ́ mọ́, omi tí èmi ó fi fún un yóò di orísun omi nínú rẹ̀, tí ó ńsun ìyè àìnípẹ̀kun. 15 Obìnrin náà sọ fún un wípé "Ọ̀gbẹ́ni, fún mí ní omi yíí, kí òǹgbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí èmi má baà wá fa omi yìí mọ́" 16 Jésù sọ fun un wípé, "Lọ, pe ọkọ ọ̀ rẹ , kí o sì padà wá." 17 Obìnrin náà dáa lóhùn, ó sì wípé, "èmi kò ní ọkọ". Jésu dáhùn wípé, ìwọ tọ̀nà tí o wípé ìwọ kò ní ọkọ. 18 Nítorípé o ti ní ọkọ máàrún tẹ́lẹ̀, èyí tí o wà lọ́dọ̀ ọ rẹ̀ báyìí, kìí ṣe ọkọ ọ̀ rẹ. Òtítọ́ ni ohun tí o sọ. 19 Obìnrin náà sọ fún un wípé, "Ọ̀gbẹ́ni mo mọ̀ wípé wòIíì ni ìwọ ńse." 20 Àwọn bàbá wa sìn ní orí òkè yìí, ṣùgbọ́n ìwọ́ wìpé Jerúsálémù ni ibi ti àwọn ènìyàn ti le jọ́sìn. 21 Jésù sọ fún un pé, "Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, àkókò ńbọ̀, nígbàtí ìwọ yóò sìn Baba, kìí se ní orí òkè yìí, tàbí Jerúsálémù. 22 Ìwọ́ sìn ohun tí ìwọ kò mọ̀, àwá sìn ohun tí àwá mọ̀, nítorí ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù. 23 Ṣùgbọ́n, àkókó ńbọ, ó sì ti dé nísinsìnyí, nígbàtí àwọn olùjọ́sín tòótọ́ yóò máa sìn Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́, nítorí irú àwọn olùjọ́sìn bẹ́ẹ̀ ni Baba ńwá, kí o máa sìn òun. 24 Ẹ̀mí ni Ọlọ́run, àwọn tí ó ńsìn ín yóò maa sìn ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́. 25 Obìnrin náà sọ fún un wípé, "Mo mọ̀ pé, Mèsáyà ńbọ̀, ẹnití a pè ní Krístǐ. Nígbàtí ó bá dé, yoo fi òye ohun gbogbo yé wa. 26 Jésù wí fun pe, "Èmi ni ẹnití ó ńbá ọ sọ̀rọ́." 27 Ní àkókò náà, àwọn ọmọ ẹ́yìn rẹ̀ dé, ó yà wọ́n lẹ́nu, ìdí tí ó ńfi bá obiǹrin sọ̀rọ̀, ṣùgbón kò sí ẹni tí o sọ̀rọ̀ pe "Kíni ìwọ ńfẹ́, tàbí kíni ìdí tí ò ńfi ńbaa sọ̀rọ̀." 28 Obìnrin naa fi ìfami rẹ̀ sílẹ̀, ó padà lọ sí ìgboro, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn. 29 Ẹ wá, wo arákùnrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti se fún mi. Òún ha ńṣe Krístì náà, ǹjẹ́ ó lè rí bẹ́ẹ̀?. 30 Wọ́n fi ìgboro sílẹ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Rẹ. 31 Ní àsìkò diẹ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ńkan lójú pé "Olùkọ́ni, jẹun" 32 Sùgbọ́n ó sọ fun wọn pé, "Mo ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀ nípa a rẹ̀." 33 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn in rẹ̀ sọ fún un ara wọn pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó gbe oúnjẹ wá fún, à bi?. 34 Jésù sọ fún wọn pé, oúnjẹ ẹ̀ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti làti parí isẹ́ rẹ̀. 35 Ẹ̀yin kò ha sọ pé, àkókò ìkórè ku oṣù mẹ́rin? Èmí sọ fún un yìn, ẹ wòké, ẹ wo oko tí ó ti pọ́n fun ìkórè!. 36 Ẹnití ó ńkórè gba owó iṣẹ́, ó sì kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí ẹnití ńfúnrúgbìn àti ẹnití ńkórè le yọ̀ papọ̀. 37 Nítorí a sọ èyí pé, ènìyàn kan gbìn, ẹlòmíràn ńkórè, òtítọ́ ni. 38 Mo rán an yín láti kórè ohun tí ẹ kò ṣiṣẹ́ fún. Àwọn mìíràn ti ṣiṣẹ́, ìwọ sì ti wọnú ìkórè e wọn. 39 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará a Samáríà gbàgbọ́ nínú ẹ̀rí obìnrin yi, pé ó sọ ohun gbogbo tí mo ṣe. 40 Nígbàtí àwọn ará a Samáríà wá, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ ọ rẹ̀ kí ó dúró sí ọ̀dọ̀ ọ wọn, ó dúró fún ọjọ́ méjì. 41 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ síi, nítorí ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀. 42 Wọ́n sọ fún obìnrin nàá pé, kìí se pé a gbàgbọ́ nìtorí ọ̀rọ̀ rẹ nìkan, ṣùgbọ́n nítorí àwa náà ti gbọ́, a sì ti mọ̀ nítòótọ́ pe, òun ni Olùgbàlà aráyé. 43 Lẹ́híìn ọjọ́ méjì, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Gálílì. 44 Jésù fúnraarẹ̀ sọ pé wòlíì ki ílọ́lá ní ìlú u rẹ̀. 45 Nígbàtí ó dé Gálílì, àwọn ará ìlú Gálílì kíi káàbọ, wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Jerúsálẹ́mù ní àkókò àjọ̀dún, nítorí àwọn pẹ̀lú ti lọ sí àjọ̀dún. 46 Nísinsìnyí, ó wá sí Kánà ti Gálílì, níbití ó ti sọ omi di ọtí wáìnì. Ara ọmọ ìjóyè ọlọ́là kan kò yá. 47 Nígbàtí ó gbọ́ pé Jésù dé láti Jùdíà sí Gálílì, ó lọ bá Jésù, ó sì bẹ̀ẹ́ kí ó wá láti wo ọmọ rẹ̀ tí ó ń kú lọ sàn. 48 Jésù dàa lóhùn pé, "Bí ẹ̀yin kò bá rí isẹ́ àmìn àti ìyanu, ẹ̀yin kò ní gbàgbọ́. 49 Ìjòyè náà sọ fún un pé, " Ọ̀gbẹ́ni, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ ọ mi tó ó kú. 50 Jésú dáa lóhùn, "Lọ, ọmọ ọ̀ rẹ yè," Ọkùnrin náà gbaa ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún un gbọ́, ó sì lọ. 51 Nígbàtí ó ńlọ, ọmọ ọ̀dọ̀ ọ̀ rẹ̀ pàdé e rẹ̀, ó sì sọ fún un pé ọmọ ọ rẹ́ ye. 52 Ó bèèrè àsìkò tí èyí ṣẹlẹ̀. Ó sì dá a lóhùn wípé, "Ní àná ní wákàtí keje ni àrùn ibà náà fi sílẹ̀." 53 Nígbà náà ni bàbá ọmọ náà kíyèsi wípé ní wákàtí tí Jésù sọ pé "Ọmọ ọ̀ rẹ́ yè." Nítorí ìdí èyí, òhun àti gbogbo ilé e rẹ̀ gbàgbọ́. 54 Èyì ni iṣẹ ìyanu kejì tí Jésù ṣe nígbàtí ó wá sí Jùdíà, ti Gálílì.